ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Gbọn Àwọn Ìgbéyàwó Jìgìjìgì
  • Ìpadàbọ̀ Àwọn Ẹranko Tí Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Pòórá
  • Ẹ̀wù Tí Ó Bá A Mu fún Ìgbà Òtútù
  • Àwọn Òǹwòran Tí Ń Dákú
  • Gbígbé Ọmọ Tini Lọ́fẹ̀ẹ́ Kẹ̀?
  • Òkìtì Yanrìn Nínú Ewu
  • Ìlera Àwọn Ará Japan Ń Jìyà Lọ́wọ́ Ipa Ìdarí Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn
  • Ibi Tí Àkókò Ń Lọ
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Púpọ̀ Sí I fún Títà
  • A Ti Sọ ọ́ Di Ti Ayé Pátápátá
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
Jí!—1996
g96 3/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

A Gbọn Àwọn Ìgbéyàwó Jìgìjìgì

Ọ̀pọ̀ aya ní àgbègbè Kobe, ní Japan, ti fẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí ìwà àwọn ọkọ wọn nígbà ìmìtìtì ilẹ̀ tí ó sọ ẹkùn náà dahoro ní ìbẹ̀rẹ̀ 1995 àti lẹ́yìn rẹ̀. Obìnrin kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News sọ pé: “Kì í ṣe ilé wa nìkan ni ó fọ́ yángá, ṣùgbọ́n ipò ìbátan wa pẹ̀lú fọ́, níwọ̀n bí mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé n kò lè gbẹ́kẹ̀ lé ọkọ mi.” Àwọn ọkọ ti wọ gàù, nítorí pé wọ́n dágunlá, fún ṣíṣàìpèsè ìtùnú ní àkókò tí ó yẹ, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, fún gbígbìyànjú láti dáàbò bo ara wọn nìkan. Ibùdó Ìdájọ́ Ọ̀ràn Àwọn Obìnrin ní Hyogo ròyìn pé, obìnrin kan “ni ó yà lẹ́nu pé ọkọ rẹ̀ jẹ gbogbo ìrẹsì tí wọ́n gbé fún wọn tán, láìkò fi ohunkóhun sílẹ̀ fún un.” Aya mìíràn sọ fún ibùdó náà pé: “N kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé kankan mọ́ nínú ọkọ mi, lẹ́yìn tí ó ké pe orúkọ àwọn ọmọ wa, ṣùgbọ́n tí kò pé orúkọ tèmi.” Bí ó ti wù kí ó rí, ibùdó náà fi kún un pé, iye àwọn ènìyàn kan náà sọ pé ìmìtìtì ilẹ̀ náà, fún ipò ìbátan àwọn lókun.

Ìpadàbọ̀ Àwọn Ẹranko Tí Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Pòórá

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera ti Milan ṣe sọ, “iṣẹ́ ìyanu ará Itali” ni àwọn kan ń pe ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ irú ẹranko fi padà dé nígbà tí ó jẹ́ pé wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá tán. Ní pàtàkì jù lọ nítorí àwọn agbègbè tí ó láàbò lórí Alps àti Apennines, àwọn ẹranko bí àgbọ̀nrín, ẹtu, àgbọ̀nrín aláwọ̀ ìyeyè, àti àgbọ̀nrín aláwọ̀ ilẹ̀ ń pọ̀ sí i ní Itali. Ìkokò orí Apennine, tí ó ń pọ̀ sí i ní iye, ti ń gbilẹ̀ láti Itali lọ sí orí òkè Alps ní Etíkun Faransé nísinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwé agbéròyìnjáde Corriere della Sera sọ pé, irú àwọn ẹranko bí otter àti monk seal ṣì wà nínú ewu, ṣùgbọ́n àwọn ògbógi ní ìdánilójú pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ààbò tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ “kì yóò kùnà láti mú àbájáde tí ó wà pẹ́ títí, tí ó jẹ́ ojúlówó, tí ó sì dára wá.”

