ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Míkà 1:1-7:20
  • Míkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Míkà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Míkà

MÍKÀ

1 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Míkà*+ ará Móréṣétì, nínú ìran tó rí nípa Samáríà àti Jerúsálẹ́mù láyé ìgbà Jótámù,+ Áhásì+ àti Hẹsikáyà,+ tí wọ́n jẹ́ ọba Júdà:+

 2 “Ẹ gbọ́, gbogbo ẹ̀yin èèyàn!

Fetí sílẹ̀, ìwọ ayé àti ohun tó wà nínú rẹ,

Kí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́rìí ta kò yín,+

Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ láti inú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀.

 3 Wò ó! Jèhófà ń jáde lọ láti àyè rẹ̀;

Ó máa sọ̀ kalẹ̀ wá, á sì tẹ àwọn ibi gíga ayé mọ́lẹ̀.

 4 Àwọn òkè yóò yọ́ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀,+

Àwọn àfonífojì* yóò sì pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀,

Bí ìgbà tí iná yọ́ ìda,

Bí omi tó ṣàn wálẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè.

 5 Ọ̀tẹ̀ Jékọ́bù ló fa gbogbo èyí,

Ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì.+

Ta ló fa ọ̀tẹ̀ Jékọ́bù?

Ṣebí àwọn ará Samáríà ni?+

Ta ló sì kọ́ àwọn ibi gíga tó wà ní Júdà?+

Ṣebí àwọn ará Jerúsálẹ́mù ni?

 6 Màá sọ Samáríà di àwókù ilé inú oko,

Yóò di ibi tí wọ́n ń gbin àjàrà sí;

Màá ju* àwọn òkúta rẹ̀ sínú àfonífojì,

Èmi yóò sì hú àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ síta.

 7 Gbogbo ère gbígbẹ́ rẹ̀ máa fọ́ sí wẹ́wẹ́,+

Gbogbo ẹ̀bùn tó sì gbà nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó* ni wọ́n máa finá sun.+

Gbogbo òrìṣà rẹ̀ ni màá pa run.

Torí èrè tó rí nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó ló fi kó wọn jọ,

Wọ́n á sì pa dà di èrè fún àwọn aṣẹ́wó.”

 8 Torí èyí, màá pohùn réré ẹkún, màá sì hu;+

Èmi yóò rìn láìwọ bàtà àti ní ìhòòhò.+

Màá pohùn réré ẹkún bí ajáko,*

Èmi yóò sì ṣọ̀fọ̀ bí ògòǹgò.

 9 Torí ọgbẹ́ rẹ̀ kò lè jinná;+

Ó ti dé Júdà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.+

Egbò náà ti ràn dé ẹnubodè àwọn èèyàn mi, dé Jerúsálẹ́mù.+

10 “Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní Gátì;

Ẹ kò gbọ́dọ̀ sunkún rárá.

Ẹ gbé ara yín yílẹ̀ ní Bẹti-áfírà.*

11 Ẹ sọdá ní ìhòòhò pẹ̀lú ìtìjú, ẹ̀yin* tó ń gbé ní Ṣáfírì.

Àwọn* tó ń gbé ní Sáánánì kò tíì jáde.

Àwọn ará Bẹti-ésélì máa pohùn réré ẹkún, wọn ò sì ní tì yín lẹ́yìn mọ́.

12 Torí, ohun rere ni àwọn* tó ń gbé ní Márótì ń retí,

Àmọ́ Jèhófà ti mú ohun tó burú wá sí ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.

13 Ẹ̀yin* tó ń gbé ní Lákíṣì, ẹ de kẹ̀kẹ́ mọ́ àwọn ẹṣin.+

Ẹ̀yin lẹ mú kí ọmọbìnrin Síónì dẹ́ṣẹ̀,

Ẹ̀yin lẹ sì mú kí Ísírẹ́lì dìtẹ̀.+

14 Torí náà, wàá fún Moreṣeti-gátì ní ẹ̀bùn ìdágbére.

Ẹ̀tàn ni ilé Ákísíbù+ jẹ́ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì.

15 Ẹ̀yin* tó ń gbé ní Máréṣà,+ màá mú ẹni tí yóò ṣẹ́gun* yín wá.+

Ògo Ísírẹ́lì yóò dé Ádúlámù.+

16 Ẹ mú orí yín pá, kí ẹ sì fá irun yín torí àwọn ọmọ yín ọ̀wọ́n.

