ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/22 ojú ìwé 25
  • Lammergeier Igún Bàgùjẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lammergeier Igún Bàgùjẹ̀
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
    Jí!—1998
Jí!—1996
g96 2/22 ojú ìwé 25

Lammergeier Igún Bàgùjẹ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN

IGÚN lammergeier jẹ́ ẹyẹ pípabambarì kan, tí ó gùn tó nǹkan bí 120 sẹ̀ǹtímítà láti ibi ṣóńṣó orí ẹnu dé ibi ìrù. Ènìyàn lè rí i tí ń fò fẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìyẹ́ rẹ̀ tí ó fẹ̀ tó mítà mẹ́ta, gba orí àwọn òkè ní ilẹ̀ Europe àti Áfíríkà pẹ̀lú gbẹ̀fẹ́, nígbà míràn sì nìyí, ó lè lọ sókè tó nǹkan bíi kìlómítà mẹ́jọ sí ìsàlẹ̀ ní òkè Himalayas. Ìṣẹ̀dá fífani mọ́ra yìí, tí ó ní igbáàyà àti ọrùn olómi-ọsàn àti orí tí ó ní dúdú àti funfun, máa ń ní irun gàn-ùngàn-ùn tí ó ṣàn wá sísàlẹ̀ láti ibi ṣóńṣó orí ẹnu rẹ̀. Èyí ló fà á tí wọ́n fi fún un ní orúkọ mìíràn tí ó ní, igún onírungbọ̀n. Níwọ̀n bí ó ti ń gbé ní àwọn agbègbè tí kò bọ́ sí gbangba, tí ó sì jẹ́ aṣálẹ̀, oúnjẹ wo ló wá fi ń gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró?

Àwọn ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé àwọn igún lammergeier máa ń fi àwọn ẹ̀dá alààyè—chamois, ọmọ àgùntàn, ọmọ ewúrẹ́, ehoro, àti àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́rin kéékèèké—ṣe oúnjẹ, àmọ́ àwọn ìwé mìíràn kò gbà bẹ́ẹ̀. Ìwé The World Atlas of Birds sọ pé: “Kò tí ì sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ kan tí ó sọ nípa bí ẹyẹ náà ṣe kọlu ẹranko alààyè rí,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ̀ pé ó máa ń jẹ àwọn ìdì kandikandi oníyẹ̀ẹ́ yẹtuyẹtu tí àwọn ẹyẹ mìíràn bá pọ̀ jáde, èyí tí kò ní ẹran kankan lára rẹ̀ mọ́. Kí ló wá ń jẹ nígbà náà?

Igún lammergeier máa ń gbé eegun àwọn òkú ẹran tí ẹlòmíràn pa, tàbí tí ó gba ọ̀nà míràn kú, lọ sókè lálá, tí yóò sì ju eegun náà sórí àpáta nísàlẹ̀. Ohun tí àwọn ènìyàn sábà máa ń rò ni pé ó ń ju eegun náà mọ́lẹ̀ lọ́nà yìí kìkì láti rí mùdùnmúdùn eegun náà. Nísinsìnyí, ìwé agbéròyìnjáde The Economist ròyìn pé, lẹ́yìn àyẹ̀wò fínnífínní tí àwọn olùṣèwádìí tí wọ́n wá láti Yunifásítì Glasgow ní Scotland ṣe nípa ààyè àti òkú ẹyẹ náà, ó ti ṣeé ṣe láti ṣe àlàyé tí ó yàtọ̀.

Àwọn igún lammergeier máa ń gbé ẹ̀là eegun tí ó tóbi tó sẹ̀ǹtímítà 25 ní gígùn àti sẹ̀ǹtímítà 4 ní fífẹ̀ mì. Síbẹ̀, sí ìyàlẹ́nu àwọn olùṣèwádìí náà, wọ́n rí i pé àwọn ẹyẹ náà kò ní ètò oúnjẹ dídà tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ kankan, irú bí iwe, láti lè kojú àwọn oúnjẹ wọn tí kì í dà. Kìkì ohun tí wọ́n ní tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni ọ̀nà ọ̀fun tí ó máa ń ràn kọjá ààlà, èyí tí ó jẹ́ kí àwọn ẹ̀là eegun náà lè kọjá. Bí ó ti wù kí ó rí, ikùn àwọn igún lammergeier tún fi nǹkan púpọ̀ sí i hàn.

Ó ya àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ lẹ́nu láti rí àwọn sẹ́ẹ̀lì púpọ̀ rẹpẹtẹ kan nínú ikùn wọn, tí ń sun omiró tí ó lágbára lọ́nà tí ó ṣàjèjì kan—tí ó mú ju omi bátìrì lọ, jáde—èyí tí ń mú kí àwọn èròjà calcium inú eegun yòrò, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí èròjà protein àti mùdùnmúdùn tọró jáde. Oúnjẹ náà ń pèsè okun tí ó ju èyí tí oúnjẹ náà yóò pèsè bí ó bá jẹ́ pé ẹran ni lọ. Ohun tí ó tilẹ̀ wá yani lẹ́nu jù lọ ni òtítọ́ náà pé àwọn èròjà tí ń mú kí oúnjẹ dà wà ní ibi tí irú omiró bẹ́ẹ̀ wà. Nítorí èyí, àràmàǹdà bí ìṣẹ̀dá lílágbára yìí ṣe ń gbé ẹ̀mí ara rẹ̀ ró pẹ̀lú irú oúnjẹ kékeré tí ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún rẹ̀ jẹ́ eegun ti di èyí tí a tú síta nísinsìnyí—ìyanu iṣẹ́ ìṣẹ̀dá mìíràn.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

© Nigel Dennis, Photo Researchers

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́