“Ilé Gogoro Tí Ń Kọrin” ní Australia
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ AUSTRALIA
ỌNÀ, ìmọ̀ ẹ̀rọ, àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti sábà ń para pọ̀ nínú ọ̀ràn orin láti gbé ohun èèlò orin tí ó ní ànímọ́ títayọ lọ́lá jáde. Ṣùgbọ́n, nígbà tí violin ti Antonius Stradivarius àti àwọn fèrè ti Theobald Böhm lè jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká, ní gbogbogbòò, ìwọ̀nba díẹ̀ ni a mọ̀ nípa carillon ọlọ́lá ńlá.
Ṣùgbọ́n, kí ní ń jẹ́ carillon, báwo ni a sì ṣe ń lù ú? Ìbẹ̀wò kan sí ọ̀kan lára àwọn carillon pàtàkì jù lọ lágbàáyé yóò là wá lóye, bóyá ó sì lè mú ìmọrírì wa jinlẹ̀ sí i fún orin rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́.
Ohun Èèlò Kíkàmàmà
Carillon wà lára àwọn ohun èèlò orin tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé, ó sì ti wà láti ìgbà ìjímìjí. A sábà máa ń gbé e sí ilé gogoro tí a kọ́ fún agogo, ìdí èyí ní a fi ń tọ́ka sí i lọ́nà tí ó bá a mu gẹ́gẹ́ bí “ilé gogoro tí ń kọrin.” Ilé gogoro fún carillon àti agogo tí ń bẹ ní Canberra, olú ìlú Australia, jẹ́ ẹ̀bùn àjọ̀dún tí ìjọba ilẹ̀ Great Britain fi tọrẹ ní ọdún 1963 láti fi ṣe ayẹyẹ àyájọ́ ìdásílẹ̀ àti ìsọlórúkọ ìlú náà ní 50 ọdún ṣáájú. Wọ́n gbé carillon náà sí Erékùṣù Aspen ní àárín gbùngbùn Adágún Burley Griffin àrímálèlọ.
Ilé gogoro fún aago yìí, tí ó ga ní 50 mítà ní ọ̀pá àjà mẹ́ta, tí ó ní ìrísí onígun mẹ́ta, tí ọ̀kọ̀ọ̀kán wà ní ẹ̀gbẹ́ ìrísí onígun mẹ́ta tí ó gùn lọ́gbọọgba kan láàárín. Lókè fíofío lọ́hùn-ún, tí a sì gbé rọ̀ sára ọ̀pá àjà mẹ́ta náà ni àgbékà tí a gbé carillon náà fúnra rẹ̀ sí wà.
Ẹ̀rọ agbéniròkè inú ilé gogoro náà gbé wa lọ sí àjà kíní, níbi tí a ti rí clavier, tàbí àpótíi bọ́tìnnì ńláńlá méjì, tí wọ́n rí bákan náà pẹ̀lú àwọn ti dùrù. Èkíní wulẹ̀ wà fún carillonneur, bí a ti ń pe ẹni tí ń tẹ̀ ẹ́, láti máa fi dánra wò. Àwọn òòlù àpótíi bọ́tìnnì yìí wulẹ̀ ń lu àwọn ọ̀pá amóhùnjáde lásán ni.
Ojúlówó àpótí bọ́tìnnì carillon fẹ́rẹ̀ẹ́ fẹ̀yìn ti àpótíi bọ́tìnnì ìdánrawò yìí. Ṣùgbọ́n kì í ṣe àpótíi bọ́tìnnì lásánlàsàn kan, nítorí ó ní bọ́tìnnì ńláńlá, fífẹ̀ roboto, nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà méjì ní ìwọ̀n ìdábùú. Àwọn ti ìlà òkè dà bí àwọn bọ́tìnnì dúdú tí a mọ̀ dáradára nínú piano tàbí dùrù. Wọ́n yọ síta ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 9, nígbà tí àwọn tìsàlẹ̀ (tí ó dúró fún bọ́tìnnì funfun ti piano) yọ síta ní nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 17. Bí ó ti wù kí ó rí, láìdà bíi ẹni tí ń tẹ piano tàbí atẹdùrù, carillonneur kì í lo ìka ọwọ́ rẹ̀, àmọ́ ìkúùkù ló ń lò. Ìdí nìyẹn tí àwọn bọ́tìnnì náà fi yàkàtà síra gan-an—kí ẹni tí ń tẹ̀ ẹ́ lè yẹra fún títẹ àwọn bọ́tìnnì míràn bí ó bá ń tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́.
