Má Fi Ṣòfò, Má Ṣàìní
NÍNÚ àwùjọ aláràjẹ wa òde òní, ìpalẹ̀mọ pàǹtírí àti àwọn èròjà eléwu tí a kò nílò mọ́, lọ́nà tí kò léwu, ti di ohun tí ń dẹ́rù bani. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ìṣẹ̀dá Ọlọ́run jẹ́ àgbàyanu àìfiǹkanṣòfò àti àlòtúnlò. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò afárá oyin. Àtè oyin, ohun èèlò tí a fi ń kọ́ afárá oyin, wọ́nwó gan-an—oyin kán nílò oyin ìwọn gíráàmù 16 àti ìwọn lẹ́búlẹ́bú tí a kò mọ̀, láti ṣe kìkì ìwọn gíráàmú àtè oyin kan. Báwo ni àwọn oyín ṣe ń díwọ̀n ìṣirò àtè oyin wọn? Ìwé By Nature’s Design ṣàlàyé pé: “Àwọn ògiri àtè horo kéékèèké afárá oyin náà ń so pọ̀ ní mẹ́ta-mẹ́ta ní igun oníwọ̀n ìlàta ìpòbìrìkótó, tí ó di ìrísí onígun mẹ́fà ní ìtòpọ̀ bíbára dọ́gba. Bátànì yìí ń mú kí oyín lo afárá níwọ̀nba, nígbà tí ó tún ń pèsè ìrísí ìgbékalẹ̀ tí ó nípọn, nínú èyí tí wọ́n ń fi oyin pamọ́ sí.” Báyìí ni ìrísí oníhùmọ̀ kan ṣe ń pa ẹwà ìrísí pọ̀ mọ́ àìfagbáraṣòfò, ó sì ṣeé lò lálòtúnlò!
Bí o bá máa ń gbádùn kíka àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ lórí sáyẹ́ǹsì àti àwọn ohun àgbàyanu inú ìṣẹ̀dá, tí o sì ń fẹ́ láti máa gba Jí! déédéé, kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àdúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ nínú èyí tí a tò sí ojú ìwé 5.