-
1 Kọ́ríńtì 11:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Nítorí ọwọ́ Olúwa ni mo ti gba èyí tí mo fi lé yín lọ́wọ́, pé Jésù Olúwa mú búrẹ́dì ní alẹ́ ọjọ́+ tí a ó dalẹ̀ rẹ̀, 24 lẹ́yìn tó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí ó wà nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+ 25 Ó ṣe bákan náà ní ti ife náà,+ lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó ní: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ tí a fi ẹ̀jẹ̀ mi dá.*+ Nígbàkigbà tí ẹ bá ń mu ún, ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+
-