ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 1 Tímótì 1:1-6:21
  • 1 Tímótì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 Tímótì
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Tímótì

ÌWÉ KÌÍNÍ SÍ TÍMÓTÌ

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì Kristi Jésù nípasẹ̀ àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa àti ti Kristi Jésù, ìrètí wa,+ 2 sí Tímótì,*+ ọmọ gidi+ nínú ìgbàgbọ́:

Kí o ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àánú àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Kristi Jésù Olúwa wa.

3 Bí mo ṣe gbà ọ́ níyànjú nígbà tí mo fẹ́ lọ sí Makedóníà pé kí o dúró ní Éfésù, bẹ́ẹ̀ náà ni mò ń ṣe báyìí, kí o lè pàṣẹ fún àwọn kan pé kí wọ́n má ṣe fi ẹ̀kọ́ tó yàtọ̀ kọ́ni, 4 kí wọ́n má sì tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ àti àwọn ìtàn ìdílé. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò wúlò rárá,+ ṣe ló ń mú káwọn èèyàn máa méfò dípò kó máa fúnni ní ohunkóhun látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́. 5 Ní tòótọ́, ìdí tí mo fi ń sọ ìtọ́ni* yìí jẹ́ nítorí ìfẹ́+ látinú ọkàn tó mọ́, látinú ẹ̀rí ọkàn rere àti látinú ìgbàgbọ́+ tí kò ní àgàbàgebè. 6 Torí àwọn kan ti pa àwọn nǹkan yìí tì, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀.+ 7 Wọ́n fẹ́ di olùkọ́+ òfin, àmọ́ wọn ò lóye àwọn ohun tí wọ́n ń sọ àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń tẹnu mọ́ pé ó dá àwọn lójú.

8 A mọ̀ pé Òfin dáa tí èèyàn bá tẹ̀ lé e bó ṣe yẹ,* 9 ó yé wa pé torí olódodo kọ́ ni òfin ṣe wà, àmọ́ ó wà torí àwọn arúfin  + àtàwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, àwọn aláìṣòótọ́* àti aláìmọ́, àwọn tó ń pa bàbá àti àwọn tó ń pa ìyá, àwọn apààyàn, 10 àwọn oníṣekúṣe,* àwọn ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lò pọ̀,* àwọn ajínigbé, àwọn òpùrọ́, àwọn tó ń parọ́ nílé ẹjọ́* àti torí gbogbo àwọn nǹkan míì tó ta ko ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní*+ 11 tó bá ìhìn rere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀ mu, èyí tí a fi sí ìkáwọ́ mi.+

12 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Kristi Jésù Olúwa wa, tó fún mi lágbára, torí ó kà mí sí olóòótọ́ ní ti pé ó fún mi ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan,+ 13 bó tiẹ̀ jẹ́ pé asọ̀rọ̀ òdì ni mí tẹ́lẹ̀, mo máa ń ṣe inúnibíni, mo sì jẹ́ aláfojúdi.+ Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, torí àìmọ̀kan ni mo fi hùwà, mi ò sì ní ìgbàgbọ́. 14 Àmọ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa pọ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tó wà nínú Kristi Jésù. 15 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé, ó sì yẹ ká gbà á délẹ̀délẹ̀, pé: Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.+ Èmi sì ni ẹni àkọ́kọ́ lára wọn.+ 16 Síbẹ̀, a fi àánú hàn sí mi, kó lè jẹ́ pé nípasẹ̀ èmi tí mo jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ nínú ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi Jésù máa fi gbogbo sùúrù rẹ̀ hàn, kó lè fi mí ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tó máa gbà á gbọ́ kí wọ́n lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.+

17 Nítorí náà, kí ọlá àti ògo máa jẹ́ ti Ọba ayérayé,+ ẹni tí kò lè díbàjẹ́,+ tí a kò lè rí,+ Ọlọ́run kan ṣoṣo,+ títí láé àti láéláé. Àmín.

18 Tímótì ọmọ mi, mo fi ìtọ́ni* yìí sí ìkáwọ́ rẹ, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn nǹkan tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ, pé kí o lè máa fi wọ́n ja ogun rere,+ 19 kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀, kí o sì máa ní ẹ̀rí ọkàn rere,+ èyí tí àwọn kan ti sọ nù, tó sì ti mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì. 20 Híméníọ́sì+ àti Alẹkisáńdà wà lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, mo sì ti fi wọ́n lé Sátánì lọ́wọ́,+ kí a lè fi ìbáwí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ òdì mọ́.

