-
Nọ́ńbà 16:39, 40Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
39 Àlùfáà Élíásárì wá kó àwọn ìkóná tí wọ́n fi bàbà ṣe, èyí tí àwọn tó jóná náà mú wá, ó sì fi wọ́n rọ ohun tí wọ́n á fi máa bo pẹpẹ, 40 bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè sọ fún un. Yóò máa rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ẹnikẹ́ni tí kò tọ́ sí,* tí kì í ṣe ọmọ Áárónì kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ tòsí láti sun tùràrí níwájú Jèhófà+ àti pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ dà bíi Kórà àti àwọn tó ń tì í lẹ́yìn.+
-
-
1 Sámúẹ́lì 2:27, 28Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Èèyàn Ọlọ́run kan wá sọ́dọ̀ Élì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Ǹjẹ́ mi ò fara han ilé baba rẹ nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì, tí wọ́n jẹ́ ẹrú ní ilé Fáráò?+ 28 Mo sì yàn án nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì+ láti ṣe àlùfáà fún mi, kó máa gòkè lọ sórí pẹpẹ mi+ láti rú ẹbọ, kó máa sun tùràrí,* kó sì máa wọ éfódì níwájú mi. Mo sì fún ilé baba ńlá rẹ ní gbogbo àwọn ẹbọ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* fi iná sun.+
-