ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 1 Tẹsalóníkà 1:1-5:28
  • 1 Tẹsalóníkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Tẹsalóníkà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Tẹsalóníkà

ÌWÉ KÌÍNÍ SÍ ÀWỌN ARÁ TẸSALÓNÍKÀ

1 Pọ́ọ̀lù, Sílífánù*+ àti Tímótì,+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Olúwa:

Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà wà pẹ̀lú yín.

2 Ìgbà gbogbo là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tí a bá ń rántí gbogbo yín nínú àdúrà wa,+ 3 torí a ò lè ṣe ká má rántí iṣẹ́ tí ìgbàgbọ́ mú kí ẹ ṣe àti ìsapá onífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfaradà yín nítorí ìrètí tí ẹ ní+ nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. 4 Ẹ̀yin ará tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, a mọ̀ pé òun ló yàn yín, 5 nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ nìkan ni ìhìn rere tí à ń wàásù fi dé ọ̀dọ̀ yín, ó tún wá nípasẹ̀ agbára, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ àti nípasẹ̀ ìdánilójú tó lágbára, bí ẹ ṣe mọ irú ẹni tí a dà láàárín yín àti nítorí yín. 6 Ẹ sì ń fara wé àwa+ àti Olúwa,+ bí ẹ ṣe tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú+ pẹ̀lú ayọ̀ ẹ̀mí mímọ́, 7 débi pé ẹ di àpẹẹrẹ fún gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ní Makedóníà àti ní Ákáyà.

8 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ Jèhófà* ti dún jáde látọ̀dọ̀ yín ní Makedóníà àti Ákáyà nìkan ni, àmọ́ ìgbàgbọ́ yín nínú Ọlọ́run ti tàn káàkiri níbi gbogbo,+ débi pé a kò nílò láti sọ ohunkóhun. 9 Nítorí àwọn fúnra wọn ń ròyìn nípa bí a ṣe kọ́kọ́ dé ọ̀dọ̀ yín àti bí ẹ ṣe fi àwọn òrìṣà yín sílẹ̀,+ tí ẹ sì yíjú sọ́dọ̀ Ọlọ́run kí ẹ lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè, 10 kí ẹ sì lè dúró de Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run,+ ẹni tó gbé dìde kúrò nínú ikú, ìyẹn Jésù tó gbà wá sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìrunú tó ń bọ̀.+

2 Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dájú pé ìbẹ̀wò tí a ṣe sọ́dọ̀ yín kò já sí asán.+ 2 Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ́kọ́ jìyà, tí wọ́n sì hùwà àfojúdi sí wa ní ìlú Fílípì,+ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le* kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run+ fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.* 3 Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kò wá látinú ìṣìnà tàbí látinú ìwà àìmọ́ tàbí pẹ̀lú ẹ̀tàn, 4 àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gbà wá pé kí ìhìn rere wà ní ìkáwọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí ká lè wu èèyàn, àmọ́ torí ká lè wu Ọlọ́run, ẹni tó ń yẹ ọkàn wa wò.+

5 Kódà, ẹ mọ̀ pé kò sí ìgbà kankan tí a sọ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni tàbí tí a ṣe ojú ayé nítorí ohun tí a fẹ́ rí gbà;*+ Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí! 6 Bẹ́ẹ̀ ni a kò máa wá ògo lọ́dọ̀ èèyàn, ì báà jẹ́ lọ́dọ̀ yín tàbí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi, àwa fúnra wa lè sọ ara wa di ẹrù tó wúwo sí yín lọ́rùn.+ 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, a di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú* àwọn ọmọ rẹ̀. 8 Torí náà, bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu* pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara* wa,+ torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.+

9 Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ rántí òpò* àti làálàá wa. A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn,+ nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín. 10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, bí a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìlẹ́bi sí ẹ̀yin onígbàgbọ́. 11 Ẹ mọ̀ dáadáa pé ṣe là ń gbà yín níyànjú, tí à ń tù yín nínú, tí a sì ń jẹ́rìí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín,+ bí bàbá+ ṣe máa ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, 12 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó ń pè yín sí Ìjọba+ àti ògo rẹ̀.+