2 Torí náà, mò ń pàrọwà fún yín ṣáájú ohun gbogbo pé kí ẹ máa rawọ́ ẹ̀bẹ̀, kí ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ máa dúpẹ́, kí ẹ sì máa bẹ̀bẹ̀ torí onírúurú èèyàn, 2 kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ torí àwọn ọba àti gbogbo àwọn tó wà ní ipò gíga,*+ ká lè máa gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, bí a ti ń fi gbogbo ọkàn wa sin Ọlọ́run, tí a sì ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan.+ 3 Èyí dáa, ó sì ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run, Olùgbàlà wa,+ 4 ẹni tó fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là,+ kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́. 5 Torí Ọlọ́run kan ló wà+ àti alárinà kan+ láàárín Ọlọ́run àtàwọn èèyàn,+ ọkùnrin kan, Kristi Jésù,+ 6 ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà tó bá a mu rẹ́gí fún gbogbo èèyàn*+—ohun tí a máa jẹ́rìí sí nìyí tí àkókò rẹ̀ bá tó. 7 Torí ìjẹ́rìí yìí  + ni a ṣe yàn mí láti jẹ́ oníwàásù àti àpọ́sítélì+—òótọ́ ni mò ń sọ, mi ò parọ́—olùkọ́ àwọn orílẹ̀-èdè+ ní ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.

8 Nítorí náà, ní ibi gbogbo mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́* sókè,+ láìsí ìbínú+ àti fífa ọ̀rọ̀.+ 9 Bákan náà, kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tó bójú mu* ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀,* kì í ṣe dídi irun lọ́nà àrà àti lílo wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ olówó ńlá,+ 10 àmọ́ kó jẹ́ lọ́nà tó yẹ àwọn obìnrin tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn,+ ìyẹn nípa àwọn iṣẹ́ rere.

11 Kí obìnrin kẹ́kọ̀ọ́ ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́* kó sì máa tẹrí ba délẹ̀délẹ̀.+ 12 Mi ò fọwọ́ sí kí obìnrin kọ́ni tàbí kó pàṣẹ lé ọkùnrin lórí, àmọ́ kí ó dákẹ́.*+ 13 Torí Ádámù ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, kó tó wá dá Éfà.+ 14 Bákan náà, a kò tan Ádámù jẹ, àmọ́ a tan obìnrin náà jẹ pátápátá,+ ó sì di arúfin. 15 Síbẹ̀, ọmọ bíbí máa dáàbò bò ó,+ tó* bá rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìjẹ́mímọ́ àti àròjinlẹ̀.*+

3 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé: Tí ọkùnrin kan bá ń sapá láti di alábòójútó,+ iṣẹ́ rere ló fẹ́ ṣe. 2 Nítorí náà, alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí kò lẹ́gàn, tí kò ní ju ìyàwó kan lọ, tí kì í ṣe àṣejù, tó ní àròjinlẹ̀,*+ tó wà létòlétò, tó ń ṣe aájò àlejò,+ tó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni,+ 3 kì í ṣe ọ̀mùtí,+ kì í ṣe oníwà ipá,* àmọ́ kó máa fòye báni lò,+ kì í ṣe oníjà,+ kì í ṣe ẹni tó fẹ́ràn owó,+ 4 kó jẹ́ ọkùnrin tó ń bójú tó* ilé rẹ̀ dáadáa, tí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń tẹrí ba, tí wọ́n sì jẹ́ onígbọràn+ 5 (torí tí ọkùnrin kan ò bá mọ bó ṣe máa bójú tó* ilé ara rẹ̀, báwo ló ṣe máa bójú tó ìjọ Ọlọ́run?), 6 kì í ṣe ẹni tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yí lọ́kàn pa dà,+ torí ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbéra ga, kó sì ṣubú sínú ìdájọ́ tí a ṣe fún Èṣù. 7 Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kí àwọn tó wà níta+ máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa* kó má bàa ṣubú sínú ẹ̀gàn* àti pańpẹ́ Èṣù.

8 Bákan náà, kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, kí wọ́n má ṣe jẹ́ ẹlẹ́nu méjì,* kí wọ́n má ṣe máa mu ọtí* lámujù, kí wọ́n má ṣe máa wá èrè tí kò tọ́,+ 9 kí wọ́n ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́+ bí wọ́n ti ń rọ̀ mọ́ àṣírí mímọ́ ti ìgbàgbọ́.

