Ọ̀rẹ́ Mi Ọ̀wọ́n
Àwọn wo ni ọ̀rẹ́ rẹ? Ṣé kìkì àwọn tí wọ́n jẹ́ ojúgbà rẹ nìkan ni? Ka àkọsílẹ̀ èwe kan nípa ọ̀kan nínú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó fi nǹkan bí ẹ̀wádún méje jù ú lọ.
ÌDÍLÉ wa kó lọ sí Aberdeen, Scotland, ní nǹkan bí ọdún mẹ́sàn-án sẹ́yìn, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà péré. Èyí jẹ́ àkókò tí ń bani lẹ́rù fún mi nítorí pé mo ní láti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tuntun, mo sì ní láti wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun. Ṣùgbọ́n ohun kan wà tí ó rọra mu ara tù mí pẹ̀sẹ̀ ní ipò tuntun tí mo wà. Obìnrin àgbàlagbà kan, tí àwọn òbí mi ti bá pàdé rí, ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wa. Wọ́n fi mí hàn án lọ́nà tí ó yẹ, kò sì pẹ́ tí mo fi mọ bí ó ti jẹ́ ẹni tí ó fani lọ́kàn mọ́ra tó. Ó máa ń ṣe gbogbo nǹkan rẹ̀ bíi ti ọ̀dọ́, ó sì máa ń múra rèterète.
A yá ilé tí à ń gbé ni, nítorí náà, a kó lọ sí ilé tiwa tí ó fi nǹkan bíi kìlómítà kan jìnnà sí ilé Àǹtí Louie. Mo máa ń pè é ní “àǹtí” nítorí ọ̀wọ̀ tí mo ní fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbàpe olùfẹ́ ẹni. Inú mi bà jẹ́ nígbà tí a ní láti kó lọ, nítorí pé èmi àti ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ kí i déédéé.
Bí ó ti wù kí ó rí, ilé ẹ̀kọ́ tí mò ń lọ kò jìnnà sí àyíká ibi tí ilé Àǹtí Louie wà. Nítorí náà, ní gbogbo ọjọ́ Friday, lẹ́yìn tí a bá ti jáde ní kíláàsì, ṣaájú kí n tó lọ sí ibi ìdánrawò àṣálẹ́ fún Ijó Ìbílẹ̀ Scotland ní ilé ẹ̀kọ́, èmi yóò lọ sọ́dọ̀ Àǹtí láti wá nǹkan panu. Èyí di ohun tí mò ń ṣe nígbà gbogbo. Èmi yóò mú ọ̀kan nínú àwọn ìwé ìtàn mi lọ́wọ́, yóò sì máa kà á fún mi nígbà tí mo bá ń jẹ ìpápánu tí mo sì ń mu ife mílíìkì tútù kan lọ́wọ́.
Mo rántí pé ńṣe ni ọjọ́ Friday máa ń dà bí èyí tí ó pẹ́ kí ó tóó dé nígbà tí mo bá ń fojú sọ́nà fẹ̀tòfẹ̀tò kí agogo mẹ́ta àbọ̀ lù, èyí tí ó máa ń jẹ́ àmì fún mi láti fò fẹ̀rẹ̀ lọ sílé Àǹtí Louie. Àkókò yìí ni mo mọ bí àwọn àgbàlagbà ṣe lè jẹ́ ẹni tí ń fani mọ́ra, tí ó sì gbádùn mọ́ni tó. Ní ti gidi, n kò wò ó bí arúgbó. Lọ́kàn mi, ọ̀dọ́ gan-an ló jẹ́. Ó lè wakọ̀, ilé àti ọgbà rẹ̀ sì máa ń já fíkánfíkán fún òórùn dídùn—àbí, kí ni ọmọdé kan tún ń wá?
Ọdún mẹ́ta kọjá, mo ṣì wà ní ìpele ọdún tí ó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yìí ni Àǹtí Louie pinnu pé ọgbà òun ti ń di ohun tí ó pọ̀ jù fún òun láti mójú tó, àti pé ilé gbéetán kan ni yóò jẹ́ yíyàn tí ó lọ́gbọ́n nínú fún òun. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, n kò lóye ohun tí ọjọ́ ogbó túmọ̀ sí. Inú ń bí mi pé ilé gbéetán rẹ̀ wà ní apá ibòmíràn nínú ìlú. Ọjọ́ Friday kò gbádùn mọ́ mi mọ́ bí ó ti máa ń rí tẹ́lẹ̀.
Ní ọdún 1990, kíkó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga mi ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀. Kí ni èmi yóò ṣe ní irú ilé ẹ̀kọ́ tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀? Ibo ni n óò gbé e gbà? Nísinsìnyí n óò máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí ó yàtọ̀ sí èyí tí àwọn ọ̀rẹ́ mi ń lọ, níwọ̀n bí ìdílé wa ti ń gbé ní agbègbè tí ó yàtọ̀. Àmọ́, lọ́tẹ̀ yìí, Àǹtí Louie wà níbẹ̀, nítorí pé ilé gbéetán tí ó kó lọ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí mo ń lọ! Mo bi í bóyá mo lè máa wá sí ilé gbéetán rẹ̀ ní àkókò ìjẹun láti wá máa jẹ ìpápánu mi. Bí ohun tí mo sọ di àṣà oníyebíye mìíràn tún ṣe yọjú nìyẹn.