13 Ní tòótọ́, ìdí nìyẹn tí àwa náà fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo,+ torí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó tún wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́. 14 Ẹ̀yin ará ń fara wé àwọn ìjọ Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ní Jùdíà, nítorí àwọn ará ìlú yín ń fìyà jẹ yín  + bí àwọn Júù ṣe ń fìyà jẹ àwọn náà, 15 kódà wọ́n pa Jésù Olúwa+ àti àwọn wòlíì, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wa.+ Bákan náà, wọn ò ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, wọn ò sì ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn, 16 bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́ ká má lè bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀ sí i. Àmọ́ ìrunú Ọlọ́run ti dé tán sórí wọn.+

17 Ẹ̀yin ará, nígbà tí wọ́n yà wá kúrò lọ́dọ̀ yín* fún àkókò kúkúrú (nínú ara, tí kì í ṣe nínú ọkàn wa), àárò yín tó ń sọ wá gan-an mú ká sa gbogbo ipá wa láti rí yín lójúkojú.* 18 Torí náà, a fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni, èmi Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú láti wá, kódà kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹ̀mejì ni; àmọ́ Sátánì dí wa lọ́nà. 19 Nítorí kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni?+ 20 Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.

3 Torí náà, nígbà tí a ò lè mú un mọ́ra mọ́, a rí i pé á dára kí àwa nìkan dúró sí Áténì;+ 2 a sì rán Tímótì,+ arákùnrin wa àti òjíṣẹ́* Ọlọ́run nínú ìhìn rere nípa Kristi, kí ó lè mú kí ẹ fìdí múlẹ̀,* kí ó sì tù yín nínú nítorí ìgbàgbọ́ yín, 3 kí àwọn ìpọ́njú yìí má bàa mú ẹnì kankan yẹsẹ̀.* Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé kò sí bí a ò ṣe ní jìyà irú àwọn nǹkan yìí.*+ 4 Nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń sọ fún yín pé a máa ní ìpọ́njú, ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn, bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀.+ 5 Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí mi ò lè mú un mọ́ra mọ́, mo ránṣẹ́ kí n lè mọ̀ nípa ìdúróṣinṣin yín,+ pé bóyá lọ́nà kan, Adánniwò+ lè ti dán yín wò, kí làálàá wa sì ti já sí asán.

6 Àmọ́ Tímótì ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ọ̀dọ̀ wa látọ̀dọ̀ yín ni,+ ó sì ti fún wa ní ìròyìn ayọ̀ nípa ìdúróṣinṣin yín àti ìfẹ́ yín, pé ìgbà gbogbo ni inú yín máa ń dùn tí ẹ bá rántí wa, àárò wa sì ń sọ yín bí tiyín ṣe ń sọ àwa náà. 7 Ẹ̀yin ará, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nínú gbogbo wàhálà* wa àti ìpọ́njú wa, a ti rí ìtùnú gbà nítorí yín àti nítorí ìdúróṣinṣin tí ẹ ní.+ 8 Torí pé à ń mú wa sọ jí,* tí ẹ bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. 9 Báwo ni ká ṣe dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí yín lórí ayọ̀ púpọ̀ tí ẹ̀ ń mú ká ní níwájú Ọlọ́run wa? 10 Tọ̀sántòru là ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ taratara ká lè fojú kàn yín,* ká sì fún yín ní àwọn ohun tí á mú kí ìgbàgbọ́ yín lágbára.+

11 Tóò, kí Ọlọ́run àti Baba wa fúnra rẹ̀ àti Jésù Olúwa wa ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti wá sọ́dọ̀ yín. 12 Yàtọ̀ síyẹn, kí Olúwa mú kí ẹ pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni, kí ó mú kí ẹ pọ̀ gidigidi nínú ìfẹ́ sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan+ àti sí gbogbo èèyàn, bí àwa náà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín, 13 kí ó lè mú kí ọkàn yín fìdí múlẹ̀, kí ó jẹ́ aláìlẹ́bi nínú jíjẹ́ mímọ́ níwájú Ọlọ́run+ àti Baba wa nígbà tí Jésù Olúwa wa+ bá wà níhìn-ín pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

