ÌWÉ KÌÍNÍ JÒHÁNÙ
1 Ohun tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀, tí a gbọ́, tí a fi ojú wa rí, tí a kíyè sí, tí a sì fọwọ́ bà, nípa ọ̀rọ̀ ìyè,+ 2 (òótọ́ ni, a fi ìyè náà hàn kedere, a ti rí ìyè àìnípẹ̀kun+ tó wà pẹ̀lú Baba, tí a fi hàn kedere fún wa, à ń jẹ́rìí fún yín nípa rẹ̀,+ a sì ń ròyìn rẹ̀ fún yín), 3 a tún ń sọ àwọn ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti rí fún yín,+ kí ẹ̀yin náà lè ní àjọṣe* pẹ̀lú wa. Àwa àti Baba pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi la jọ ní àjọṣe yìí.+ 4 A sì ń kọ àwọn nǹkan yìí kí ayọ̀ wa lè kún rẹ́rẹ́.
5 Ohun tí a gbọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀, tí a sì ń sọ fún yín ni pé: Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí òkùnkùn kankan nínú rẹ̀* rárá. 6 Tí a bá sọ pé, “A ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀,” síbẹ̀ tí à ń rìn nínú òkùnkùn, irọ́ ni à ń pa, a ò sì sọ òótọ́.+ 7 Àmọ́, tí a bá ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bí òun fúnra rẹ̀ ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀, a ní àjọṣe pẹ̀lú ara wa, ẹ̀jẹ̀ Jésù Ọmọ rẹ̀ sì ń wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀.+
8 Tí a bá sọ pé, “A ò ní ẹ̀ṣẹ̀,” à ń tan ara wa,+ òótọ́ ò sì sí nínú wa. 9 Tí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ó máa dárí jì wá, ó sì máa wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo torí olóòótọ́ àti olódodo ni.+ 10 Tí a bá sọ pé, “A ò dẹ́ṣẹ̀,” à ń sọ ọ́ di òpùrọ́, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì sí nínú wa.
2 Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mò ń kọ àwọn nǹkan yìí sí yín kí ẹ má bàa dẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, tí ẹnikẹ́ni bá dẹ́ṣẹ̀, a ní olùrànlọ́wọ́* lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi,+ ẹni tó jẹ́ olódodo.+ 2 Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ síbẹ̀ kì í ṣe fún ẹ̀ṣẹ̀ tiwa nìkan, àmọ́ fún gbogbo ayé pẹ̀lú.+ 3 Tí a bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, èyí á jẹ́ ká mọ̀ pé a ti wá mọ̀ ọ́n. 4 Òpùrọ́ ni ẹni tó bá sọ pé, “Mo ti wá mọ̀ ọ́n,” síbẹ̀ tí kò pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, òótọ́ ò sí nínú ẹni náà. 5 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, ó dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run ti di pípé nínú ẹni náà.+ Èyí la fi mọ̀ pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+ 6 Ẹni tó bá sọ pé òun wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa rìn bí ẹni yẹn ṣe rìn.+
7 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, àṣẹ tí mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín kì í ṣe tuntun, àmọ́ ó jẹ́ àṣẹ àtijọ́ tí ẹ ti ní láti ìbẹ̀rẹ̀.+ Àṣẹ àtijọ́ yìí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ gbọ́. 8 Síbẹ̀, àṣẹ tuntun ni mò ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín, ó jẹ́ òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ àti nínú tiyín, torí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ sì ti tàn báyìí.+
9 Ẹni tó bá sọ pé òun wà nínú ìmọ́lẹ̀, síbẹ̀ tó kórìíra+ arákùnrin rẹ̀, inú òkùnkùn ló ṣì wà.+ 10 Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ wà nínú ìmọ́lẹ̀,+ kò sì sí ohun tó lè fa ìkọ̀sẹ̀ nínú rẹ̀. 11 Àmọ́ ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ wà nínú òkùnkùn, ó ń rìn nínú òkùnkùn,+ kò sì mọ ibi tó ń lọ,+ torí òkùnkùn ò jẹ́ kó ríran.