10 Bákan náà, ká kọ́kọ́ dán wọn wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n;* lẹ́yìn náà kí wọ́n di òjíṣẹ́, nítorí wọn ò ní ẹ̀sùn lọ́rùn.+

11 Kí àwọn obìnrin pẹ̀lú jẹ́ ẹni tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan, kí wọ́n má ṣe jẹ́ abanijẹ́,+ kí wọ́n má ṣe jẹ́ aláṣejù, kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun gbogbo.+

12 Kí àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ má ṣe ní ju ìyàwó kan lọ, kí wọ́n máa bójú tó àwọn ọmọ wọn àti ìdílé wọn dáadáa. 13 Torí àwọn ọkùnrin tó ń ṣe ìránṣẹ́ lọ́nà tó dáa ń ṣe orúkọ rere fún ara wọn, wọ́n á sì lè sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Kristi Jésù.

14 Bí mo tiẹ̀ ń retí láti wá sọ́dọ̀ rẹ láìpẹ́, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí ọ, 15 torí tí mi ò bá tètè dé, kí o lè mọ bó ṣe yẹ kí o máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run,+ tó jẹ́ ìjọ Ọlọ́run alààyè, òpó àti ìtìlẹyìn òtítọ́. 16 Ní tòótọ́, a gbà pé àṣírí mímọ́ ti ìfọkànsin Ọlọ́run yìí ga lọ́lá: ‘A fi í hàn nínú ẹran ara,+ a kéde pé ó jẹ́ olódodo nínú ẹ̀mí,+ ó fara han àwọn áńgẹ́lì,+ a wàásù nípa rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ a gbà á gbọ́ ní ayé,+ a sì gbà á sókè nínú ògo.’

4 Àmọ́, ọ̀rọ̀ onímìísí* sọ ní kedere pé tó bá yá àwọn kan máa yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n á máa tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí*+ tó ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù, 2 nípasẹ̀ àgàbàgebè àwọn èèyàn tó ń parọ́,+ bíi pé irin ìsàmì ti dá àpá sí ẹ̀rí ọkàn wọn. 3 Wọ́n ka ìgbéyàwó léèwọ̀,+ wọ́n pàṣẹ pé kí àwọn èèyàn yẹra fún àwọn oúnjẹ+ tí Ọlọ́run dá pé kí àwọn tó ní ìgbàgbọ́+ tí wọ́n sì mọ òtítọ́ tó péye máa jẹ,+ kí wọ́n sì máa dúpẹ́. 4 Torí gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá ló dára,+ kò sì yẹ ká kọ ohunkóhun+ tí a bá fi ìdúpẹ́ gbà á, 5 nítorí a ti sọ ọ́ di mímọ́ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà tí a gbà sórí rẹ̀.

6 Tí o bá fún àwọn ará ní ìtọ́ni yìí, o máa jẹ́ òjíṣẹ́ rere fún Kristi Jésù, tí a fi àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ bọ́ àti ẹ̀kọ́ rere, èyí tí o ti tẹ̀ lé pẹ́kípẹ́kí.+ 7 Àmọ́, má ṣe tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké+ tí kò buyì kúnni, irú èyí tí àwọn obìnrin tó ti darúgbó máa ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ́ ara rẹ láti fi ìfọkànsin Ọlọ́run ṣe àfojúsùn rẹ. 8 Torí àǹfààní díẹ̀ wà nínú eré ìmárale,* àmọ́ ìfọkànsin Ọlọ́run ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, ní ti pé ó ní ìlérí ìwàláàyè ní báyìí àti ìlérí ìwàláàyè ti ọjọ́ iwájú.+ 9 Ọ̀rọ̀ náà ṣeé gbára lé, ó sì yẹ ká gbà á délẹ̀délẹ̀. 10 Ìdí nìyí tí a fi ń ṣiṣẹ́ kára, tí a sì ń sa gbogbo ipá wa,+ torí a ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, tó jẹ́ Olùgbàlà+ onírúurú èèyàn,+ ní pàtàkì àwọn olóòótọ́.