4 Lákòótán, ẹ̀yin ará, bí ẹ ṣe gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ wa nípa bó ṣe yẹ kí ẹ máa rìn kí ẹ lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́,+ tí ẹ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, a fi Jésù Olúwa bẹ̀ yín, a sì tún fi rọ̀ yín pé kí ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 2 Nítorí ẹ mọ àwọn ìtọ́ni* tí a fún yín nípasẹ̀ Jésù Olúwa.

3 Ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ nìyí, pé kí ẹ jẹ́ mímọ́,+ kí ẹ sì ta kété sí ìṣekúṣe.*+ 4 Kí ẹnì kọ̀ọ̀kan yín mọ bó ṣe máa kó ara* rẹ̀ níjàánu+ nínú jíjẹ́ mímọ́  + àti nínú iyì, 5 kì í ṣe nínú ojúkòkòrò ìbálòpọ̀ tí kò níjàánu+ bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ Ọlọ́run.+ 6 Kí ẹnikẹ́ni má kọjá ààlà tó yẹ, kó má sì yan arákùnrin rẹ̀ jẹ nínú ọ̀ràn yìí, torí Jèhófà* ń fìyà jẹni nítorí gbogbo àwọn nǹkan yìí, bí a ṣe sọ fún yín ṣáájú, tí a sì tún kìlọ̀ fún yín gidigidi. 7 Nítorí Ọlọ́run pè wá fún jíjẹ́ mímọ́, kì í ṣe fún ìwà àìmọ́.+ 8 Torí náà, ẹni tí kò bá ka èyí sí, kì í ṣe èèyàn ni kò kà sí, Ọlọ́run+ tó ń fún yín ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀+ ni kò kà sí.

9 Àmọ́, ní ti ìfẹ́ ará,+ ẹ kò nílò ká kọ̀wé sí yín, nítorí Ọlọ́run ti kọ́ yín láti máa nífẹ̀ẹ́ ara yín.+ 10 Kódà, ẹ̀ ń ṣe bẹ́ẹ̀ sí gbogbo àwọn ará ní gbogbo Makedóníà. Àmọ́, ẹ̀yin ará, a rọ̀ yín pé kí ẹ máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. 11 Ẹ fi ṣe àfojúsùn yín láti máa ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,+ ẹ má yọjú sí ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀,+ kí ẹ máa fi ọwọ́ yín ṣiṣẹ́,+ bí a ṣe sọ fún yín, 12 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó bójú mu lójú àwọn tó wà níta,+ kí ẹ má sì ṣe aláìní ohunkóhun.

13 Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ̀* nípa àwọn tó ń sùn nínú ikú,+ kí ẹ má bàa banú jẹ́ bí àwọn tí kò ní ìrètí ṣe máa ń ṣe.+ 14 Nítorí tí a bá nígbàgbọ́ pé Jésù kú, ó sì jí dìde,+ lọ́nà kan náà, Ọlọ́run yóò mú àwọn tó ti sùn nínú ikú nítorí Jésù wá sí ìyè pẹ̀lú rẹ̀.+ 15 Nítorí ohun tí a sọ fún yín nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jèhófà* nìyí, pé àwa alààyè tí a bá kù nílẹ̀ di ìgbà tí Olúwa bá wà níhìn-ín kò ní ṣáájú àwọn tó ti sùn nínú ikú lọ́nàkọnà; 16 nítorí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run pẹ̀lú ìpè àṣẹ, pẹ̀lú ohùn olú áńgẹ́lì+ àti pẹ̀lú kàkàkí Ọlọ́run, àwọn tó ti kú nínú Kristi ló sì máa kọ́kọ́ dìde.+ 17 Lẹ́yìn náà, àwa alààyè tí a kù nílẹ̀ ni a ó gbà lọ pẹ̀lú wọn nínú àwọsánmà+ láti pàdé Olúwa+ nínú afẹ́fẹ́; a ó sì tipa báyìí máa wà pẹ̀lú Olúwa nígbà gbogbo.+ 18 Nítorí náà, ẹ máa fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí tu ara yín nínú.

