Ojú ìwé 2
Àìríṣẹ́ṣe Ojútùú Kan Wà 3-11
Ó kéré tán, 820 mílíọ̀nù ènìyàn ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́ tàbí ni wọn kò ríṣẹ́ tí ó ṣe gúnmọ́ kan ṣe ní gbogbo àgbáyé. Bí o bá ronú nípa àwọn ìdílé wọn, o ha lè finú wòye làásìgbò àti ìyà tí èyí ní nínú? Kí ló ń fa àìríṣẹ́ṣe? Ojútùú kankan yóò ha wà láé bí?
Àwọn Oníṣẹ́ Mẹ́fà Láti Gbalasa Òfuurufú 12
Ní àwọn ẹ̀wádún ẹnu àìpẹ́ yìí nìkan ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣeé ṣe fún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti ṣàwárí àwọn oníṣẹ́ wọ̀nyí tí wọ́n ṣí ohun púpọ̀ nípa àgbáálá ayé wa payá. Kí ni wọ́n ń wí fún wa?
Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Àwọn Amerind Ìgbàanì Kan 24
Àwọn tí wọ́n jẹ́ olùgbé Àríwá America ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ti là á já papọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ ọnà wọn.