25 “Tí ẹ bá yá ìkankan nínú àwọn èèyàn mi tó jẹ́ aláìní* lówó, ẹni tó ń bá yín gbé, ẹ ò gbọ́dọ̀ hùwà sí i bí àwọn tó ń yáni lówó èlé.* Ẹ ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ rẹ̀.+
20 O lè gba èlé lọ́wọ́ àjèjì,+ àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ gba èlé lọ́wọ́ arákùnrin rẹ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+