ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 32
  • “Lati Ẹnu Awọn Ìkókó”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Lati Ẹnu Awọn Ìkókó”
  • Jí!—1996
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 32

“Lati Ẹnu Awọn Ìkókó”

Obìnrin kan láti Ballito, Natal, South Africa, fi ìmọrírì ọlọ́yàyà hàn fún ìwé náà, Iwe Itan Bibeli Mi, ó sì kọ̀wé pé:

“Mo ní ọmọ arákùnrin mi kan, tí ń jẹ́ Rudi Naidoo, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún kan àbọ̀ péré, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lè dárúkọ gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìwé náà nípa wíwulẹ̀ rí àwòrán wọn. Ó tilẹ̀ máa ń sọ ohun tí àwọn ènìyàn kan nínú Bibeli ń ṣe nínú àwọn àwòrán náà. Fún àpẹẹrẹ, ìtàn 11 fi Noa tí ó ń rúbọ hàn. Rudi sọ fún wa pé, ‘Noa—ń gbàdúrà sí Jehofa.’

“Nígbà tí a béèrè nípa ohun tí Joṣua ń ṣe nínú ìtàn 49, Rudi dúró bí Joṣua ṣe dúró nínú àwòrán náà, ó sì sọ pé, ‘Ìwọ oòrùn duro soju kan!’ Kò lè pe àwọn ọ̀rọ̀ náà dáradára, ṣùgbọ́n, ó sọ ọ́ bí ó ti lè sọ ọ́, lọ́nà tí ń pani lẹ́rìn-ín tí ó sì gbádùn mọ́ni.

“Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìtẹ̀jáde tó fakọ yọ yìí. Àwọn ọmọ kéékèèké lè ṣàlàyé ohun tí àwọn àgbà mélòó kan kò mọ̀. Ọ̀rọ̀ Jesu ni Matteu 21:16 jẹ́ òtítọ́ ní ti gidi: ‘Lati ẹnu awọn ìkókó ati ọmọ-ẹnu-ọmú ni iwọ ti mú ìyìn jáde.’”

Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè gba Iwe Itan Bibeli Mi, tàbí bí o bá fẹ́ kí ẹnì kan ké sí ọ ní ilé rẹ láti jíròrò ìníyelórí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli pẹ̀lú rẹ, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, fún ìsọfúnni síwájú sí i, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́