“Wọ́n Jẹ́ Àgbàyanu Gan-an!”
“Mo sábà máa ń gbádùn kíka Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, àmọ́ wọ́n jẹ́ àgbàyanu gan-an lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí débi pé ó ṣòro láti rí ọ̀rọ̀ ajúwe tí mo lè fi ṣàpèjúwe wọn. Mo fẹ́ láti fi ìmọrírì mi hàn fún ìsọfúnni tí ẹ gbé jáde nínú ìtẹ̀jáde October 22 àti November 8, 1994, ti Jí! lábẹ́ àkọlé náà “Nígbà tí Ìsìn Bá Ń Gbè Síhà kan Nínú Ogun” àti “Sarajevo—Láti 1914 sí 1994.” Ọ̀ràn líle koko, tí ó sì lóró ni ọ̀ràn ogun abẹ́lé Bosnia àti Serbia àti Croatia jẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀kan tí ó mú mi lọ́kàn gan-an gẹ́gẹ́ bí ọmọ Croat kan. Ní pàtàkì, mo mọrírì ọ̀nà tí ẹ gbà sọ ìtàn ìforígbárí náà àti orísun rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1054. Èyí ṣí ipa tí ìsìn kó àti àwọn ìsapá rẹ̀ tí ó ti ṣamọ̀nà sí ìpínyà àti ìkórìíra púpọ̀ sí i láàárín àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí payá. Lọ́nà tí ó bani nínú jẹ́, aráyé lè rí àríṣá àwọn tí a pè ní ènìyàn rere wọ̀nyí. Ẹ ṣeun lẹ́ẹ̀kan sí i fún mímú kí ipò ọ̀ràn tí kò rọrùn láti lóye náà yéni kedere. [Ó buwọ́ lù ú] M. K.”
Jí! ti fìdí ìfùsì ṣíṣèwádìí kínníkínní àti ríròyìn tí ó nítumọ̀ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ìwé ìròyìn tí ń fúnni ní ìrètí fún ọjọ ọ̀la alálàáfíà tí a gbé karí ìlérí Ọlọrun láti mú ilẹ̀ ayé wá sábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀.
Bí o bá fẹ́ láti máa ka ìwé ìròyìn yìí déédéé, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní agbègbè rẹ, tàbí kí ó kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú nínú èyí tí a tò sí ojú ewé 5 ìwé ìròyìn yìí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Apá ọ̀tún: Culver Pictures