Ẹ mú orí yín pá bíi ti ẹyẹ idì,

Torí wọ́n ti kó wọn kúrò lọ́dọ̀ yín lọ sí ìgbèkùn.”+

2 “Àwọn tó ń gbìmọ̀ ìkà gbé,

Tí wọ́n ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn!

Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n gbèrò,

Torí pé agbára wọn ká a.+

 2 Oko olóko wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n sì gbà á;+

Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gba ilé onílé;

Wọ́n fi jìbìtì gba ilé mọ́ onílé lọ́wọ́,+

Wọ́n gba ogún lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.

 3 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

‘Mò ń gbèrò àjálù kan sí ìdílé yìí,+ ẹ kò sì ní yè bọ́.*+

Ẹ kò ní lè gbéra ga mọ́,+ torí àkókò àjálù ló máa jẹ́.+

 4 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa pa òwe fún yín,

Wọn á sì dárò lórí yín.+

Wọ́n á sọ pé: “Ó ti pa wá run pátápátá!+

Ó ti gba ìpín àwọn èèyàn wa. Ó sì ti fún àwọn ẹlòmíì!+

Ó ti fún àwọn aláìṣòótọ́ ní ilẹ̀ wa.”

 5 Torí náà, kò ní sí ẹnì kankan tó máa bá yín ta okùn,

Láti fi pín ilẹ̀ nínú ìjọ Jèhófà.

 6 Wọ́n ń pàrọwà fún wọn pé: “Ẹ má wàásù mọ́!

Kò yẹ kí wọ́n máa wàásù nípa àwọn nǹkan yìí;

Ojú kò ní tì wá!”

 7 Ilé Jékọ́bù, ṣé ohun tí àwọn èèyàn ń sọ ni pé:

“Àbí Jèhófà* kò ní sùúrù mọ́ ni?

Ṣé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nìyí?”

Àbí, ṣé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn olódodo láǹfààní ni?

 8 Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn mi ti sọ ara wọn di ọ̀tá.

Ẹ bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tó gbayì àti ẹ̀wù* lọ́rùn àwọn èèyàn ní gbangba,

Lọ́rùn àwọn tó ń kọjá lọ tí ọkàn wọn sì balẹ̀ bí ẹni tó ń ti ogun bọ̀.

 9 Ẹ lé àwọn obìnrin àwọn èèyàn mi kúrò nínú ilé tí wọ́n fẹ́ràn;

Ògo tí mo fún àwọn ọmọ wọn lẹ gbà lọ́wọ́ wọn títí láé.

10 Ẹ dìde, kí ẹ máa lọ, torí ibí kì í ṣe ibi ìsinmi.

Torí ìwà àìmọ́ yín,+ ẹ máa pa run, ìparun pátápátá.+

11 Bí èèyàn kan bá wà tó ń lépa asán, tó ń tanni jẹ, tó sì ń parọ́ pé:

“Màá wàásù fún yín nípa wáìnì àti ọtí,”

Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan-an ni oníwàásù táwọn èèyàn yìí fẹ́!+

12 Ẹ̀yin ilé Jékọ́bù, èmi yóò kó gbogbo yín jọ;

Ó dájú pé màá kó àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì jọ.+

Màá mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, bí àgùntàn ní ilé ẹran,

Bí agbo ẹran ní pápá ìjẹko wọn;+

Ariwo àwọn èèyàn máa gba ibẹ̀ kan.’+

13 Ẹni tó ń la ọ̀nà yóò lọ ṣáájú wọn;

Wọ́n á la ọ̀nà, wọ́n á gba ẹnubodè kọjá, wọ́n á sì gba ibẹ̀ jáde.+

Ọba wọn yóò ṣáájú wọn,

Jèhófà yóò sì ṣe olórí wọn.”+

3 Mo sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́ ẹ gbọ́, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù

Àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì.+

Ṣé kò yẹ kí ẹ mọ ohun tó tọ́?

 2 Àmọ́ ẹ kórìíra ohun rere,+ ẹ sì fẹ́ràn ohun búburú;+

Ẹ bó àwọn èèyàn mi láwọ, ẹ sì ṣí ẹran kúrò lára egungun wọn.+

 3 Ẹ tún jẹ ẹran ara àwọn èèyàn mi,+

Ẹ sì bó wọn láwọ,

Ẹ fọ́ egungun wọn, ẹ sì rún un sí wẹ́wẹ́,+

Bí ohun tí wọ́n sè nínú ìkòkò,* bí ẹran nínú ìkòkò oúnjẹ.

