ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt Hágáì 1:1-2:23
  • Hágáì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Hágáì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Hágáì

HÁGÁÌ

1 Ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso, ní oṣù kẹfà, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà rán wòlíì Hágáì*+ pé kó sọ fún Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pé:

2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Àwọn èèyàn yìí sọ pé: “Kò tíì tó àkókò láti kọ́ ilé* Jèhófà.”’”*+

3 Jèhófà tún rán wòlíì Hágáì+ pé: 4 “Ṣé àsìkò yìí ló yẹ kí ẹ máa gbé inú àwọn ilé yín tí ẹ fi pákó ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, nígbà tí ilé yìí ti di àwókù?+ 5 Ní báyìí, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ kíyè sí* àwọn ohun tí ẹ̀ ń ṣe. 6 Ẹ ti fún irúgbìn tó pọ̀, àmọ́ irè oko díẹ̀ ni ẹ kó.+ Ẹ̀ ń jẹun, àmọ́ ẹ ò yó. Ẹ̀ ń mu, àmọ́ kò tẹ́ yín lọ́rùn. Ẹ̀ ń wọṣọ, àmọ́ ara ẹnì kankan yín ò móoru. Inú ajádìí àpò ni ẹni tí wọ́n gbà síṣẹ́ ń kó owó iṣẹ́ rẹ̀ sí.’”

7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ kíyè sí* àwọn ohun tí ẹ̀ ń ṣe.’

8 “‘Ẹ gun orí òkè lọ, kí ẹ sì gbé igi gẹdú wá.+ Kí ẹ sì kọ́ ilé náà,+ kí inú mi lè dùn sí i, kí a sì lè yìn mí lógo,’+ ni Jèhófà wí.”

9 “‘Ohun tó pọ̀ ni ẹ̀ ń retí, àmọ́ díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí gbà; nígbà tí ẹ sì mú un wá sínú ilé, mo fẹ́ ẹ dà nù.+ Kí nìdí?’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. ‘Torí ilé mi ti di àwókù, kálukú yín sì ń sá kiri kó lè bójú tó ilé tirẹ̀.+ 10 Torí náà, ọ̀run ò sẹ ìrì, ilẹ̀ ò sì mú èso jáde. 11 Mo sì mú kí ọ̀dá wà lórí ayé, lórí àwọn òkè, lórí ọkà, lórí wáìnì tuntun, lórí òróró, lórí ohun tó ń hù lórí ilẹ̀, lórí èèyàn àti ẹran ọ̀sìn àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.’”

12 Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì+ àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà àti gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wọn àti sí ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, torí Jèhófà Ọlọ́run wọn ló rán an; àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù Jèhófà.

13 Hágáì ìránṣẹ́ Jèhófà wá jíṣẹ́ fún àwọn èèyàn bí Jèhófà ṣe rán an pé: “‘Mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni Jèhófà wí.”

14 Torí náà, Jèhófà ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ sókè, ó tún ru ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà sókè àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà; wọ́n wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnkọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.+ 15 Èyí jẹ́ ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso.+

2 Ní ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù keje, Jèhófà rán wòlíì Hágáì+ níṣẹ́ pé: 2 “Jọ̀ọ́, bi Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ àti Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì,+ àlùfáà àgbà àti àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà pé: 3 ‘Ta ló ṣẹ́ kù nínú yín tó rí ilé* yìí nígbà tó ṣì rẹwà?+ Báwo ló ṣe rí lójú yín báyìí? Tí ẹ bá fi wé ti tẹ́lẹ̀, ǹjẹ́ ó ṣì já mọ́ nǹkan kan?’+

4 “‘Àmọ́ ní báyìí, ìwọ Serubábélì, jẹ́ onígboyà. Kí ìwọ Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pẹ̀lú sì jẹ́ onígboyà,’ ni Jèhófà wí.

“‘Kí gbogbo ẹ̀yin èèyàn ilẹ̀ náà pẹ̀lú jẹ́ onígboyà,+ kí ẹ sì ṣiṣẹ́’ ni Jèhófà wí.

“‘Torí mo wà pẹ̀lú yín,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. 5 ‘Ẹ rántí ìlérí tí mo ṣe fún yín nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ̀mí mi wà láàárín yín.*+ Ẹ má bẹ̀rù.’”+

6 “Torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Lẹ́ẹ̀kan sí i, màá mi ọ̀run, ayé, òkun àti ilẹ̀ gbígbẹ jìgìjìgì;+ kò ní pẹ́ mọ́.’

