A7-GB
Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Pàtàkì Nínú Ìgbésí Ayé Jésù—Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Ṣe Kẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù (Apá Kejì)
| ÀKÓKÒ | IBI | ÌṢẸ̀LẸ̀ | MÁTÍÙ | MÁÀKÙ | LÚÙKÙ | JÒHÁNÙ | 
|---|---|---|---|---|---|---|
| Nísàn 14 | Jerúsálẹ́mù | Jésù fi hàn pé Júdásì ni ọ̀dàlẹ̀, ó sì ní kó máa lọ | ||||
| Ó dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀ (1Kọ 11:23-25) | ||||||
| Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Pétérù máa sẹ́ òun àti pé àwọn àpọ́sítélì máa fọ́n ká | ||||||
| Ó ṣèlérí olùrànlọ́wọ́; àpèjúwe àjàrà tòótọ́; ó pàṣẹ pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn; àdúrà tó gbà kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì | ||||||
| Gẹ́tísémánì | Ẹ̀dùn ọkàn bá a nínú ọgbà; Júdásì fi Jésù hàn, wọ́n sì mú Jésù | |||||
| Jerúsálẹ́mù | Ánásì bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀; ìgbẹ́jọ́ níwájú Káyáfà, Sàhẹ́ndìrìn; Pétérù sẹ́ Jésù | |||||
| Júdásì ọ̀dàlẹ̀ pokùn so (Iṣe 1:18, 19) | ||||||
| Níwájú Pílátù, lẹ́yìn náà Hẹ́rọ́dù, ó tún pa dà sọ́dọ̀ Pílátù | ||||||
| Pílátù wá bó ṣe máa dá a sílẹ̀ àmọ́ àwọn Júù ní kó dá Bárábà sílẹ̀; wọ́n dájọ́ ikú fún un pé kí wọ́n kàn án mọ́ òpó igi oró | ||||||
| (n. aago mẹ́ta ọ̀sán, Friday) | Gọ́gọ́tà | Ó kú lórí òpó igi oró | ||||
| Jerúsálẹ́mù | Wọ́n gbé òkú rẹ̀ kúrò lórí òpó igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sínú ibojì | |||||
| Nísàn 15 | Jerúsálẹ́mù | Àwọn àlùfáà àtàwọn Farisí gba àwọn ẹ̀ṣọ́ láti máa ṣọ́ ibojì náà, wọ́n sì sé e pa | ||||
| Nísàn 16 | Jerúsálẹ́mù àti agbègbè rẹ̀; Ẹ́máọ́sì | Jésù jíǹde; ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní ẹ̀ẹ̀marùn-ún | ||||
| Lẹ́yìn Nísàn 16 | Jerúsálẹ́mù; Gálílì | Ó tún fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn (1Kọ 15:5-7; Iṣe 1:3-8); ó fún wọn ní ìtọ́ni; ó ní kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn | ||||
| Ííyà 25 | Òkè Ólífì, nítòsí Bẹ́tánì | Jésù pa dà sí ọ̀run, ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tó jíǹde (Iṣe 1:9-12) |