ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣírí Ayọ̀?
  • DNA àti Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú
  • Ìbàjẹ́ Ìdílé Tí Ó Tàn Kálẹ̀
  • Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba
  • Ó Ń Bọ̀ Lọ́nà: Orílẹ̀-Èdè Asia Àkọ́kọ́ Tí Kò Ní Ẹgàn
  • “Alábùkúnfún Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa”
  • Olùṣe Erin Lóge
  • Àwọn Ọ̀dọ́mọdé Òjìyà Ogun
  • Àlùsì Ẹyọwó Pẹ́nì
  • Ìrètí fún Àwọn Tí Àrùn Ọkàn Ń Bá Jà
  • Àwọn Bàbá—Ìdí Tí Wọ́n Fi Ń di Àwátì
    Jí!—2000
  • Òbí Tó Ń Dá Tọ́mọ Túbọ̀ Ń Pọ̀ Sí I
    Jí!—2002
  • Kí ni Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Eyín Erin—Báwo Ló Ṣe Níye Lórí Tó?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Àṣírí Ayọ̀?

Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí tí a ròyìn rẹ̀ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Daily Telegraph ti London, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ara àwọn ará Britain dá ṣáṣá jù, tí wọ́n sì túbọ̀ lọ́rọ̀ jù bí wọ́n ti ní in ní ọdún 25 sẹ́yìn lọ, ní gbogbogbòò, wọn kò láyọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ní fífohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àbájáde Ìròyìn Ìṣarasíhùwà Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà láti Orílé-Iṣẹ́ Ìṣèṣirò, onímọ̀ nípa ìṣarasíhùwà ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kan tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ America sọ pé ayọ̀ tòótọ́ ń wá láti inú níní “ìtumọ̀ kan nínú ìgbésí ayé” tí ó ní “ìlépa àwọn góńgó títóyeyẹ” nínú. Lẹ́yìn fífọ̀rọ̀ wá èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 400 ènìyàn lẹ́nu wò, àwọn olùṣèwádìí ará New Zealand méjì dé orí ìpinnu tí ó fara jọra—pé, ọ̀pọ̀ sọ pé ayọ̀ ń wá láti inú “fífún ètò àti ète ìwàláàyè wọn ní àkànṣe àfiyèsí.” Ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó àti àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ ìsìn tí ó fìdí múlẹ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn tí ó pọ̀. Lójú ìwòye ìlọsílẹ̀ nínú ìgbéyàwó àti ìgbàgbọ́ ìsìn ní ilẹ̀ Britain, ìwé agbéròyìnjáde náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, a óò máa bá a nìṣó láti túbọ̀ jẹ́ aláìláyọ̀.”

DNA àti Àwọn Àkájọ Ìwé Òkun Òkú

Lílóye àwọn Àkájọ Ìwé ìṣẹ̀m̀báyé ti Òkun Òkú bẹ̀rẹ̀ kété lẹ́yìn àwárí wọn nínú aginjù Judea ní 1947. Títí di àkókò yìí, a ti túmọ̀ àwọn àkájọ bíi 15. Ó ṣì tún ku nǹkan bíi 10,000 ẹ̀kíjá tí wọn kò tóbi ju èékánná àtàm̀pàkò láti ara ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn àkájọ mìíràn. Títa àwọn ẹ̀kíjá náà mọ́ra ti jẹ́ èyí tí ó gba wàhálà gan-an. Àwọn etí wọn ti jẹrà ju ohun tí ènìyàn lè ta mọ́ra bí àdìtú aláwòrán títò lọ, níwọ̀n bí ẹ̀kíjá kọ̀ọ̀kan sì ti ní kìkì ọ̀rọ̀ díẹ̀ nínú, a kò lè ta wọ́n mọ́ra nípasẹ̀ ìtumọ̀ wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune, nísinsìnyí, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ yóò ṣèrànwọ́. Lọ́nà wo? A kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà sórí awọ ẹranko, nítorí náà, ṣíṣàwárí ẹ̀yà àwọn DNA lè fi irú ẹ̀yà ẹranko, ara àti odidi ẹranko tí ó ni ẹ̀kíjá kọ̀ọ̀kan hàn. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ retí pé èyí yóò mú kí ó rọrùn láti ṣa àwọn ẹ̀kíjá tí wọ́n bára mu, kí a sì ta wọ́n mọ́ra.