11 Máa pa àṣẹ yìí fúnni, kí o sì máa fi kọ́ni. 12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fojú ọmọdé wò ọ́ rárá. Àmọ́, kí o jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn olóòótọ́ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.* 13 Títí màá fi dé, máa tẹra mọ́ kíkàwé fún ìjọ,*+ máa gbani níyànjú,* kí o sì máa kọ́ni. 14 Má fojú kéré ẹ̀bùn tí o ní, èyí tí a fún ọ nípasẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà gbé ọwọ́ lé ọ.+ 15 Máa ronú* lórí àwọn nǹkan yìí; jẹ́ kó gbà ọ́ lọ́kàn, kí gbogbo èèyàn lè rí i kedere pé ò ń tẹ̀ síwájú. 16 Máa kíyè sí ara rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ+ nígbà gbogbo. Rí i pé o ò jáwọ́ nínú ṣíṣe àwọn nǹkan yìí, torí tí o bá ń ṣe é, wàá lè gba ara rẹ àti àwọn tó ń fetí sí ọ là.+

5 Má ṣe fi ọ̀rọ̀ líle bá àgbà ọkùnrin wí.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kí o pàrọwà fún un bíi bàbá, pàrọwà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin bí ọmọ ìyá, 2 àwọn àgbà obìnrin bí ìyá, àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí ọmọ ìyá, pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.

3 Máa gba ti àwọn opó rò,* àwọn tí wọ́n jẹ́ opó lóòótọ́.*+ 4 Àmọ́ tí opó èyíkéyìí bá ní àwọn ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, kí wọ́n kọ́kọ́ fi ìfọkànsin Ọlọ́run hùwà nínú ilé tiwọn,+ kí wọ́n sì san àwọn ohun tó yẹ pa dà fún àwọn òbí wọn àti àwọn òbí wọn àgbà,+ torí inú Ọlọ́run dùn sí èyí.+ 5 Obìnrin tó jẹ́ opó lóòótọ́, tí a sì fi sílẹ̀ láìní nǹkan kan, nírètí nínú Ọlọ́run,+ ó túbọ̀ ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀, ó sì ń gbàdúrà tọ̀sántòru.+ 6 Àmọ́ èyí tó ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn ti kú bó tiẹ̀ ṣì wà láàyè. 7 Torí náà, máa fún wọn ní àwọn ìtọ́ni* yìí, kí wọ́n má bàa ní ẹ̀gàn. 8 Ó dájú pé tí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún ìdílé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.+

9 Kí ẹ kọ orúkọ opó tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò bá dín ní ọgọ́ta (60) ọdún sílẹ̀, tó jẹ́ ìyàwó ọkùnrin kan tẹ́lẹ̀, 10 tí wọ́n mọ̀ sí ẹni tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rere,+ tó bá tọ́ àwọn ọmọ,+ tó bá ṣe aájò àlejò,+ tó bá fọ ẹsẹ̀ àwọn ẹni mímọ́,+ tó bá ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìyà ń jẹ,+ tó sì ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rere tọkàntọkàn.

11 Àmọ́ ṣá o, ẹ má kọ orúkọ àwọn opó tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré sílẹ̀, torí tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ bá ń dí wọn lọ́wọ́ ìfẹ́ ti Kristi, wọ́n á fẹ́ ní ọkọ. 12 A máa dá wọn lẹ́jọ́ torí wọ́n ti pa ìgbàgbọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ní* tì. 13 Bákan náà, wọ́n tún sọ ara wọn di aláìníṣẹ́, wọ́n ń tọ ojúlé kiri; àní, kì í ṣe pé wọn ò níṣẹ́ nìkan, wọ́n tún ń ṣòfófó, wọ́n sì ń tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀,+ wọ́n ń sọ àwọn nǹkan tí kò yẹ kí wọ́n sọ. 14 Torí náà, ó wù mí kí àwọn opó tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré ní ọkọ,+ kí wọ́n bímọ,+ kí wọ́n máa tọ́jú ilé, kí wọ́n má bàa fàyè gba àwọn alátakò láti fẹ̀sùn kàn wọ́n. 15 Kódà, àwọn kan ti fi ọ̀nà òtítọ́ sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé Sátánì. 16 Tí obìnrin èyíkéyìí tó jẹ́ onígbàgbọ́ bá ní àwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ opó, kó ràn wọ́n lọ́wọ́, kí wọ́n má bàa di ẹrù ìjọ. Ìjọ á sì lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tó jẹ́ opó ní tòótọ́.*+

17 Ó yẹ ká fún àwọn alàgbà tó ń ṣe àbójútó lọ́nà tó dáa+ ní ọlá ìlọ́po méjì,+ pàápàá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.+ 18 Torí ìwé mímọ́ sọ pé, “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà,”+ àti pé, “Owó iṣẹ́ tọ́ sí òṣìṣẹ́.”+ 19 Má ṣe gba ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àgbà ọkùnrin,* àfi tí ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá jẹ́rìí sí i.+ 20 Bá àwọn tó sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà+ wí+ níṣojú gbogbo àwùjọ náà, kó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn yòókù.* 21 Mo pàṣẹ tó rinlẹ̀ yìí fún ọ níwájú Ọlọ́run àti Kristi Jésù àti àwọn áńgẹ́lì àyànfẹ́ pé kí o máa tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni yìí láìṣe ẹ̀tanú tàbí ojúsàájú.+

22 Má fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé;*+ má sì pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíì; jẹ́ oníwà mímọ́.