12 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, mò ń kọ̀wé sí yín torí a ti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.+ 13 Mò ń kọ̀wé sí ẹ̀yin bàbá, torí ẹ ti wá mọ ẹni tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀. Mò ń kọ̀wé sí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, torí ẹ ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+ Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin ọmọdé, torí ẹ ti wá mọ Baba.+ 14 Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin bàbá, torí ẹ ti wá mọ ẹni tó wà láti ìbẹ̀rẹ̀. Mo kọ̀wé sí ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, torí ẹ jẹ́ alágbára,+ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà nínú yín,+ ẹ sì ti ṣẹ́gun ẹni burúkú náà.+
15 Ẹ má ṣe nífẹ̀ẹ́ ayé tàbí àwọn nǹkan tó wà nínú ayé.+ Tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, kò ní ìfẹ́ Baba;+ 16 torí gbogbo ohun tó wà nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara,+ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú+ àti fífi ohun ìní ẹni ṣe àṣehàn*—kò wá látọ̀dọ̀ Baba, àmọ́ ó wá látọ̀dọ̀ ayé. 17 Bákan náà, ayé ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ṣùgbọ́n ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló máa wà títí láé.+
18 Ẹ̀yin ọmọdé, wákàtí ìkẹyìn nìyí, bí ẹ sì ṣe gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀,+ kódà ọ̀pọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ti fara hàn báyìí,+ ìyẹn sì jẹ́ ká mọ̀ pé wákàtí ìkẹyìn nìyí lóòótọ́. 19 Wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa, àmọ́ wọn kì í ṣe ara wa;*+ torí ká ní wọ́n jẹ́ ara wa ni, wọn ò ní fi wá sílẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kúrò lọ́dọ̀ wa kó lè hàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló jẹ́ ara wa.+ 20 Ẹni mímọ́ ti yàn yín,+ gbogbo yín sì ní ìmọ̀. 21 Kì í ṣe torí pé ẹ ò mọ òótọ́+ ni mo ṣe kọ̀wé sí yín, àmọ́ torí pé ẹ mọ̀ ọ́n àti pé kò sí irọ́ kankan nínú òótọ́.+
22 Ta ni òpùrọ́ tí kì í bá ṣe ẹni tó sọ pé Jésù kọ́ ni Kristi?+ Ẹni yìí ni aṣòdì sí Kristi,+ ẹni tó sẹ́ Baba àti Ọmọ. 23 Ẹnikẹ́ni tó bá sẹ́ Ọmọ kò ní Baba.+ Ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun mọ Ọmọ+ ní Baba pẹ̀lú.+ 24 Ní tiyín, àwọn nǹkan tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ kò gbọ́dọ̀ kúrò nínú yín.+ Tí àwọn nǹkan tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ kò bá kúrò nínú yín, ẹ̀yin àti Ọmọ máa wà ní ìṣọ̀kan, ẹ sì máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba. 25 Bákan náà, ohun tí òun fúnra rẹ̀ ṣèlérí fún wa ni ìyè àìnípẹ̀kun.+
26 Torí àwọn tó fẹ́ ṣì yín lọ́nà ni mo ṣe kọ àwọn nǹkan yìí sí yín. 27 Ní tiyín, yíyàn tó yàn yín+ kò kúrò nínú yín, ẹ ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni máa kọ́ yín; àmọ́, yíyàn tó yàn yín ń kọ́ yín ní ohun gbogbo,+ òótọ́ ni, kì í ṣe irọ́. Kí ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ bó ṣe kọ́ yín gẹ́lẹ́.+ 28 Torí náà, ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ká lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà + nígbà tí a bá fi í hàn kedere, kí a má bàa fi ìtìjú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tó bá wà níhìn-ín. 29 Tí ẹ bá mọ̀ pé olódodo ni, ẹ tún máa mọ̀ pé gbogbo ẹni tó bá ń fi òdodo ṣe ìwà hù ni a bí látọ̀dọ̀ rẹ̀.+
3 Ẹ wo irú ìfẹ́ tí Baba ní sí wa+ tí a fi ń pè wá ní ọmọ Ọlọ́run!+ Ohun tí a sì jẹ́ nìyẹn. Ìdí nìyẹn tí ayé ò fi mọ̀ wá,+ torí kò tíì mọ̀ ọ́n.+ 2 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, a ti wá di ọmọ Ọlọ́run,+ àmọ́ a ò tíì fi ohun tí a máa jẹ́ hàn kedere.+ A mọ̀ pé nígbà tí a bá fi í hàn kedere a máa dà bíi rẹ̀, torí a máa rí i bó ṣe rí gẹ́lẹ́. 3 Gbogbo ẹni tó bá sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀ ń wẹ ara rẹ̀ mọ́+ bí ẹni yẹn ṣe jẹ́ mímọ́.