 4 Ní àkókò yẹn, wọ́n á ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́,

Àmọ́ kò ní dá wọn lóhùn.

Ó máa fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún wọn ní àkókò yẹn,+

Torí ìwà burúkú wọn.+

 5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí nípa àwọn wòlíì tó ń ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà,+

Tí wọ́n ń kéde ‘Àlàáfíà!’+ nígbà tí wọ́n bá ń rí nǹkan jẹ,*+

Àmọ́ tí wọ́n ń gbógun ti* ẹni tí kò fún wọn ní nǹkan kan jẹ:

 6 ‘Ilẹ̀ máa ṣú lọ́dọ̀ yín;+ kò ní sí ìran;+

Òkùnkùn nìkan lẹ máa rí, ẹ kò ní lè woṣẹ́.

Oòrùn yóò wọ̀ lórí àwọn wòlíì,

Ojúmọmọ yóò sì ṣókùnkùn fún wọn.+

 7 Ojú máa ti àwọn tó ń rí ìran,+

Ìjákulẹ̀ sì máa bá àwọn woṣẹ́woṣẹ́.

Gbogbo wọn máa bo ẹnu* wọn,

Torí pé Ọlọ́run kò ní dá wọn lóhùn.’”

 8 Ní tèmi, ẹ̀mí Jèhófà ti fún mi ní agbára,

Ó ti jẹ́ kí n lè ṣe ìdájọ́ òdodo, ó sì ti fún mi lókun,

Kí n lè sọ fún Jékọ́bù nípa ọ̀tẹ̀ tó dì, kí n sì sọ ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì fún un.

 9 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin olórí ilé Jékọ́bù

Àti ẹ̀yin aláṣẹ ilé Ísírẹ́lì,+

Tí ẹ kórìíra ìdájọ́ òdodo, tí ẹ sì ń yí gbogbo ọ̀rọ̀ po,+

10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ìtàjẹ̀sílẹ̀ kọ́ Síónì, tí ẹ sì ń fi àìṣòdodo kọ́ Jerúsálẹ́mù.+

11 Àwọn olórí* rẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó dájọ́,+

Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń gba owó kí wọ́n tó kọ́ni,+

Àwọn wòlíì rẹ̀ ń gba owó* kí wọ́n tó woṣẹ́.+

Síbẹ̀ wọ́n gbára lé Jèhófà,* wọ́n ń sọ pé:

“Ṣebí Jèhófà wà pẹ̀lú wa?+

Àjálù kankan ò lè dé bá wa.”+

12 Nítorí yín,

Wọ́n á túlẹ̀ Síónì bíi pápá,

Jerúsálẹ́mù á di àwókù,+

Òkè Ilé* náà á sì dà bí àwọn ibi gíga nínú igbó.*+

4 Ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́,*

Òkè ilé Jèhófà+

Máa fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè,

A sì máa gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèké lọ,

Àwọn èèyàn á sì máa rọ́ lọ síbẹ̀.+

 2 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa lọ, wọ́n á sì sọ pé:

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká lọ sórí òkè Jèhófà,

Sí ilé Ọlọ́run Jékọ́bù.+

Ó máa kọ́ wa ní àwọn ọ̀nà rẹ̀,

A ó sì máa rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.”

Torí òfin* máa jáde láti Síónì,

Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì máa jáde láti Jerúsálẹ́mù.

 3 Ó máa ṣe ìdájọ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,+

Ó sì máa yanjú* ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè alágbára tí ọ̀nà wọn jìn.

Wọ́n máa fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀,

Wọ́n sì máa fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn.+

Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,

Wọn ò sì ní kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.+

 4 Kálukú wọn máa jókòó* lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀,+

Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n,+

Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.

 5 Gbogbo èèyàn yóò máa rìn ní orúkọ ọlọ́run wọn,

Àmọ́ àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa+ títí láé àti láéláé.

 6 Jèhófà kéde pé, “Ní ọjọ́ yẹn,

Èmi yóò kó ẹni* tó ń tiro jọ,

Èmi yóò sì kó ẹni tó ti fọ́n ká jọ,+

Pẹ̀lú àwọn tí mo ti fìyà jẹ.