Mo gbà gbọ́ pé ìgbà yìí ni àjọṣepọ̀ wa yí padà láti orí àjọṣepọ̀ ọmọdé òun àgbà sórí gbígbádùn wíwà pẹ̀lú ẹnì kíní-kejì lọ́gbọọgba. Èyí ṣe kedere ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà, àmọ́ ọ̀nà kan ní pàtàkì ni nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìwé gidi pa pọ̀—ìwé Jane Eyre, Villette, Pride and Prejudice, àti Women in White—dípò àwọn ìwé ìtàn mi. Ìfẹ́ tí mo ní fún ìwé kíkà ti kúrò ní ti ọmọ kékeré.
Àǹtí Louie kọ́ mi pé ìfẹ́ fún àwọn ènìyàn jẹ́ ohun kan tí à ń kọ́, ó sì jẹ́ iṣẹ́ ọnà. Bí kì í bá ṣe nítorí tirẹ̀, n kì bá tí mọ èyíinì títí tí n óò fi dàgbà sí i. Ó kọ́ mi bí a ti ń tẹ́tí sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú ayé tí ọwọ́ ti dí pinpin yìí ni kò sì tí ì kọ́ ìyẹn, ì báà jẹ́ àgbàlagbà tàbí ọmọdé. Níbi tí mo bá ká kò sí lórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀, yóò máa sọ ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ àti àwọn ìrírí tí ó ti ní fún mi. Ìmọ̀ fífani mọ́ra tí obìnrin yìí ní máa ń ṣí mi lórí.
Ohun púpọ̀ ni Àǹtí Louie ti fi rúbọ—ìgbéyàwó, ọmọ, iṣẹ́—kí ó baà lè máa tọ́jú àwọn òbí rẹ àti ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀ obìnrin ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ń ṣàìsàn líle koko. Èyí ló jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún àbúrò rẹ̀ ọkùnrin láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.
Ní ọdún méjì tí ó kọjá, ara Àǹtí Louie ti ń jagọ̀, mo sì lè rí ìjákulẹ̀, ìnira, àti ìrora tí ọjọ́ ogbó ń mú wá. Láìpẹ́ yìí, nígbà tí ó pé ẹni ọdún 84, ó di dandan kí ó pa ọkọ̀ wíwà tì, èyí ni ó sì wọ̀ ọ́ lákínyẹmí ara jù lọ. Ìgbésí ayé oníkòókòó-jàn-ánjàn-án ti mọ́ ọn lára, fífi tí a sì fìdíi rẹ̀ gúnlẹ̀ pa sílé nísinsìnyí ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Ó di pé kí ó máa bá ìmọ̀lára pé òun ń yọ àwọn ẹlòmíràn lẹ́nu jìjàkadì. Láìka iye ìgbà tí a sọ fún un pé a fẹ́ràn rẹ̀, àti pé a óò ṣe gbogbo ohun tí ó bá fẹ́ fún un sí, ó sì máa ń nímọ̀lára bí ẹni tí ń ṣe nǹkan tí kò dára.
Ohun tí ó tilẹ̀ mú kí ó burú jù nísinsìnyí ni pé ó ṣòro fún un láti wẹ̀ fùnra rẹ̀, kí ó sì múra fúnra rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti ṣe èyí fún àwọn ẹlòmíràn rí, ó jẹ́ àdánwò fún un nísinsìnyí láti rí i tí òun fúnra rẹ̀ ń wá irú ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀. Èyí ń kọ́ mi pé, àní bí àwọn ènìyàn kò bá tilẹ̀ lè ṣe ohunkóhun fún ara wọn, wọ́n ṣì lẹ́tọ̀ọ́ sí ọ̀wọ̀ wa.
Bí ó ti wù kí ó rí, ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìrírí yìí ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye bí ipò arúgbó ṣe máa ń ṣe ènìyàn. Gbogbo nǹkan tí Àǹtí Louie kò lè ṣe mọ́ pátá ló ń mú mi sunkún. Lékè gbogbo rẹ̀, nígbà tí mo bá rí i pé ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, tàbí tí ó ń joró, n óò fẹ́ láti ṣáà máa sunkún ni. Ohun tí mo kábàámọ̀ ní pàtàkì jù lọ ni pé ọmọdé kékeré mìíràn tí ó kéré ju èmi lọ lè máà gbádùn ọgbọ́n rẹ̀, kí ó sì mọrírì rẹ̀.
Mo máa ń ṣe kàyéfì nígbà míràn bóyá ohun tí mò ń ṣe fún un tó. Ṣé ó gbádùn mi, tí ó sì nífẹ̀ẹ́ mi gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi náà ṣe gbádùn rẹ̀ tí mo sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ṣùgbọ́n nígbà tí mo bá lọ fún oúnjẹ ọ̀sán, tí mo sì dì mọ́ ọn, gbogbo iyè méjì yóò fò lọ.
Ó gbé mi pọ́n láti ní irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó ti kọ́ mi ní ọ̀pọ̀ ànímọ́ rere—ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ti kọ́ mi ní ìfẹ́. N kò lè fi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ọgọ́rùn-ún ọ̀rẹ́ tí ó jẹ́ ojúgbà mi rọ́pò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ mi pẹ̀lú rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní pẹ́ fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, tí n kò sì ní lọ jẹ oúnjẹ ọ̀sán ní ilé gbéetán rẹ̀ mọ́, n kò ní dáwọ́ nínífẹ̀ẹ́ ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀, àti ríràn án lọ́wọ́ dúró. Ó ti kọ́ mi pé ìgbésí ayé lè ní ìtumọ̀, kí ó sì níláárí bí ènìyàn bá ń ronú àwọn ẹlòmíràn ṣaájú ara rẹ̀.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Àǹtí Louie