4 Gbogbo ẹni tó bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà ń rú òfin, ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin. 5 Bákan náà, ẹ mọ̀ pé a fi í hàn kedere láti mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò,+ kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ nínú rẹ̀. 6 Gbogbo ẹni tó bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà;+ ẹnikẹ́ni tó bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà kò tíì rí i, kò sì tíì mọ̀ ọ́n. 7 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kí ẹnikẹ́ni má ṣì yín lọ́nà; gbogbo ẹni tó bá ń ṣe òdodo jẹ́ olódodo, bí ẹni yẹn ṣe jẹ́ olódodo. 8 Ẹni tó bá ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà wá látọ̀dọ̀ Èṣù, torí láti ìbẹ̀rẹ̀* ni Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀.+ Ìdí tí a ṣe fi Ọmọ Ọlọ́run hàn kedere nìyí, kó lè fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.*+
9 Gbogbo ẹni tí a bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà,+ torí irúgbìn* Rẹ̀ wà nínú ẹni náà, kò sì lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, torí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti bí i.+ 10 Ohun tí a máa fi dá àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù mọ̀ nìyí: Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe òdodo kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀.+ 11 Torí ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;+ 12 kì í ṣe bíi Kéènì, tó jẹ́ ti ẹni burúkú náà, tó sì pa àbúrò rẹ̀.+ Kí nìdí tó fi pa á? Torí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú,+ àmọ́ ti àbúrò rẹ̀ jẹ́ òdodo.+
13 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe jẹ́ kó yà yín lẹ́nu pé ayé kórìíra yín.+ 14 A mọ̀ pé a ti tinú ikú wá sí ìyè,+ torí pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ará.+ Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ ṣì wà nínú ikú.+ 15 Gbogbo ẹni tó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apààyàn,+ ẹ sì mọ̀ pé kò sí apààyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun ṣì wà nínú rẹ̀.+ 16 Ohun tó jẹ́ ká mọ ìfẹ́ ni pé ẹni yẹn fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ fún wa,+ torí náà ó di dandan kí àwa náà fi ẹ̀mí wa* lélẹ̀ fún àwọn ará wa.+ 17 Àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá ní ohun ìní ayé yìí, tó sì rí i pé arákùnrin rẹ̀ ṣaláìní síbẹ̀ tí kò ṣàánú rẹ̀, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe wà nínú rẹ̀?+ 18 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, kò yẹ kí ìfẹ́ wa jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí ti ahọ́n,+ àmọ́ ó yẹ kó jẹ́ ní ìṣe+ àti òtítọ́.+
19 Èyí ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé a wá látinú òtítọ́, a sì máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀* níwájú rẹ̀ 20 nínú ohunkóhun tí ọkàn wa ti lè dá wa lẹ́bi, torí Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.+ 21 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tí ọkàn wa kò bá dá wa lẹ́bi, a lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà níwájú Ọlọ́run;+ 22 a sì ń rí ohunkóhun tí a bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà,+ torí à ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, a sì ń ṣe àwọn ohun tó dáa lójú rẹ̀. 23 Lóòótọ́, àṣẹ tó pa nìyí pé: ká ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi,+ ká sì nífẹ̀ẹ́ ara wa+ bó ṣe pàṣẹ fún wa gẹ́lẹ́. 24 Bákan náà, ẹni tó bá ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, ó sì máa wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni náà.+ Ẹ̀mí tó fún wa sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa.+
4 Ẹ̀yin ará mi ọ̀wọ́n, ẹ má gba gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí*+ gbọ́, àmọ́ kí ẹ dán àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí* wò kí ẹ lè mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló ti wá,+ torí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ló ti jáde lọ sínú ayé.+
2 Báyìí lẹ ṣe máa mọ̀ bóyá ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ kan tó ní ìmísí ti wá: Gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tó bá fi hàn pé Jésù Kristi wá nínú ẹran ara jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ 3 Àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ onímìísí tí kò bá fi hàn pé Jésù wá, kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.+ Bákan náà, ọ̀rọ̀ yìí ni aṣòdì sí Kristi mí sí, ẹni tí ẹ gbọ́ pé ó ń bọ̀,+ ó sì ti wà ní ayé báyìí.+
