Wọ́n Gba Àfiyèsí Rẹ̀
Ní May 1995, obìnrin kan ní New York City kọ̀wé sí orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Brooklyn, New York. Ó ṣàlàyé pé:
“Mo ń rìn lọ ní Òpópónà East 124th, láàárín First àti Second Avenue. Ó ṣẹlẹ̀ pé mo wolẹ̀, afẹ́fẹ́ sì ń fẹ́ àwọn ìwé ìléwọ́ kan. Mo dúró mú mẹ́ta lára àwọn ìwé ìléwọ́ yín, Gbadun Igbesi-aye Idile, Ìtùnú fun Awọn ti o Soríkọ́, àti Ta Ni Ń Ṣakoso Ayé Niti Tootọ? Mo kà wọ́n, mo sì gbádùn wọn gan-an ni.
“Èmi yóò mọrírì rẹ̀ bí ẹ bá lè ṣoore fún mi nípa fífi àwọn ìsọfúnni díẹ̀ ránṣẹ́ sí mi nípa ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. Bákan náà, bí ó bá ṣeé ṣe, ń óò fẹ́ láti gba díẹ̀ lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yín. Ní tèmi, ìbùkún ni ó jẹ́ pé Oluwa rere náà gbé àwọn ìwé ìléwọ́ mẹ́ta náà wá sí iwájú mi kí n lè rí wọn. Oluwa máa ń ṣe iṣẹ́ lọ́nà ìyanu ní tòótọ́.”
Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ka àwọn ìwé ìléwọ́ tí ń ru àfiyèsí sókè yìí tàbí bí o bá fẹ́ láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.