 7 Èmi yóò mú kí ẹni* tó ń tiro ṣẹ́ kù,+

Èmi yóò sì sọ ẹni tí wọ́n ti mú lọ sí ọ̀nà tó jìn di orílẹ̀-èdè alágbára;+

Jèhófà yóò sì jọba lé wọn lórí ní Òkè Síónì,

Láti ìsinsìnyí lọ àti títí láé.

 8 Ní ti ìwọ ilé gogoro tí agbo ẹran wà,

Òkìtì ọmọbìnrin Síónì,+

Ìjọba àkọ́kọ́* yóò wá sọ́dọ̀ rẹ, àní yóò wá,+

Ìjọba ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù.+

 9 Kí ló wá dé tí o fi ń pariwo?

Ṣé o kò ní ọba ni,

Àbí ẹni tó ń gbà ọ́ nímọ̀ràn ti ṣègbé,

Tí ara fi ń ro ọ́, bí obìnrin tó ń rọbí?+

10 Máa yí nínú ìrora, ọmọbìnrin Síónì, kí o sì kérora,

Bí obìnrin tó ń rọbí,

Torí o máa kúrò ní ìlú, wàá sì lọ gbé ní pápá.

O máa lọ jìnnà dé Bábílónì,+

Ibẹ̀ ni wàá ti rí ìdáǹdè;+

Ibẹ̀ ni Jèhófà yóò ti rà ọ́ pa dà lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ.+

11 Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kóra jọ láti dojú ìjà kọ ọ́;

Wọ́n á sọ pé, ‘Ẹ jẹ́ kó di aláìmọ́,

Ká sì fi ojú wa rí bí èyí ṣe máa ṣẹlẹ̀ sí Síónì.’

12 Àmọ́ wọn ò mọ ohun tí Jèhófà ń rò,

Wọn ò sì mọ ohun tó ní lọ́kàn;*

Torí ó máa tò wọ́n jọ bí ọkà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gé sílẹ̀ níbi ìpakà.

13 Dìde, kí o sì pakà, ìwọ ọmọbìnrin Síónì;+

Torí èmi yóò sọ ìwo rẹ di irin,

Màá sọ àwọn pátákò rẹ di bàbà,

Ìwọ yóò sì pa ọ̀pọ̀ èèyàn run.+

Ìwọ yóò fún Jèhófà ní ohun tí wọ́n fi èrú kó jọ,

Ìwọ yóò sì fún Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé ní àwọn ohun àmúṣọrọ̀ wọn.”+

5 “Ò ń fi nǹkan ya ara rẹ,

Ìwọ ọmọbìnrin tí wọ́n gbógun tì;

Wọ́n ti pàgọ́ tì wá.+

Wọ́n fi ọ̀pá lu onídàájọ́ Ísírẹ́lì ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.+

 2 Ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà,+

Ìwọ tó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún* Júdà,

Inú rẹ ni ẹni tí mo fẹ́ kó ṣàkóso Ísírẹ́lì ti máa jáde wá,+

Ẹni tó ti wà láti ìgbà àtijọ́, láti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.

 3 Torí náà, ó máa yọ̀ǹda wọn

Títí di àkókò tí ẹni tó fẹ́ bímọ fi máa bímọ.

Àwọn arákùnrin rẹ̀ tó kù sì máa pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

 4 Ó máa dìde dúró, Jèhófà yóò sì fún un lókun láti ṣe olùṣọ́ àgùntàn,+

Nípasẹ̀ orúkọ ńlá Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.

Ààbò yóò sì wà lórí wọn,+

Torí àwọn èèyàn máa mọ̀ ní gbogbo ìkángun ayé pé ó tóbi lọ́ba.+

 5 Ó sì máa mú àlàáfíà wá.+

Tí àwọn ará Ásíríà bá gbógun tì wá, tí wọ́n sì tẹ àwọn ilé gogoro wa tó láàbò mọ́lẹ̀,+

A máa rán olùṣọ́ àgùntàn méje sí wọn, àní àwọn ìjòyè* mẹ́jọ látinú aráyé.

 6 Wọ́n á fi idà ṣe olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ásíríà,+

Àti níbi àbáwọ ilẹ̀ Nímírọ́dù.+

Ó máa gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà+

Tí wọ́n bá gbógun tì wá, tí wọ́n sì tẹ ìlú wa mọ́lẹ̀.