4 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lẹ ti wá, ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn,+ torí ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú yín+ tóbi ju ẹni tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ayé.+ 5 Inú ayé ni wọ́n ti wá;+ ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń sọ ohun tó wá látinú ayé, ayé sì ń fetí sí wọn.+ 6 Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá. Ẹnikẹ́ni tó bá ti wá mọ Ọlọ́run ń fetí sí wa;+ ẹnikẹ́ni tí kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í fetí sí wa.+ Báyìí la ṣe ń fìyàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ní ìmísí àti ọ̀rọ̀ àṣìṣe tó ní ìmísí.+
7 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara wa,+ torí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá, gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ la ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì mọ Ọlọ́run.+ 8 Ẹnikẹ́ni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, torí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.+ 9 Bí a ṣe fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀rọ̀ wa nìyí, Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo+ wá sí ayé, ká lè ní ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.+ 10 Bí ìfẹ́ náà ṣe jẹ́ nìyí, kì í ṣe pé àwa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, àmọ́ òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹbọ ìpẹ̀tù*+ fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.+
11 Ẹ̀yin ẹni ọ̀wọ́n, tó bá jẹ́ pé bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa nìyí, àwa náà gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa.+ 12 Kò sí ẹni tó rí Ọlọ́run rí.+ Tí a bá túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ ara wa, Ọlọ́run ò ní fi wá sílẹ̀, ìfẹ́ rẹ̀ á sì di pípé nínú wa.+ 13 Èyí la fi mọ̀ pé a wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀, tí òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa, torí ó ti fún wa ní ẹ̀mí rẹ̀. 14 Bákan náà, àwa fúnra wa ti rí, a sì ń jẹ́rìí pé Baba ti rán Ọmọ rẹ̀ wá kó lè jẹ́ olùgbàlà ayé.+ 15 Ẹnikẹ́ni tó bá gbà pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù,+ Ọlọ́run wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni yẹn, òun náà sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run.+ 16 A ti wá mọ̀, a sì gbà gbọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa.+
Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,+ ẹni tó bá wà nínú ìfẹ́ ṣì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Ọlọ́run sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀.+ 17 Báyìí la ṣe sọ ìfẹ́ di pípé nínú wa, ká lè sọ̀rọ̀ ní fàlàlà*+ ní ọjọ́ ìdájọ́, torí pé bí ẹni yẹn ṣe jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà jẹ́ nínú ayé yìí. 18 Kò sí ìbẹ̀rù nínú ìfẹ́,+ àmọ́ ìfẹ́ tó pé máa ń lé ìbẹ̀rù jáde,* torí ìbẹ̀rù máa ń ká wa lọ́wọ́ kò. Lóòótọ́, ẹni tó bá ń bẹ̀rù kò tíì di pípé nínú ìfẹ́.+ 19 A nífẹ̀ẹ́ torí òun ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.+
20 Tí ẹnikẹ́ni bá sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run,” síbẹ̀ tó ń kórìíra arákùnrin rẹ̀, òpùrọ́ ni.+ Torí ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ tó rí,+ kò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí kò rí.+ 21 Àṣẹ tí a gbà látọ̀dọ̀ rẹ̀ nìyí, pé ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.+
5 Gbogbo ẹni tó bá gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi ni a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run,+ gbogbo ẹni tó bá sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tó jẹ́ ká bí ẹnì kan, máa nífẹ̀ẹ́ ẹni tí onítọ̀hún bí. 2 Ohun tí a fi mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run+ nìyí, tí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí a sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. 3 Torí ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí nìyí, pé ká pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́;+ síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kò nira,+ 4 nítorí gbogbo ẹni* tí a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń ṣẹ́gun ayé.+ Ohun tó sì ṣẹ́gun ayé ni ìgbàgbọ́ wa.+
5 Ta ló lè ṣẹ́gun ayé?+ Ṣebí ẹni tó ní ìgbàgbọ́ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run ni?+ 6 Jésù Kristi ni ẹni tó wá nípasẹ̀ omi àti ẹ̀jẹ̀, kò wá nípasẹ̀ omi nìkan,+ àmọ́ nípasẹ̀ omi àti nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀.+ Ẹ̀mí sì ń jẹ́rìí,+ torí pé ẹ̀mí ni òtítọ́. 7 Nítorí àwọn mẹ́ta ló ń jẹ́rìí: 8 ẹ̀mí,+ omi+ àti ẹ̀jẹ̀;+ àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà níṣọ̀kan.