Èèlò Amúṣẹ́yá Títóbi Lọ́lá Kan ní Tòótọ́
Láti orí clavier gan-an ni a ti mú àwọn wáyà lọ sí àtẹ̀gùn òkè, tí a sì so ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn bọ́tìnnì ohùn mẹ́jọ lọ́nà mẹ́rin àbọ̀ náà kọ́ wáyà onírin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú adíwọ̀n ìfàro tí ń pàfiyèsí lára rẹ̀. Láti mọ ibi tí gbogbo wáyà wọ̀nyí lọ, a gun ẹ̀rọ agbéniròkè lọ sí àjà tí ó tẹ̀ lé e. Níhìn-ín, a so àwọn aago ńláńlá méjì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n wọn nǹkan bíi tọ́ọ̀nù mẹ́fà rọ̀. Bí a ti ń wo àárín àwọn aago wọ̀nyí, a rí àwọn aago 51 mìíràn tí a so rọ̀ lókèe wọn, tí wọ́n tò lọ sókè gẹ̀ẹ̀rẹ̀gẹ̀ títí dórí èyí tí ó kéré jù lọ, tí ó wọn kìkì kìlógíráàmù méje.
A fọgbọ́n to àwọn aago náà lọ́nà tí kì yóò fàyè gba ìkọlùkọgbà ohùn tí ohùn orin tí ń ròkè jù lọ nínú àwọn kan lára àwọn aago náà ń fà. Aago kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú nǹkan onímẹ́táàlì rírọ̀ tí ń lù ú nínú rẹ̀, ni a ń mú ṣiṣẹ́ nípa wáyà onírin tí a so mọ́ bọ́tìnnì kọ̀ọ̀kan ara clavier tó wà nísàlẹ̀. Wọ́n fara balẹ̀ díwọ̀n ìfàro náà gẹ́lẹ́ láti bá bí carillonneur ṣe ń tẹ̀ wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan, àti ipò ojú ọjọ́ àkókò náà mu.
Àwọn Kókó Díẹ̀ Tí Ń Pàfiyèsí
Wọ́n rọ àwọn aago inú carillon ti Canberra ní ilé arọ́ ti Ilé Iṣẹ́ John Taylor ní England, wọ́n sì jẹ́ àpẹẹrẹ dáradára iṣẹ́ ọnà àtijọ́ ní ọ̀rúndún ogún. Àwọn aago náà lè gbé ohùn orin aládùn wọn jáde sókè tó 300 mítà sọ́tùn-ún, sósì, síwá, sẹ́yìn, la àwọn adágún omi náà kọjá lọ sí àwọn ọgbà ọ̀gbìn àti ọgbà ìtura tó wà lódì kejì lọ́hùn-ún.
Carillon tí ó ní agogo 53 yìí kọ́ ni ó tóbi jù lọ lágbàáyé, ṣùgbọ́n a kà á sí ọ̀kan lára wọn, nítorí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn carillon máa ń ní láàárín agogo 23 sí 48. Bí ó ti wù kí ó rí, carillon tí ó tóbi jù lọ ń bẹ ní Ìlú Ńlá New York. Ó ní agogo 74. Tirẹ̀ náà ni agogo olóhùn orin títóbi jù lọ lágbàáyé. Ìwọ̀n aago yìí lé ní tọ́ọ̀nù 18, ó sì ní ohùn ìsàlẹ̀ kẹta (low C), ní ìfiwéra pẹ̀lú carillon ti Canberra tí ó ní ohùn ìsàlẹ̀ kẹfà tí ó gan (low F sharp).
Ẹ jẹ́ kí a wá gbádùn ohùn orin kan tí carillonneur fi dá wa lára yá. Ṣé ká lọ jókòó nínú ọgbà nísàlẹ̀? Níhìn-ín ohùn orin aládùn “ilé gogoro tí ń kọrin” nìkan kọ́ la óò gbọ́, ṣùgbọ́n a óò máa gbádùn àwọn ohun àgbàyanu ìṣẹ̀dá tí ó yí wa ká nígbà kan náà. Ìfẹ́lóló afẹ́fẹ́ ìrọ̀lẹ́ àti ìgagògòrò wíwọni lọ́kàn àwọn aago náà para pọ̀ láti mú ohùn orin tí ó jọ tẹ̀mí, tí ń fi ìmoore kún ọkàn-àyà wa fún ẹ̀bùn àtọ̀runwá ti orin kíkọ, jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn aago inú ilé gogoro náà