 7 Láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Jékọ́bù

Máa dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,

Bí ọ̀wààrà òjò lórí ewéko,

Tí kì í retí èèyàn

Tàbí kó dúró de ọmọ aráyé.

 8 Àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Jékọ́bù máa wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,

Láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn,

Bíi kìnnìún láàárín àwọn ẹran inú igbó,

Bí ọmọ kìnnìún* láàárín agbo àgùntàn,

Tó kọjá, tó bẹ́ mọ́ ẹran, tó sì fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ;

Kò sì sí ẹni tó lè gbà wọ́n sílẹ̀.

 9 Ọwọ́ yín máa lékè àwọn elénìní yín,

Gbogbo ọ̀tá yín sì máa pa run.”

10 Jèhófà kéde pé: “Ní ọjọ́ yẹn,

Màá pa àwọn ẹṣin yín run láàárín yín, màá sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin yín run.

11 Màá run àwọn ìlú tó wà ní ilẹ̀ yín,

Màá sì wó gbogbo ibi olódi yín lulẹ̀.

12 Màá fòpin sí iṣẹ́ oṣó tí ẹ̀ ń ṣe,*

Kò sì ní sí onídán kankan láàárín yín mọ́.+

13 Màá run àwọn ère gbígbẹ́ àti àwọn ọwọ̀n yín kúrò láàárín yín,

Ẹ kò sì ní forí balẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ yín mọ́.+

14 Màá fa àwọn òpó òrìṣà*+ yín tu,

Màá sì run àwọn ìlú yín.

15 Ìbínú àti ìrunú ni màá fi gbẹ̀san

Lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ya aláìgbọràn.”

6 Ẹ jọ̀ọ́, ẹ gbọ́ ohun tí Jèhófà ń sọ.

Ẹ dìde, ẹ gbé ẹjọ́ yín lọ síwájú àwọn òkè,

Kí àwọn òkè kéékèèké sì gbọ́ ohùn yín.+

 2 Ẹ gbọ́ ẹjọ́ Jèhófà, ẹ̀yin òkè

Àti ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayé tó fìdí múlẹ̀,+

Torí Jèhófà fẹ́ pe àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́jọ́;

Yóò sì bá Ísírẹ́lì ro ẹjọ́ pé:+

 3 “Ẹ̀yin èèyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?

Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi sú yín?+

Ẹ sọ ohun tí mo ṣe.

 4 Mo mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+

Mo rà yín pa dà lóko ẹrú;+

Mo rán Mósè, Áárónì àti Míríámù sí yín.+

 5 Ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ jọ̀ọ́, ẹ rántí ohun tí Bálákì ọba Móábù gbèrò+

Àti ohun tí Báláámù ọmọ Béórì fi dá a lóhùn.+

Ẹ rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ láti Ṣítímù+ títí dé Gílígálì,+

Kí ẹ lè mọ̀ pé òdodo ni Jèhófà ń ṣe.”

 6 Kí ni màá mú wá síwájú Jèhófà?

Kí sì ni màá mú wá tí mo bá wá tẹrí ba fún Ọlọ́run lókè?

Ṣé odindi ẹbọ sísun ni màá gbé wá síwájú rẹ̀,

Àwọn ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?+

 7 Ṣé inú Jèhófà máa dùn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àgbò,

Sí ẹgbẹẹgbàárùn-ún ìṣàn òróró?+

Ṣé màá fi àkọ́bí mi ọkùnrin rúbọ torí ọ̀tẹ̀ tí mo dì,

Àbí màá fi èso ikùn mi rúbọ torí ẹ̀ṣẹ̀ mi?*+

 8 Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ, ìwọ ọmọ aráyé.

Kí sì ni Jèhófà fẹ́ kí o ṣe?*

Bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo,*+ kí o mọyì jíjẹ́ adúróṣinṣin,*+

Kí o sì mọ̀wọ̀n ara rẹ+ bí o ṣe ń bá Ọlọ́run rẹ rìn!+

 9 Àwọn èèyàn ìlú náà gbọ́ ohùn Jèhófà;

Àwọn tó ní ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ yóò bẹ̀rù orúkọ rẹ.

Ẹ fiyè sí ọ̀pá náà àti ẹni tó yàn án.+

10 Ṣé àwọn ìṣúra tí wọ́n fi ìwà ìkà kó jọ ṣì wà nílé ẹni burúkú

Àti òṣùwọ̀n eéfà* tí kò péye tó ń ríni lára?