Ẹ̀wù Tí Ó Bá A Mu fún Ìgbà Òtútù

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń gbìyànjú láti rí àwọn ẹranko ńlá tí ń gbé ilẹ̀ olótùútù láti inú ọkọ̀ òfuurufú kojú ìṣòro ńlá—kì í ṣe kìkì nítorí ìdí tí ó hàn gbangba pé àwọn ẹranko ńlá ilẹ̀ olótùútù náà funfun, tí wọ́n sì ń gbé ilẹ̀ oníyìnyín nìkan ni. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Popular Science ṣe sọ, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní ohun kan tí ó dà bí ojútùú ọlọ́gbọ́nféfé kan sí ìṣòro yẹn: wọ́n lo ìdànǹdán tí ń ṣàwárí ooru, pẹ̀lú ìrònú náà pé yóò lè fi ìrọ̀rùn ṣàwárí ooru inú ara tí ń jáde láti ara àwọn àgbààràgbá ẹ̀dá wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n ìdànǹdán náà kò rí ohun kan mú bọ̀! Ó dà bí ẹni pé awọ ẹranko ńlá ilẹ̀ olótùútù yìí gbéṣẹ́ láti má ṣe jẹ́ kí ooru ráyè kọjá, tí ó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba ooru díẹ̀ ní ń jáde láti ara ẹranko náà. Ìwé ìròyìn náà ṣàkíyèsí pẹ̀lú pé irun ara awọ náà jọ bíi pé ó lè gba ìtànṣán oòrùn sára, ní fífà á sínú ohun tí ó lè jẹ́ “sẹ́ẹ̀lì oòrùn” nínú ẹranko ńlá ilẹ̀ olótùútù náà, tí ó sì ń gbìyànjú bákan ṣáá láti yí irú ìtànṣán bẹ́ẹ̀ padà sí ooru.

Àwọn Òǹwòran Tí Ń Dákú

Èé ṣe tí ọ̀pọ̀ fi ń dákú ní ibi ijó rọ́ọ̀kì? Oníṣègùn kan, nípa ìgbékalẹ̀ iṣan ara, ní Ilé Ìwòsan ti Yunifásítì ní Berlin, Germany, ṣàyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn láìpẹ́. Ní ibi ijó rọ́ọ̀kì kan ní Berlin tí àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní pàtàkì pésẹ̀ sí, nǹkan bí 400 ni ó dákú lásìkò ijó náà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Discover ti sọ, oníṣègùn nípa ìgbékalẹ̀ iṣan ara náà ṣàwárí pé, ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ó dákú ni ó jẹ́ pé àwọn ìlà iwájú ni wọ́n dúró sí. Kí wọ́n ba lè rí àyè níbi àwọn ìjókòó iwájú tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn yìí, àwọn ọmọdébìnrin náà ti wà lórí ìlà gígùn fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ọ̀pọ̀ nínú wọn kò sì tí ì jẹun tàbí sùn ní alẹ́ tí ó ṣáájú. Àwọn ìdí mìíràn—híhan gooro àwọn fúnra wọn àti bí àwọn èrò tí ó wà lẹ́yìn ti ń tì wọ́n—mú kí àyà wọn fún pọ̀, tí ó sì mú kí ìfúnpá dín kù. Èyí kò jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tí ń lọ síbi ọpọlọ tó. Àwọn ènìyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í dákú. Bí oníṣègùn nípa ìgbékalẹ̀ iṣan ara náà tilẹ̀ dábàá pé kí àwọn òǹwòran rọ́ọ̀kì máa jẹun, kí wọ́n sì máa sùn ṣáájú, kí wọ́n máa jókòó, kí wọ́n máa ṣe wọ̀ọ̀, kí wọ́n sì jìnnà sí àwọn èrò nígbà ijó náà, ó jẹ́wọ́ pé ó ṣeé ṣe pé àwọn ọ̀dọ́langba òǹwòran tí ó lè ṣe èyí kò tó nǹkan.

Gbígbé Ọmọ Tini Lọ́fẹ̀ẹ́ Kẹ̀?