Ìbàjẹ́ Ìdílé Tí Ó Tàn Kálẹ̀

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn àìpẹ́ yìí kan, ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Kárí ayé, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ àti ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n tòṣì, ìgbékalẹ̀ ìdílé ń la ìyípadà pátápátá kan kọjá. Yánpọnyánrin nínú ìdílé kò kan ipò tàbí ibùgbé.” Ìròyìn tí a gbé karí ìwádìí àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀ tí a tipasẹ̀ Ìgbìmọ̀ Tí Ń Bójú Tó Iye Ènìyàn ṣe, tọ́ka sí ìtẹ̀sí bíi iye ìkọ̀sílẹ̀ tí ń lọ sókè àti iye àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó tí ń pọ̀ sí i. Judith Bruce, ọ̀kan nínú àwọn olùṣètò ìwádìí náà, sọ pé: “Èrò náà pé, ìdílé jẹ́ ìgbékalẹ̀ kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì so mọ́ra gírígírí níbi tí bàbá ti jẹ́ olùpèsè owóòná, tí ìyá sì jẹ́ olùfúnni ní ìtọ́jú jẹ́ ìtàn àròsọ.” Títú ìgbéyàwó ká, bóyá nípasẹ̀ gbígbé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, pípa ẹnì kejì tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tàbí ìkọ̀sílẹ̀, ń yára lọ sókè kánkán, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ibi gbogbo ni àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó ti wọ́pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, èyí tí ó pọ̀ tó ìdá mẹ́ta gbogbo ìbímọ ní Ìhà Àríwá Europe jẹ́ nípasẹ̀ àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó. Àwọn olùṣèwádìí tọ́ka sí “ìwàlómìnira àwọn obìnrin,” tí ó ní ipò wọn ní ti ọrọ̀ ajé àti ojúṣe wọn tí ń pọ̀ sí i nínú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nínú, gẹ́gẹ́ bí ìdí pàtàkì kan fún ọ̀pọ̀ ìyípadà nínú ìdílé. Ibì kan ṣoṣo tí nǹkan ti yàtọ̀ lọ́nà tí ó gba àfiyèsí ni Japan, níbi tí àwọn ìyá tí kò ṣègbéyàwó àti àwọn agbo ilé olóbìí kan ṣoṣo kò ti fi bẹ́ẹ̀ wọ́ pọ̀ ní ìfiwéra. Bí ó ti wù kí ó rí, ìpín mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn bàbá tí wọ́n ti gba ìkọ̀sílẹ̀ níbẹ̀ kì í pèsè ìtìlẹ́yìn fún ọmọ.

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba

Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìsìn ní Ilẹ̀ Israeli ti jẹ́wọ́ pé àwọ́n ní ìwé orúkọ ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rún àwọn Júù tí a kà á léèwọ̀ fún láti gbé àwọn Júù míràn níyàwó nítorí pé, wọ́n jẹ́ irú ọmọ àwọn ìran tí a ti kà léèwọ̀. Àwọn tọkọtaya lọ́la mélòó kan sọ pé àwọn mọ èyí kíkí nígbà tí ìwéwèé ìgbéyàwó wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Àwọn rábì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ní ń ṣe ìpinnu tí ó kẹ́yìn. Ìwé agbéròyìnjáde Times Union ti Albany, New York, ròyìn pé, nígbà tí Shoshana Hadad àti Masoud Cohen gbìyànjú láti forúkọ ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́rin sílẹ̀ ní Ilé Ìjọba fún Àwọn Àlámọ̀rí Abẹ́lé, a sọ fún wọn pé ìgbéyàwó tí wọ́n ti ṣe láti ọdún 1982 kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ “nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kan tí ìdílé ìyàwó náà dá ní nǹkan bíi 2,500 ọdún sẹ́yìn.” Ó fi kún un pé: “A gbé ìdájọ́ náà karí àhesọ ọ̀rọ̀ ìtàn. Àwọn rábì gbà gbọ́ pé ìyá ńlá Hadad kan . . . ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹnì kan tí a kọ̀ sílẹ̀ lọ́nà tí kò bófin mu ní nǹkan bíi 580 ọdún ṣáájú Sànmánì Tiwa.” Láti ìgbà náà wá, a kò gba ẹnìkẹ́ni nínú ìdílé Hadad láyè láti fẹ́ ẹnìkẹ́ni tí ń jẹ́ Cohen. A gbà pé àwọn Cohen jẹ́ àwọn àtọmọdọ́mọ ojúlówó àwọn àlùfáà tẹ́ḿpìlì, wọ́n sì gbọ́dọ̀ gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìkálọ́wọ́kò pàtàkì kan. Shoshana béèrè pé: “Bí àwọn baba ńlá lọ́hùn-únlọ́hùn-ún bá ṣe ohunkóhun nígbà Tẹ́ḿpìlì Àkọ́kọ́, a ha ní láti máa jìyà rẹ̀ títí di òní olónìí bí?” Ilé Iṣẹ́ Tí Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìsìn sọ pé, àwọn tọkọtaya náà tún lè dojú kọ ẹ̀sùn ọ̀daràn nítorí mímú rábì tí ó fọwọ́ sígbeyàwó wọn ṣìnà.