23 Má mu omi mọ́,* àmọ́ máa mu wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ àti àìsàn rẹ tó ń ṣe lemọ́lemọ́.

24 Àwọn kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn máa ń hàn sí ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì máa ń yọrí sí ìdájọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àmọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn míì máa ń hàn síta nígbà tó bá yá.+ 25 Bákan náà, iṣẹ́ rere máa ń hàn síta,+ a ò sì lè fi àwọn tí kò hàn síta pa mọ́ lọ títí.+

6 Kí àwọn tó jẹ́ ẹrú* máa ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún àwọn olúwa wọn,+ kí àwọn èèyàn má bàa sọ̀rọ̀ àbùkù nípa orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.+ 2 Bákan náà, kí àwọn tí olúwa wọn jẹ́ onígbàgbọ́ má ṣe hùwà àìlọ́wọ̀ sí wọn torí wọ́n jẹ́ ará. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n túbọ̀ máa ṣe ìránṣẹ́, torí àwọn tó ń jàǹfààní iṣẹ́ ìsìn rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti àyànfẹ́.

Túbọ̀ máa fi nǹkan wọ̀nyí kọ́ni, kí o sì máa gbani níyànjú. 3 Tí ẹnikẹ́ni bá fi ẹ̀kọ́ míì kọ́ni, tí kò sì fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣàǹfààní,*+ tó wá látọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kristi àti ẹ̀kọ́ tó bá ìfọkànsin Ọlọ́run mu,+ 4 ó ń gbéra ga, kò sì lóye ohunkóhun.+ Ìjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀ ló gbà á lọ́kàn.*+ Àwọn nǹkan yìí máa ń fa owú, wàhálà, bíbanijẹ́,* ìfura burúkú, 5 ṣíṣe awuyewuye lemọ́lemọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan láàárín àwọn èèyàn tí ìrònú wọn ti dìbàjẹ́,+ tí wọn ò mọ òtítọ́, tí wọ́n sì ń ronú pé èrè ni ìfọkànsin Ọlọ́run wà fún.+ 6 Lóòótọ́, èrè ńlá wà nínú ìfọkànsin Ọlọ́run+ téèyàn bá ní ìtẹ́lọ́rùn.* 7 Torí a ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.+ 8 Torí náà, tí a bá ti ní oúnjẹ* àti aṣọ,* àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ wa lọ́rùn.+

9 Àmọ́ àwọn tó pinnu pé àwọn fẹ́ di ọlọ́rọ̀ máa ń kó sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn+ àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́ ọkàn tí kò bọ́gbọ́n mu, tó sì lè pani lára, èyí tó ń mú kí àwọn èèyàn pa run kí wọ́n sì ṣègbé.+ 10 Torí ìfẹ́ owó ni ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú jàǹbá, àwọn kan tí wọ́n sì ní irú ìfẹ́ yìí ti ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.+

11 Àmọ́, ìwọ tí o jẹ́ èèyàn Ọlọ́run, sá fún àwọn nǹkan yìí. Ṣùgbọ́n máa wá òdodo, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà àti ìwà tútù.+ 12 Ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́; di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí, èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́, tí o sì wàásù rẹ̀ dáadáa ní gbangba lójú ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí.

13 Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, ẹni tó pa ohun gbogbo mọ́ láàyè àti Kristi Jésù, ẹlẹ́rìí tó wàásù dáadáa ní gbangba níwájú Pọ́ńtíù Pílátù,+ 14 pé kí o pa àṣẹ náà mọ́ láìní àbààwọ́n àti láìlẹ́gàn títí di ìgbà tí Olúwa wa Jésù Kristi máa fara hàn,+ 15 èyí tí ẹni tó jẹ́ aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo máa fi hàn nígbà tí àwọn àkókò rẹ̀ bá tó. Òun ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa,+ 16 ẹnì kan ṣoṣo tó ní àìkú,+ ẹni tó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí kò ṣeé sún mọ́,+ tí èèyàn kankan kò rí rí, tí wọn ò sì lè rí.+ Òun ni kí ọlá àti agbára ayérayé jẹ́ tirẹ̀. Àmín.

