Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Mànàmáná!
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SWEDEN
ÌBÙYẸ̀RÌ màmàmáná kan lè ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mẹ́wàá-mẹ́wàá ìwọ̀n agbára iná mànàmáná pẹ̀lú ìgbì tí ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá agbára ìwọ̀n ìgbì mànàmáná. Ní ìfiwéra, àyípoyípo ìgbékiri iná mànàmáná inú ilé kan ni a sábà máa ń díwọ̀n sí ìwọ̀n agbára ìgbì mànàmáná 15.a Kí lo lè ṣe láti dín ewu dídi ẹni tí mànàmáná kọ lù kù? Ṣàkíyèsí àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí.
• Bí ó bá tilẹ̀ ṣeé ṣe pàápàá, wọnú ilé. Wíwọnú ọkọ̀ kan pàápàá lè pèsè ààbò dídára. Ti wíwà nínú ilé gogoro kan ńkọ́? Ilé gogoro tí a so àwọn ọ̀pá adènà mànàmáná mọ́ lè jẹ́ ibi ààbò. Fún àpẹẹrẹ, Empire State Building ní New York City máa ń la ìkọlù mànàmáná já ní nǹkan bí ìgbà 25 lọ́dọọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dara jù láti yẹra fún àwọn ilé tí kò ní ohun ìdènà iná mànàmáná tí a dè mọ́lẹ̀, tí wọ́n ní òrùlé onímẹ́táàlì àti àwọn ibi tí ó sún mọ́ òpó ohun onímẹ́táàlì àti àwọn ògiri onímẹ́táàlì.
• Kúrò ní àwọn ibi tí ó ṣe gbayawu, bí adágún omi, orí pápá, àti ibi ìgbábọ́ọ̀lù golf. Àwọn igi gogoro, tí ó dá wà lè léwu pẹ̀lú. Bí o bá wà ní àyíká ibi tí igi pọ̀ sí, sá sítòsí àwọn tí kò ga. Bí ìjì náà bá sún mọ́ ọ gan-an lọ́nà tí ó léwu, tí o kò sì lè sá lọ kúrò ní ibi tí ó ṣe gbayawu, lóṣòó, kí o sì gbá orúnkún rẹ mú. Má ṣe dọ̀bálẹ̀ gbalaja, níwọ̀n bí ó ti ṣe pàtàkì pé kí o má ṣe pèsè àyè púpọ̀ fún ìkọlù àrá bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.
• Kódà bí o bá wà nínú ilé pàápàá, o lè lo ìṣọ́ra. Ìmọ̀ràn díẹ̀ nìwọ̀nyí: Gbìyànjú láti yẹra fún ìfarakanra pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè gba iná mọ́ra, bí àdìrò onírin àti àwọn pọ́m̀pù onírin. Ó lè jẹ́ ohun tí ó bọ́gbọ́n mu láti má ṣe lo ilé ìwẹ̀ alásẹ́ tàbí agbada ìwẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lú gbìyànjú láti má ṣe lo tẹlifóònù. Yọ àwọn kọ̀m̀pútà, tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́ mìíràn kúrò lẹ́nu iná, níwọ̀n bí wọ́n ti lè bà jẹ́ bí mànàmáná náà bá kọ lu ilé.
• Bí mànàmáná náà bá kọ lu ẹnì kan, ó ṣe pàtàkì láti lo ọ̀nà ìmọ́kàn-sọjí (CPR) lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Victor Scuka, tí ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwádìí Ìwọ̀n Agbára Mànàmáná Gíga ní Yunifásítì Uppsala, Sweden, sọ pé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ púpọ̀, a ti lo ìlànà CPR láti mú èémí àwọn tí ọ̀ràn kàn padà, kódà nígbà tí ó bá jọ pé wọ́n ti kú pàápàá. Ó kìlọ̀ pé: “Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìtọ́jú náà ni a gbọ́dọ̀ lò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kí ó má baà kó àbùkù bá ọpọlọ.”
Bí ìjì mànàmáná bá kọ lù ọ́, ronú nípa lílo àwọn ìṣọ́ra tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu kàn yìí. Nígbà náà, ó ṣeé ṣe kí o máà bá ìjàm̀bá yíyani lẹ́nu yìí lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwọ̀n agbára ìgbì iná mànàmáná jẹ́ òṣùwọ̀n ìgbì mànàmáná, iye ìgbì mànàmáná tí a ń lò. Ìwọ̀n agbára iná mànàmáná tọ́ka sí ipá ìgbì mànàmáná náà. Wo Jí!, February 22, 1985, ojú ewé 26 sí 27 (Gẹ̀ẹ́sì).