23 Jésù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀, ‘Tí o bá lè’! Ó dájú pé ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́.”+24 Ojú ẹsẹ̀ ni bàbá ọmọ náà kígbe pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”+
2 bí a ṣe ń tẹjú mọ́ Jésù, Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.+ Torí ayọ̀ tó wà níwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró,* kò ka ìtìjú sí, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.+