5 Ẹ̀yin ará, ní ti àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò, ẹ ò nílò kí a kọ nǹkan kan ránṣẹ́ sí yín. 2 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà*+ ń bọ̀ bí olè ní òru.+ 3 Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn,+ bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà. 4 Àmọ́, ẹ̀yin ará, ẹ ò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn á fi dé bá yín lójijì bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè, 5 nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán.+ Àwa kì í ṣe ti òru tàbí ti òkùnkùn.+

6 Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò,+ kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́.+ 7 Nítorí àwọn tó ń sùn máa ń sùn ní òru, àwọn tó sì ń mutí yó máa ń mutí yó ní òru.+ 8 Àmọ́ ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa ronú bó ṣe tọ́, kí a gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀, kí a sì dé ìrètí ìgbàlà bí akoto*+ 9 nítorí Ọlọ́run kò yàn wá fún ìrunú, bí kò ṣe láti rí ìgbàlà+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa. 10 Ó kú fún wa,+ kó lè jẹ́ pé, bóyá a sùn* tàbí a ò sùn, a máa lè wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ 11 Nítorí náà, ẹ máa fún ara yín níṣìírí,* kí ẹ sì máa gbé ara yín ró,+ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.

12 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń gbà yín níyànjú; 13 ẹ máa kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.+ Ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.+ 14 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège,*+ ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́,* ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.+ 15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+

16 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.+ 17 Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.+ 18 Ẹ máa dúpẹ́ ohun gbogbo.+ Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún yín nìyí nínú Kristi Jésù. 19 Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.+ 20 Ẹ má ṣe kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.+ 21 Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú;+ ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin. 22 Ẹ yẹra fún gbogbo ìwà burúkú.+

23 Kí Ọlọ́run àlàáfíà fúnra rẹ̀ sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí ẹ̀mí àti ọkàn* àti ara ẹ̀yin ará, tó dára ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ aláìlẹ́bi nígbà tí Olúwa wa Jésù Kristi bá wà níhìn-ín.+ 24 Ẹni tó ń pè yín jẹ́ olóòótọ́, ó sì dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.

25 Ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa.+

26 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn ará.

27 Mò ń fi dandan lé e fún yín ní orúkọ Olúwa pé kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.+

28 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú yín.

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.

Wo Àfikún A5.

Tàbí “nígboyà.”

Tàbí kó jẹ́, “nínú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.”

Ní Héb., “ojúkòkòrò.”

Tàbí “ṣìkẹ́.”

Ní Grk., “ó dùn mọ́ wa pé.”

Tàbí “ọkàn.”

Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”

Tàbí “gbà yín kúrò lọ́wọ́ wa.”

Ní Grk., “rí ojú yín.”

Tàbí kó jẹ́, “alábàáṣiṣẹ́ pẹ̀lú.”

Tàbí “fún yín lókun.”

Tàbí “mi ẹnikẹ́ni nínú yín.”

Tàbí “pé a ti yàn wá fún àwọn nǹkan yìí.”

Ní Grk., “àìní.”

Ní Grk., “a wà láàyè.”

Ní Grk., “rí ojú yín.”

Tàbí “àwọn àṣẹ.”

Lédè Gíríìkì, por·neiʹa. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Ní Grk., “ohun èlò.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “a ò fẹ́ kí ẹ ṣaláìmọ̀.”

Wo Àfikún A5.

Wo Àfikún A5.

Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.

Tàbí “sùn nínú ikú.”

Tàbí “tu ara yín nínú.”

Tàbí “gba àwọn tó ń ṣe ségesège níyànjú.”

Tàbí “àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì.” Ní Grk., “àwọn tó ní ọkàn kékeré.”

Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́