Ó Ń Bọ̀ Lọ́nà: Orílẹ̀-Èdè Asia Àkọ́kọ́ Tí Kò Ní Ẹgàn

Ètò Ìdàgbàsókè ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNDP) kìlọ̀ pé, orílẹ̀-èdè Philippines dojú kọ igbó píparun pátápátá. “Iye àwọn olùgbé tí ń pọ̀ sí i àti gígé igi fún pípèsè pákó” ń pa púpọ̀ àwọn ilẹ̀ tí igi wà run sí i ni orílẹ̀-èdè Philippines. Ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, ìpín ọgọ́ta sí àádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà jẹ́ ẹgàn. Lónìí, kíkí ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún ni ó jẹ́ bẹ́ẹ̀. Update, lẹ́tà ìròyìn ti ètò UNDP, ròyìn pé: “Nígbà tí ó bá fi máa di ọdún 2000, orílẹ̀-èdè Philippines ṣee ṣe kí ó di orílẹ̀-èdè Asia àkọ́kọ́ tí yóò pàdánù gbogbo ilẹ̀ ẹgàn àti igbó rẹ̀.”

“Alábùkúnfún Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa”

Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè míràn, họ́wùhọ́wù ẹ̀jẹ̀ ti bẹ́ sílẹ̀ ní Itali. A sọ fúnni pé, a pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún jáálá ẹ̀jẹ̀ káàkiri àwọn ibùdó ìfàjẹ̀sínilára láìsí àyẹ̀wò fínnífínní tí ó tó, tàbí láìgbégbèésẹ̀ ààbò tí ó yẹ, tí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn sínú ewu kíkó àrùn, irú bí àrùn AIDS àti àrùn mẹ́dọ̀wú. Nígbà tí Luigi Pintor, olùyẹ̀wòṣàtúnṣe ìwé agbéròyìnjáde Il Manifesto ti Itali ń sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ń múni gbọ̀n rìrì náà, tí ó fi jíjèrè ṣáájú ìlera ara ẹni, ó bẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Alábùkúnfún ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n . . . kọ ìfàjẹ̀sínilára nítorí ìsìn. Bí wọ́n ti ń ka àwọn ìwé agbéròyìnjáde lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn nìkan ni kì yóò dààmú nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ . . . ní àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀jẹ̀ àti àwọn ilé ìwòsàn tí ń ta ẹ̀jẹ̀, èròjà plasma, àti àwọn ohun mìíràn tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n sì ń fà á sí wọn lára.”

Olùṣe Erin Lóge

Àwọn erin ni ìpínlẹ̀ Kerala, gúúsù India, sábà máa ń gbé ẹrù wíwúwo sórí ọwọ́jà wọn. Ṣùgbọ́n, a tún máa ń lo ọ̀pọ̀ nínú àwọn erin náà nínú ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́ rìn tẹ́ḿpìlì àti ní ibi àwọn àjọyọ̀ ìsìn. Ṣáájú àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ olùṣenilóge kan yóò ṣe ọwọ́jà wọn lóge, kì í ṣe ojú wọn. Ni Kerala, ẹnì kan ṣoṣo tí ń ṣe iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ yìí, P. K. Sasidharan, kọ́ iṣẹ́ náà láti ọ̀dọ̀ bàbá rẹ̀ àgbà. Báwo ni ó ṣe ń pinnu bi ohun tí òun yóò gé kù yóò ti tó? Ìpinnu náà—tí a gbé karí bí erin náà bá ti ga sí, bí ó bá ti tóbi tó àti bí ara rẹ̀ bá ṣe rí—jẹ́ àṣírí ìdílé tí a pamọ́ dáradára. Bí ẹran náà bá ṣe jẹ́jẹ́, ìtọ́jú náà máa ń gba nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta, ṣùgbọ́n, erin tí ó bá jẹ́ agánnigàn léwu, ó sì lè gba àkókò púpọ̀ sí i. Yàtọ̀ sí ṣíṣe wọ́n lóge, a ní láti gé ọwọ́jà àwọn erin tí ń ṣiṣẹ́ kù ní ọdún méjì-méjì kí gígún wọn baà lè rọrùn láti fi gbé ẹrù.

