6 Fetí sílẹ̀! Ẹnì kan ń sọ pé: “Ké jáde!”
Ẹlòmíì béèrè pé: “Igbe kí ni kí n ké?”
“Koríko tútù ni gbogbo ẹran ara.
Gbogbo ìfẹ́ wọn tí kì í yẹ̀ dà bí ìtànná àwọn ewéko.+
7 Koríko tútù máa ń gbẹ dà nù,
Ìtànná máa ń rọ,+
Torí pé èémí Jèhófà fẹ́ lù ú.+
Ó dájú pé koríko tútù ni àwọn èèyàn náà.