Ìmọrírì Tí Serosha Fi Hàn fún Jí! Wú Mi Lórí
Ọ̀dọ́ kan láti ìpínlẹ̀ Washington, U.S.A., kọ̀wé pé: “Nínú kíláàsì ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n béèrè pé kí a kọ̀wé sí ìwé ìròyìn kan tàbí ìwé agbéròyìnjáde kan. Nítorí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé ìròyìn, tí mo lè fèsì padà sí.
“Mo pinnu láti wo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú ìwé ìròyìn Jí! tí ó dé sínú àpótí lẹ́tà wa lánàá. Inú mi dùn gan-an pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ‘Ìpadàbẹ̀wò sí Russia,’ nínú ìtẹ̀jáde February 22, 1995, wú mi lórí gidigidi. Ní pàtàkì, ó jẹ́ ohun ìṣírí láti kà nípa ìtara tí Serosha, ọmọ ọdún méje, ní fún Ìjọba Ọlọrun. Ìfẹ́ àti ìmọrírì rẹ̀ fún ìwé ìròyìn Jí! mú kí n ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú Jí! tí n kò tí ì kà. Mo ń ronú láti túbọ̀ sapá sí i láti ka gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ dáradára tí ó wà nínú Jí! àti Ilé-Ìṣọ́nà.”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ bí ó ṣe lè rí ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! gbà tàbí bí o bá fẹ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú ní ojú ìwé 5.