Àwọn Ọ̀dọ́mọdé Òjìyà Ogun

Ní ìgbà kan, àwọn òjìyà ogun sábà ń jẹ́ àwọn ológun. Èyí kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Láàárín ọdún mẹ́wàá tó kọjá, ogun ti sọ ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé di aláàbọ̀ ara, ó sì ti ṣekú pa wọ́n ju àwọn ológun lọ. Ìròyìn kan tí a pè ní The State of the World’s Children 1995 láti ọwọ́ Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tí Ń Rí Sí Ọ̀ràn Ọmọdé sọ pé, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé ti kú nínú àwọn ogun ní ẹ̀wádún tó kọjá. A ti sọ mílíọ̀nù 4 sí 5 àwọn ọmọdé mìíràn di aláàbọ̀ ara, a lé àwọn tí ó ju mílíọ̀nù 5 lọ sí àgọ́ ìsádi, a sì sọ iye tí ó ju mílíọ̀nù 12 dí aláìnílé. Ìròyìn náà sọ pé: “Ìwọ̀nyí jẹ́ ìṣirò tí ń tini lójú. Wọ́n jẹ́ orísun ìbànújẹ́ fún àwọn ìran ọjọ́ iwájú àti ìjàkadì wọn fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àti ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.”

Àlùsì Ẹyọwó Pẹ́nì

Agbẹnusọ kan fún Ilé Iṣẹ́ Ìrọwó Aláyélúwà ti Britain sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn ènìyàn kò tilẹ̀ ní dúró mú ẹyọwó pẹ́nì.” Ṣùgbọ́n kì í ṣe Britain nìkan. Ní United States, a ń sọ ọ̀pọ̀ ẹyọwó pẹ́nì nù, a sì ń kó àwọn mìíràn da nù débi pé àwọn báǹkì kò fi bẹ́ẹ̀ ní in lọ́wọ́ mọ́. Láìpẹ́ yìí, Key Bank ti New York pinnu láti fún ẹnìkẹ́ni tí ó bá mú 50 ẹyọwó pẹ́nì wá ní Sẹ́ǹtì 55. Nítorí èyí, a rí mílíọ̀nù márùn-ún ẹyọ owó gbà láàárín ọ̀sẹ̀ méjì. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé, ní Massachusetts, ibùdó ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́ ńlá kan n rí ẹyọ owó—tí púpọ̀ jù lọ rẹ̀ jẹ́ ẹyọwó pẹ́nì—tí ó tó 1,000 dọ́là kó jọ lójoojúmọ́, nípa jíjọ eérú.

Ìrètí fún Àwọn Tí Àrùn Ọkàn Ń Bá Jà

Dókítà Peter Liu, alákòóso ìwádìí nípa ọkàn ní Ilé Ìwòsàn Toronto, sọ pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ènìyàn ronú pé, níní àìṣiṣẹ́-déédéé ọkàn lẹ́yìn ìpalára púpọ̀ fún ọkàn kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n, fífa ìpalára náà sẹ́yìn ṣeé ṣe nípa ṣíṣe eré ìdárayá.” Lẹ́yìn ìwádìí kan tí ó kún fún ìrètí tí a fi èkúté ṣe, ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ròyìn pé, Kílíníìkì Ìṣiṣẹ́ Ọkàn ti ilé ìwòsàn náà mú kí àwọn olùgbàtọ́jú tí wọ́n ní àrùn ọkàn “máa rin ìrìn tí ń jìnnà sí i lójoojúmọ́. Àyẹ̀wò àkọ́kọ́ fi hàn pé, rírin, ó kéré tán, kìlómítà kan lójúmọ́ lè fa ‘ewu’ àìṣiṣẹ́-déédéé ọkàn sẹ́yìn nínú ènìyàn pẹ̀lú.” Dókítà Liu sọ pé, bí ó ti wù kí ó rí, ìṣísẹ̀ náà gbọ́dọ̀ gba okun níwọ̀nba, rírìn náà sí gbọ́dọ̀ jẹ́ lábẹ̀ àbójútó.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́