Ojú ìwé 2
Àgbàyanu Àgbáálá Ayé Ibo Ni Ó Ti Wá? 3-14
Kí ni ìdí tí a fi wà níhìn-ín? Ibo ni à ń lọ? Kí ni ète gbogbo rẹ̀? Àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá ha ṣàlàyé ìṣẹ̀dá bí? Awò awọ̀nàjíjìn Hubble gbé àwọn ìbéèrè dìde, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé sọ pé ó ku ohun kan. Kí ni ohun náà?
Iná Mọ́ Àwọn Ilé Iṣẹ́ Tábà 18
A ti ṣàwárí ẹgbẹ̀rún méjì ojú ewé ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ń ṣàkóbá, tí ó tọ́ka pé, àwọn ilé iṣẹ́ náà mọ ohun púpọ̀ sí i nípa àwọn ewu tí tábà ní ju ohun tí wọ́n sọ pé àwọ́n mọ̀ lọ.
Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’! 24
Àwọn ọ̀nì tí ń gbé inú omi oníyọ̀ ní Australia jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ọ̀nì 12 tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì léwu jù lọ lágbàáyé.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòrán iwájú ìwé àti ojú ewé 2: Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Anglo-Australian Observatory, fọ́tò láti ọwọ́ David Malin
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Australian International Public Relations