Ìwé ìròyìn Newsweek ròyìn pe, àwọn òbí tí ń kojú ìṣòro gbígbé ní agbègbè àdádó ìlú ńlá ti rí ọ̀nà tuntun láti mú kí àwọn ẹlòmíràn máa bá wọn ṣọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n baà lè rí àyè lọ ra nǹkan. Wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn kékeré sílẹ̀ ní ilé ìta-ohun-ìṣeré-ọmọdé tàbí ilé ìta-kọ̀m̀pútà gbogbonìṣe. Àwọn ọmọdé tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ sí àwọn ẹ̀rọ ọlọ́gbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ gíga máa ń fi àwọn ẹ̀rọ̀ tí a fi ń polówó ọjà ṣeré títí tí àwọn òbí wọn yóò fi dé. Bí ó ti wù kí ó rí, kò yani lẹ́nu pé inú àwọn òǹtàjà kò dùn sí ìwà náà. Wọ́n ń ṣàròyé pé, lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn ọmọdé kì í jẹ́ kí àwọn oníbàárà lo àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń polówó náà; ohun tí ó tún burú níbẹ̀ ni pé, wọ́n ń bà wọ́n jẹ́. Àwọn mìíràn ti ṣàkíyèsí pé àwọn òbí kan máa ń padà dé, tí wọn yóò sì máa ṣàròyé bí ẹnì kẹ́ni kò bá bá wọn bójú tó ọmọ wọn tàbí gbé wọn lọ sí ilé ìtura! Nípa báyìí, àwọn ilé ìtàjà kan ń gbéjà ko ìwà náà—bóyá nípa dídín àwọn kọ̀m̀pútà tí a fi ń polówó náà kù, tàbí kíké sí àwọn aláàbò ìlú, bí wọ́n bá ti fojú gán-ánní àwọn ọmọ tí kò sí ẹni tí ń bójú tó wọn.

Òkìtì Yanrìn Nínú Ewu

“Yanrìn ilẹ̀ Israeli ń tán lọ.” Ohun tí ìwé ìròyìn New Scientist sọ nìyẹn. Kí ló fa àìtó náà? Ó dára, yanrìn jẹ́ èlò pàtàkì nínú kọnkéré, èyí tí ilé iṣẹ́ tí ń kọ́lé-kọ́nà láìsọsẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà sì nílò rẹ̀ gidigidi. Nítorí náà, fún 30 ọdún tí ó kọjá, pẹ̀lú àbójútó ìjọba tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan, àwọn òǹkọ́lé ti ń fi ọkọ̀ kó yanrìn lọ láti ibi ìwọ́jọ yanrìn ńlá etíkun ilẹ Israeli, èyí tí ó ti fi ìgbà kan rí gùn láti Jaffa títí dé Gaza. Àwọn olè sì ń jí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù yanrìn láti lọ tà ní ọjà fàyàwọ́ lọ́dọọdún. Àwọn onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn ń ṣàníyàn pé, a ti pa agbègbè òkìtì yanrìn tí ń joro sí i, tí ó sì jẹ́ ẹlẹgẹ́, lórí èyí tí ó jẹ́ pé díẹ̀ nínú irú àwọn ewéko àti ẹranko ni ó lè gbé níbẹ̀, run. Àwọn òǹkọ́lé sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì nípa ibi tí wọn yóò ti máa rí yanrìn nígbà tí yanrìn ilẹ̀ Israeli bá tán.

Ìlera Àwọn Ará Japan Ń Jìyà Lọ́wọ́ Ipa Ìdarí Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn

Ní gbogbo ayé, àwọn ara Japan ni ẹ̀mí wọn ń gùn jù lọ, ṣùgbọ́n ipa ìdarí ọ̀nà ìgbésí ayé ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé lè mú kí ipò yẹn máa jó rẹ̀yìn. Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn láìpẹ́ pé, nínú àwọn ènìyàn 2.1 mílíọ̀nù tí a ṣe àyẹ̀wò ìlera ara fún ní 1994, kìkì ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún ni ara wọ́n dá ṣáṣá. Ní ọdún mẹ́wàá ṣáájú, iye yẹn jẹ́ ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ẹni tí ó kọ ìròyìn kan tí Ẹgbẹ́ Ilé Ìwòsàn Japan fi sóde ti sọ, ohun tí ń ṣokùnfà rẹ̀ ni àpọ̀jù ọ̀rá àti cholesterol nínú oúnjẹ ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ní àfikún sí ìlọsókè nínú sìgá, àti ọtí mímu. A rí ìlọsílẹ̀ ìlera tí ó ga jù lọ ní àwọn ẹkùn tí ilé iṣẹ́ ti pọ̀ gan-an, irú bí agbègbè Osaka-Kobe. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, àríwá, ní ìgbèríko ilẹ̀ àárín omi Hokkaido ni ẹkùn tí ó ní ìlera jù lọ.