11 Ṣé mo lè sọ pé ìwà* mi mọ́ tí mo bá ń lo òṣùwọ̀n èké

Àti àpò ayédèrú òkúta òṣùwọ̀n?+

12 Ìwà ipá kún ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ rẹ̀,

Òpùrọ́ ni àwọn tó ń gbé inú rẹ̀;+

Ahọ́n wọn ń tanni jẹ.+

13 “Torí náà, màá lù ọ́, màá sì ṣe ọ́ léṣe;+

Màá sọ ọ́ di ahoro torí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.

14 Wàá jẹun àmọ́ o ò ní yó,

Inú rẹ máa ṣófo.+

Tí o bá tiẹ̀ rí nǹkan kó, o ò ní lè kó o lọ,

Tí o bá sì rí i kó lọ, màá fi í fún idà.

15 Wàá fún irúgbìn, àmọ́ o ò ní ká a.

Wàá tẹ ólífì, àmọ́ o ò ní lo òróró rẹ̀;

Wàá ṣe wáìnì tuntun, àmọ́ o ò ní rí wáìnì mu.+

16 Torí ò ń tẹ̀ lé òfin Ómírì àti gbogbo ohun tí wọ́n ṣe ní ilé Áhábù,+

O sì ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn.

Ìdí nìyẹn tí màá fi mú kí o di ohun tó ń bani lẹ́rù,

Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ yóò sì di ohun àrísúfèé;+

Àwọn èèyàn yóò sì fi ọ́ ṣẹ̀sín.”+

7 Ó mà ṣe fún mi o! Mo dà bí ẹni tí

Kò rí àwọn èso àjàrà jẹ,

Tí kò sì rí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ tó wù ú* jẹ,

Lẹ́yìn tí wọ́n kó èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ,

Tí wọ́n sì ti pèéṣẹ́* lẹ́yìn ìkórè èso àjàrà.

 2 Adúrótini ti tán* ní ayé;

Kò sí olódodo kankan láàárín àwọn èèyàn.+

Gbogbo wọn lúgọ kí wọ́n lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+

Kálukú wọn ń fi àwọ̀n dọdẹ arákùnrin rẹ̀.

 3 Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi ṣe dáadáa;+

Olórí ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn,

Adájọ́ ń béèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+

Gbajúmọ̀ ń sọ ohun tó fẹ́,*+

Wọ́n sì jọ gbìmọ̀ pọ̀.*

 4 Ẹni tó dáa jù nínú wọn dà bí ẹ̀gún,

Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ jù láàárín wọn burú ju ọgbà ẹlẹ́gùn-ún lọ.

Ọjọ́ tí àwọn olùṣọ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti ọjọ́ ìyà rẹ yóò dé.+

Ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.+

 5 Má ṣe gbára lé ẹnì kejì rẹ,

Má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́.+

Máa ṣọ́ ohun tí wàá sọ fún ẹni tó ń sùn sí àyà rẹ.

 6 Torí ọmọkùnrin ń tàbùkù sí bàbá rẹ̀,

Ọmọbìnrin ń bá ìyá rẹ̀ jà,+

Ìyàwó ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀;+

Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.+

 7 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa retí Jèhófà.+

Màá dúró* de Ọlọ́run ìgbàlà mi.+

Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.+

 8 Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi.*

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣubú, màá dìde;

Bí mo tiẹ̀ wà nínú òkùnkùn, Jèhófà yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi.

 9 Èmi yóò fara da ìbínú Jèhófà,

Títí yóò fi gbèjà mi tí yóò sì dá mi láre,

Torí mo ti ṣẹ̀ ẹ́.+

Yóò mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;

Èmi yóò rí òdodo rẹ̀.

10 Ọ̀tá mi pẹ̀lú yóò rí i,

Ojú yóò sì ti ẹni tó ń sọ fún mi pé:

“Jèhófà Ọlọ́run rẹ dà?”+

Ojú mi yóò rí i.

Wọn yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ lójú ọ̀nà.

11 Ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mọ ògiri olókùúta rẹ;

Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sún ààlà síwájú.*

12 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa wá sọ́dọ̀ rẹ

Láti Ásíríà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti láti àwọn ìlú Íjíbítì,

Láti Íjíbítì títí lọ dé Odò;*

Láti òkun dé òkun àti láti òkè dé òkè.+

13 Ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro torí àwọn tó ń gbé ibẹ̀,

Nítorí ohun tí wọ́n ṣe.*

14 Fi ọ̀pá rẹ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ, agbo ẹran tó jẹ́ ogún rẹ,+

Tó ń dá gbé inú igbó, láàárín ọgbà eléso.

