ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 15:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Ṣùgbọ́n, ẹnikẹ́ni nínú yín ò gbọ́dọ̀ tòṣì, torí ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ọ+ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,

  • Diutarónómì 15:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ bá di aláìní láàárín rẹ nínú ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, o ò gbọ́dọ̀ mú kí ọkàn rẹ le tàbí kí o háwọ́ sí arákùnrin rẹ tó jẹ́ aláìní.+

  • Diutarónómì 15:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Kí o lawọ́ sí i dáadáa,+ kí o* má sì ráhùn tí o bá ń fún un, torí èyí á mú kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àtàwọn ohun tí o bá dáwọ́ lé.+

  • Òwe 19:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan,+

      Á sì san án* pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.+

  • Lúùkù 6:34, 35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 34 Bákan náà, tí ẹ bá ń yá* àwọn tí ẹ retí pé wọ́n máa san án pa dà ní nǹkan, àǹfààní kí ló jẹ́ fún yín?+ Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá máa ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní nǹkan kí wọ́n lè rí ohun kan náà gbà pa dà. 35 Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ẹ máa ṣe rere, kí ẹ sì máa yáni ní nǹkan láìretí ohunkóhun pa dà;+ èrè yín máa wá pọ̀, ẹ sì máa jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, torí ó máa ń ṣoore fún àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni burúkú.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́