Orin Ìgòkè.
120 Mo ké pe Jèhófà nínú wàhálà mi,+
Ó sì dá mi lóhùn.+
 2 Jèhófà, gbà mí lọ́wọ́ ètè tó ń parọ́
Àti lọ́wọ́ ahọ́n ẹ̀tàn.
 3 Ṣé o mọ ohun tí Ó máa ṣe sí ọ, ṣé o mọ ìyà tí Ó máa fi jẹ ọ́,
Ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn?+
 4 Yóò lo àwọn ọfà mímú+ jagunjagun
Àti ẹyin iná+ àwọn igi wíwẹ́.
 5 Mo gbé, nítorí mo jẹ́ àjèjì ní Méṣékì!+
Mò ń gbé láàárín àwọn àgọ́ Kídárì.+
 6 Mo ti ń gbé tipẹ́tipẹ́
Pẹ̀lú àwọn tó kórìíra àlàáfíà.+
 7 Àlàáfíà ni èmi ń fẹ́, àmọ́ nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀,
Ogun ni wọ́n ń fẹ́.