Ibi Tí Àkókò Ń Lọ

Níbo ni àkókò lọ? Ọ̀pọ̀ ń béèrè ìbéèrè yẹn tìtaratìtara, ṣùgbọ́n àyẹ̀wò tí a ṣe láìpẹ́ gbìyànjú láti fi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ dáhùn rẹ̀. Àjọ kan tí ń ṣèwádìí ní Illinois, U.S.A., ṣe àyẹ̀wò ọlọ́dún mẹ́ta lórí ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ àwọn 3,000 ènìyàn tí a sọ fún pé kí wọ́n máa ṣe àkọsílẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lo àkókò wọn látìgbàdégbà. Ọjọ́ orí àwọn ènìyàn náà jẹ́ 18 sí 90, wọ́n sì ní ìpìlẹ̀ ìgbésí ayé tí ó jẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tí ó gba àkókò jù lọ ni oorun. Iṣẹ́ ni ó tẹ̀ lé e, ó sì gba ìpíndọ́gba 184 ìṣẹ́jú lóòjọ́. Lẹ́yìn náà ni wíwo tẹlifíṣọ̀n, tí ó gba 154 ìṣẹ́jú. Iṣẹ́ ilé gba 66 ìṣẹ́jú, ìrìn àjò àti ìjádelọ gba 51 ìṣẹ́jú, ìmúra gba 49 ìṣẹ́jú, tí ìtọ́jú ọmọ àti ohun ọ̀sìn ìṣiré sì gba 25 ìṣẹ́jú. Ní apá ìsàlẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni ìjọsìn wà, ó gba ìpíndọ́gba 15 ìṣẹ́jú lóòjọ́.

Ṣọ́ọ̀ṣì Púpọ̀ Sí I fún Títà

Àwọn olùdúnàádúrà ilẹ̀ àti ilé sọ pé, àwọn olókòwò ti ń jìjàdù láti ra àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí a kì í sábà lò ní Brisbane ní Queensland, olú ìlú ìhà àríwá Australia. Ìdí méjì ni ó fà á: iye àwọn tí ń wá sí ṣọ́ọ̀ṣì ti ń dín kù, àti bí àwọn olókòwò ti ń wá “ohun tí ó jojú ní gbèsè” kiri láti rà. Ìwé agbéròyìnjáde The Courier-Mail ròyìn pé, ó ju ṣọ́ọ̀ṣì méjìlá lọ tí a ti polówó fún títà, a sì ti sọ díẹ̀ nínú wọn di ilé gbígbé àti ọ́fíìsì ní Brisbane. Ìwé agbéròyìnjáde náà fa ọ̀rọ̀ alákòóso káràkátà kan yọ pé ó sọ pé: “Iye púpọ̀ sí i” lára àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ni a ti “ń lò gẹ́gẹ́ bí ilé oúnjẹ, ilé ìpàtẹ iṣẹ́ ọnà, ilé ìtajà ìṣẹ̀m̀báyé, ọ́fíìsì, tàbí ilé gbígbé.” Olùdúnàádúrà ilẹ̀ àti ilé kan sọ pé: “Ó dà bíi pé kí n túbọ̀ ní púpọ̀ wọn sí i láti tà.”

A Ti Sọ ọ́ Di Ti Ayé Pátápátá

Ìpínlẹ̀ Bavaria ní Germany jẹ́ Roman Kátólíìkì paraku. Ní tòótọ́, òfin ilé ẹ̀kọ́ àwọn ará Bavaria sọ ọ́ di dandan pé kí á fi àgbélébùú kọ̀dọ̀rọ̀ sínú kíláàsì kọ̀ọ̀kan ní gbogbo ilé ẹ̀kọ́ tí ó jẹ́ ti ìpínlẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung, ti Germany ròyìn pé, bí ó ti wù kí ó rí, Kóòtù Òfin Àpapọ̀ ti polongo nísinsìnyí pé òfin yìí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, nítorí pé kò sí ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Orílẹ̀-èdè Germany, tí ó fàyè gba òmìnira ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Westfälische Allgemeine Zeitung ti sọ, Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Meisner ti Cologne kédàárò pé: “Ọjọ́ búburú nínú ìtàn àwọn ènìyàn wa.” Ẹnu ya àwọn kan nítorí àríyànjiyàn náà ju nítorí ìpinnu náà fúnra rẹ̀ lọ. Ìwé agbéròyìnjáde Die Zeit ti Hamburg sọ pé, bákan ṣáá, àwùjọ Germany ni “a ti sọ di ti ayé pátápátá” ó sì “júbà ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, ríra ọ̀pọ̀ ọjà bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, àti ìṣípayá ara ẹni.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́