9 Tí a bá gba ẹ̀rí àwọn èèyàn, ẹ̀rí ti Ọlọ́run tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ. Torí ẹ̀rí tí Ọlọ́run fún wa nìyí, ẹ̀rí tó fún wa nípa Ọmọ rẹ̀. 10 Ẹni tó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run ní ẹ̀rí náà nínú ara rẹ̀. Ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ti sọ ọ́ di òpùrọ́,+ torí kò ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀rí tí Ọlọ́run fún wa nípa Ọmọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rí náà sì nìyí, pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ìyè yìí sì wà nínú Ọmọ rẹ̀.+ 12 Ẹni tó ní Ọmọ ní ìyè yìí; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọ́run kò ní ìyè yìí.+
13 Mo kọ àwọn nǹkan yìí sí ẹ̀yin tí ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Ọmọ Ọlọ́run,+ kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè àìnípẹ̀kun.+ 14 Ohun tó dá wa lójú nípa rẹ̀ ni pé,*+ tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.+ 15 Tí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ ohunkóhun tí a bá béèrè, a mọ̀ pé a máa rí àwọn ohun tí a béèrè gbà, torí pé a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.+
16 Tí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tó ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò yẹ fún ikú, ó máa gbàdúrà, Ọlọ́run sì máa fún un ní ìyè,+ àní, fún àwọn tí kò dẹ́ṣẹ̀ tó yẹ fún ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó yẹ fún ikú.+ Irú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn ni mi ò sọ fún un pé kó gbàdúrà nípa rẹ̀. 17 Gbogbo àìṣòdodo jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,+ síbẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tí kò yẹ fún ikú.
18 A mọ̀ pé gbogbo ẹni tí a ti bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dàṣà, àmọ́ ẹni tí a bí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run* ń ṣọ́ ọ, ẹni burúkú náà ò sì lè rí i mú.*+ 19 A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run la ti wá, àmọ́ gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.+ 20 Ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ti wá,+ ó sì ti jẹ́ ká ní òye* ká lè mọ ẹni tòótọ́ náà. A sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni tòótọ́ náà,+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀. Èyí ni Ọlọ́run tòótọ́ náà àti ìyè àìnípẹ̀kun.+ 21 Ẹ̀yin ọmọ kéékèèké, ẹ máa yẹra fún àwọn òrìṣà.+
Tàbí “lè ṣàjọpín.”
Tàbí “ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.”
Tàbí “agbẹnusọ.”
Tàbí “ètùtù; ohun tí a fi ń tuni lójú.”
Tàbí “fífi ohun téèyàn ní fọ́nnu.”
Tàbí “wọn kì í ṣe tiwa.”
Tàbí “látìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀.”
Tàbí “kó lè run àwọn iṣẹ́ Èṣù.”
Ìyẹn, irúgbìn tó lè méso jáde tàbí kó bí sí i.
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn wa.”
Tàbí “máa yí èrò ọkàn wa pa dà; máa mú kó dá ọkàn wa lójú.”
Ní Grk., “gbogbo ẹ̀mí.”
Ní Grk., “àwọn ẹ̀mí náà.”
Tàbí “ètùtù; ohun tí a fi ń tuni lójú.”
Tàbí “ní ìgboyà.”
Tàbí “ju ìbẹ̀rù síta.”
Ní Grk., “gbogbo nǹkan.”
Tàbí “Ohun tó jẹ́ ká máa bá a sọ̀rọ̀ fàlàlà ni pé.”
Ìyẹn, Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.
Tàbí “dì í mú pinpin.”
Ní Grk., “agbára ìmòye; làákàyè.”