Jẹ́ kí Báṣánì àti Gílíádì+ fún wọn ní oúnjẹ bíi ti àtijọ́.

15 “Màá fi àwọn ohun àgbàyanu hàn án,+

Bíi ti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.

16 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú sì máa tì wọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára.+

Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu;

Etí wọn á di.

17 Wọ́n á lá erùpẹ̀ bí ejò;+

Wọ́n á máa gbọ̀n rìrì bí wọ́n ṣe ń jáde látinú ibi ààbò wọn bí àwọn ẹran tó ń fàyà fà.

Wọ́n á wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú ìbẹ̀rù,

Ẹ̀rù rẹ yóò sì bà wọ́n.”+

18 Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run,

Tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà+ àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀?+

Kò ní máa bínú lọ títí láé,

Torí inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.+

19 Ó tún máa ṣàánú wa;+ ó sì máa pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́.*

O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.+

20 O máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jékọ́bù,

Ìfẹ́ tí o ní sí Ábúráhámù kò ní yẹ̀,

Bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa láti ìgbà àtijọ́.+

Ìkékúrú orúkọ náà, Máíkẹ́lì (tó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bí Ọlọ́run?”) tàbí Mikáyà (tó túmọ̀ sí “Ta Ló Dà Bíi Jèhófà?”)

Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Ní Héb., “da.”

Tàbí “gbogbo ohun tó rí gbà nígbà tó lọ ṣe ìṣekúṣe.”

Tàbí “akátá.”

Tàbí “ní ilé Áfírà.”

Ní Héb., “ìwọ obìnrin.”

Ní Héb., “Ìwọ obìnrin.”

Ní Héb., “ìwọ obìnrin.”

Ní Héb., “Ìwọ obìnrin.”

Ní Héb., “Ìwọ obìnrin.”

Tàbí “gba nǹkan ìní.”

Ní Héb., “ẹ kò sì ní lè yọ ọrùn yín.”

Ní Héb., “Àbí ẹ̀mí Jèhófà.”

Tàbí kó jẹ́, “kúrò lára ẹ̀wù.”

Tàbí “ìkòkò ìsebẹ̀ ẹlẹ́nu fífẹ̀.”

Tàbí kó jẹ́, “tí wọ́n bá ń rí nǹkan bù jẹ.”

Ní Héb., “sọ ogun di mímọ́ fún.”

Ní Héb., “irunmú.”

Ní Héb., “orí.”

Tàbí “fàdákà.”

Tàbí “wọ́n ń sọ pé àwọn gbára lé Jèhófà.”

Tàbí “Òkè tẹ́ńpìlì.”

Tàbí “òkìtì igi.”

Tàbí “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí “Ó sì máa ṣàtúnṣe.”

Tàbí “gbé.”

Ní Héb., “obìnrin.”

Ní Héb., “obìnrin.”

Tàbí “àtijọ́.”

Tàbí “ète rẹ̀.”

Tàbí “agbo ilé.”

Tàbí “olórí.”

Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Ní Héb., “tó wà lọ́wọ́ rẹ.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?”

Tàbí “béèrè lọ́wọ́ rẹ.”

Tàbí “ṣe òdodo; má ṣègbè.”

Tàbí “jíjẹ́ onínúure, kí ìfẹ́ rẹ má sì yẹ̀; adúrótini.” Ní Héb., “fẹ́ràn ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Wo Àfikún B14.

Tàbí “ọwọ́.”

Tàbí “wu ọkàn rẹ̀.”

Ó túmọ̀ sí ṣíṣà lára irè oko tí wọ́n bá fi sílẹ̀.

Tàbí “ṣègbé.”

Tàbí “ohun tó wù ú lọ́kàn.”

Ní Héb., “Wọ́n sì jọ hun ún pọ̀.”

Tàbí “Màá fi sùúrù dúró.”

Lédè Hébérù, abo ni wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọ̀tá” fún.

Tàbí kó jẹ́, “àṣẹ náà yóò jìnnà réré.”

Ìyẹn, odò Yúfírétì.

Ní Héb., “Torí èrè iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Tàbí “tẹ àwọn àṣìṣe wa mọ́lẹ̀; tẹ àwọn àṣìṣe wa lórí ba.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́