7 “Kí Áárónì+ sun tùràrí onílọ́fínńdà+ lórí rẹ̀,+ kí ó mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ nígbà tó bá ń bójú tó àwọn fìtílà náà+ láràárọ̀. 8 Bákan náà, tí Áárónì bá tan àwọn fìtílà náà ní ìrọ̀lẹ́, kó sun tùràrí náà. Bí wọ́n á ṣe máa sun tùràrí ní gbogbo ìgbà níwájú Jèhófà jálẹ̀ àwọn ìran yín nìyẹn.