7 “‘Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun iyebíye* nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì wọlé wá;+ èmi yóò sì fi ògo kún ilé yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

8 “‘Tèmi ni fàdákà, tèmi sì ni wúrà,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

9 “‘Ògo tí ilé yìí máa ní yóò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

“‘Èmi yóò sì fún yín ní àlàáfíà ní ibí yìí,’+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”

10 Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹsàn-án, ọdún kejì ìjọba Dáríúsì, Jèhófà sọ fún wòlíì Hágáì+ pé: 11 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Jọ̀ọ́, bi àwọn àlùfáà nípa òfin,+ pé: 12 “Tí èèyàn bá gbé ẹran mímọ́ sí etí aṣọ rẹ̀, tí aṣọ rẹ̀ sì kan búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀ tàbí wáìnì tàbí òróró tàbí oúnjẹ èyíkéyìí, ṣé ó máa di mímọ́?”’”

Àwọn àlùfáà fèsì pé: “Rárá!”

13 Hágáì wá béèrè pé: “Tí ẹnì kan tó ti di aláìmọ́ torí pé ó fara kan òkú* bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí, ṣé ó máa di aláìmọ́?”+

Àwọn àlùfáà fèsì pé: “Ó máa di aláìmọ́.”

14 Hágáì wá sọ pé: “‘Bí àwọn èèyàn yìí ṣe rí nìyẹn, bí orílẹ̀-èdè yìí sì ṣe rí níwájú mi nìyẹn,’ ni Jèhófà wí, ‘bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn rí; ohunkóhun tí wọ́n bá mú wá síbẹ̀ jẹ́ aláìmọ́.’

15 “‘Àmọ́ ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ kíyè sí* èyí láti òní lọ: Kí wọ́n tó gbé òkúta kan lé òmíràn ní tẹ́ńpìlì Jèhófà,+ 16 báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà yẹn? Tí ẹnì kan bá wá síbi tí wọ́n ń kó ọkà jọ sí, tó ń retí ogún (20) òṣùwọ̀n, mẹ́wàá péré ló máa rí; tí ẹnì kan bá sì wá láti bu àádọ́ta (50) òṣùwọ̀n nínú ọpọ́n wáìnì, ogún (20) péré ló máa rí;+ 17 mo fi ooru tó ń jó nǹkan gbẹ àti èbíbu+ àti yìnyín kọ lù yín, àní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, àmọ́ ẹnì kankan lára yín ò pa dà sọ́dọ̀ mi,’ ni Jèhófà wí.

18 “‘Ẹ jọ̀ọ́, ẹ kíyè sí* èyí láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án, láti ọjọ́ tí wọ́n ti fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì Jèhófà lélẹ̀;+ ẹ kíyè sí ọ̀rọ̀ yìí: 19 Ṣé irúgbìn ṣì wà nínú ilé ìkẹ́rùsí?*+ Àjàrà, igi ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì àti ólífì kò tíì so, àbí wọ́n ti so? Láti òní lọ, èmi yóò bù kún yín.’”+

20 Jèhófà tún bá Hágáì sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀kejì ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà,+ ó ní: 21 “Sọ fún Serubábélì, gómìnà Júdà pé, ‘Èmi yóò mi ọ̀run àti ayé jìgìjìgì.+ 22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, èmi yóò sì gba agbára lọ́wọ́ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè;+ èmi yóò bi kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn tó gùn ún ṣubú, àwọn ẹṣin àti àwọn tó gùn wọ́n yóò sì ṣubú, kálukú wọn yóò sì fi idà pa arákùnrin rẹ̀.’”+

23 “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘èmi yóò mú ìwọ ìránṣẹ́ mi, Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì,’+ ni Jèhófà wí, ‘èmi yóò sì ṣe ọ́ bí òrùka èdìdì, torí ìwọ ni ẹni tí mo yàn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Wọ́n Bí Nígbà Àjọyọ̀.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Tàbí “tún ilé Jèhófà kọ́.”

Tàbí “Ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”

Tàbí “Ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”

Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Tàbí kó jẹ́, “nígbà tí ẹ̀mí mi dúró sáàárín yín.”

Tàbí “ohun tó fani lọ́kàn mọ́ra.”

Tàbí “nípasẹ̀ ọkàn kan.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”

Tàbí “ẹ fara balẹ̀ ronú nípa.”

Tàbí “kòtò ọkà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́