17 Sọ* fún àwọn ọlọ́rọ̀ inú ètò àwọn nǹkan yìí* pé kí wọ́n má ṣe gbéra ga,* kí wọ́n má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí kò dáni lójú,+ àmọ́ lé Ọlọ́run, ẹni tó ń pèsè gbogbo ohun tí à ń gbádùn fún wa lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.+ 18 Sọ fún wọn pé kí wọ́n máa ṣe rere, àní kí wọ́n máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere, kí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́,* kí wọ́n ṣe tán láti máa fúnni,+ 19 kí wọ́n máa to ìṣúra tí kò lè díbàjẹ́ jọ láti fi ṣe ìpìlẹ̀ tó dáa fún ọjọ́ iwájú,+ kí wọ́n lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.+

20 Tímótì, máa ṣọ́ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ,+ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́ àti àwọn ohun tí wọ́n ń fi ẹ̀tàn pè ní “ìmọ̀” èyí tó ń ta ko òtítọ́.+ 21 Àwọn kan sì ti kúrò nínú ìgbàgbọ́ torí wọ́n ń fi irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn.

Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú rẹ.

Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tó Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.”

Tàbí “pa àṣẹ.”

Grk., “bó ṣe bófin mu.”

Tàbí “tí kò ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.”

Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ìṣekúṣe.”

Tàbí “ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin sùn.” Ní Grk., “ọkùnrin tó ń sùn ti ọkùnrin.”

Tàbí “àwọn tó ń búra èké.”

Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”

Tàbí “àṣẹ.”

Tàbí “ipò àṣẹ.”

Tàbí “gbogbo onírúurú èèyàn.”

Ní Grk., “ọwọ́ ìdúróṣinṣin.”

Tàbí “tó buyì kúnni.”

Tàbí “làákàyè; òye.”

Tàbí “láìsọ̀rọ̀; fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́.”

Tàbí “máa fara balẹ̀; máa wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.”

Ní Grk., “tí wọ́n.”

Tàbí “làákàyè; òye.”

Tàbí “làákàyè; òye.”

Tàbí “aluni.”

Tàbí “tó ń tọ́jú.”

Tàbí “tọ́jú.”

Tàbí “máa sọ pé ó níwà rere.”

Tàbí “ìtìjú.”

Tàbí “fi ọ̀rọ̀ tanni jẹ.”

Ní Grk., “wáìnì.”

Tàbí “bóyá wọ́n tóótun.”

Ní Grk., “ẹ̀mí.”

Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí.”

Tàbí “ara kíkọ́.”

Tàbí “ìjẹ́mímọ́.”

Ní Grk., “ní gbangba.”

Tàbí “máa fúnni níṣìírí.”

Tàbí “Máa ṣàṣàrò.”

Ní Grk., “Máa bọlá fún àwọn opó.”

Tàbí “àwọn opó tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lóòótọ́”; ìyẹn, àwọn tí kò ní ẹni tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Tàbí “àṣẹ.”

Tàbí “ìlérí tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.”

Tàbí “àwọn opó tí wọ́n nílò ìrànwọ́ lóòótọ́”; ìyẹn, àwọn tí kò ní ẹni tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Tàbí “alàgbà.”

Ní Grk., “kí ẹ̀rù lè ba àwọn yòókù.”

Ìyẹn, má ṣe fi ìkánjú yan ọkùnrin èyíkéyìí sípò.

Tàbí “Má mu omi nìkan mọ́.”

Ní Grk., “tó wà lábẹ́ àjàgà ẹrú.”

Tàbí “tó ṣeni lóore; tó wúlò.”

Tàbí “Ó nífẹ̀ẹ́ òdì fún jíjiyàn àti fífa ọ̀rọ̀.”

Tàbí “ọ̀rọ̀ èébú.”

Ní Grk., “ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”

Tàbí “ohun ìgbẹ́mìíró.”

Tàbí kó jẹ́, “ibùgbé.” Ní Grk., “ìbora.”

Tàbí “Pàṣẹ.”

Tàbí “àsìkò yìí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Tàbí “ro ara wọn ju bó ṣe yẹ lọ.”

Tàbí “kí wọ́n má ṣe háwọ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́