Ìdí Tí Ó Fi Yí Ohun Àkọ́múṣe Rẹ̀ Padà
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ BRITAIN
Ìró ohùn orin adùnyùngbà kán gba afẹ́fẹ́ kan lójijì. Ohùn orin tí ń dún ketekete náà ń ró jáde, ó jọ pé kí yóò lópin. Mo dúró láìlè yíra padà. Jeremy kẹ́ ẹ sọ pé: “Olóbùró ni!” A fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ yọ́ gúlọ́ yí ìgbẹ́ náà po, tí a ń gbìyànjú láti fojú bu ibi tí ohùn ológo náà ti ń wá. Nígbà náà ni a fojú gán-ánní onítìjú ẹyẹ aláwọ̀ ilẹ̀ mímọ́ roro, tí kò rọrùn láti rí nínú ìgbẹ́ náà. Bí a ti fẹ́ẹ́ kúrò níbẹ̀ níkẹyìn, Jeremy sọ pé: “Ó dára tí a rí i. Ṣàṣà ènìyàn níí rí i láé.”
MO WÁÁ lo ọjọ́ náà pẹ̀lú Jeremy, olùṣọ́gbà Minsmere, igbó àìro tí ó fẹ̀ tó 800 hẹ́kítà, tí Ẹgbẹ́ Aláyélúwà fún Ìdáàbòbò Ẹyẹ (RSPB) ń bójú tó, ní apá ìlà oòrùn jù lọ ní ilẹ̀ England. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, a ya omi lu apá etíkun Òkun Àríwá yìí, láti gbéjà ko ìsàgatì tí ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹgbẹ́ ogun Germany ṣe. Ní àbáyọrí rẹ̀, ó di àkùrọ̀ oníkoríko gíga, tí àwọn ẹyẹ ilẹ̀ àkùrọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí í múlé sínú àwọn pápáko rẹ̀ tí omí ya sí. Ìrusókè ṣẹlẹ̀ nígbà tí takọtabo mẹ́rin ẹyẹ avocet kọ́ ìtẹ́ wọn síbẹ̀ ní 1947, nítorí pé irú ọ̀wọ́ yìí kò ti sí ní Britain fún èyí tí ó lé ní 100 ọdún.
Ẹgbẹ́ RSPB gba ilẹ̀ náà, ó sì ti wáá di agbègbè ìdáàbòbò kan tí ó ní ìjẹ́pàtàki kárí ayé ní báyìí. Ní àfikún sí àwọn àkùrọ̀ oníkoríko gíga wọ̀nyẹn, àwọn ibi tí àwọn ẹyẹ ń gbé náà tún kan àwọn adágún oníyọ̀ àti adágún aláìníyọ̀—tí wọ́n ń pe èyí tí ó tóbi jù lára wọn ní Scrape—ilẹ̀ etídò olókùúta ṣágiṣàgi, iyanrìn tí afẹ́fẹ́ gbá jọ, àfọ̀, pẹ̀tẹ́lẹ̀ eléwéko tútù, ilẹ̀ tí a kò lò, àti igbo onígi arẹ̀dànù àti onígi tí kì í gbọnwé. Ó lé ní 330 irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí a ní lákọsílẹ̀, nǹkan bí 100 lára wọn ń pamọ nínú igbó àìro náà. Ní pàtàkì, ìjónírúurú kíkàmàmà àwọn ẹyẹ wọ̀nyí jẹ́ nítorí àwọn ọ̀nà ìṣíkiri tí ó gba ìhà òkun ìlà oòrùn kọjá, ṣùgbọ́n, àbójútó amọṣẹ́dunjú tún ti kó ipa tirẹ̀ náà.
Jeremy sọ fún mi pé: “Mo wá síhìn-ín ní 1975, nítorí igbó Minsmere gbé ìpèníjà àrà ọ̀tọ̀ dìde. Láti 1966, ẹyẹ avocet di àmì ẹgbẹ́ RSPB, ó sì wáá di àwòrán àmi rẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Igbó àìro Minsmere ni ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ń wò bí igbó àìro pàtàkì jù lọ tí ẹgbẹ́ RSPB ní, tí ń gbà tó 80,000 olùṣèbẹ̀wò lálejò lọ́dọọdún.”
Ìpèníjà Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀
Bí a ti ń rìn lọ, Jeremy ń bá ọ̀rọ rẹ̀ lọ pé: “A tanná ran ìfẹ́ ọkàn mi ní ilé ẹ̀kọ́. Níbẹ̀ ni mo ti kọ́ láti máa fòrùka ìdámọ̀ bọ ẹyẹ lẹ́sẹ̀, mo sì kọ́ nípa ìṣíkiri ẹyẹ. Nígbà tí àwọn ọdún 1960 fi ń parí lọ, mo máa ń fòrùka bọ nǹkan bí 12,000 sí 20,000 ẹyẹ lẹ́sẹ̀ lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí eré àfipawọ́. Nígbà náà ni Chris Mead ti Ẹgbẹ́ Ẹ̀kọ́ Nípa Ẹyẹ Ilẹ̀ Britain ké sí mi láti dara pọ̀ nínú ìrìn àjò ìwádìí kan sí ilẹ̀ Sípéènì láti lọ fi òrùka bọ ẹsẹ̀ àwọn ẹyẹ tí ń rìn la aṣálẹ Sahara já. Àwọ̀n tí a lò ní okùn àwọ̀n dúdú tí ó wẹ́, tí ó gùn tó mítà 6 sí 18, tí a so rọ̀ gẹgẹrẹ, tí a sì fọgbọ́n dẹ sí ẹ̀yìn igi, kí àwọn ẹyẹ́ má baà rí i. A kò pa àwọn ẹyẹ náà lára, bí a sì ti ń mú wọn jáde kúrò nínú àwọ̀n ni a ń fi òrùka ìdámọ̀ kékeré kan tí a sábà máa ń fi Mẹ́táàli Monel ṣe sí ẹsẹ̀ kan.a Jíjù àwọn ẹyẹ sílẹ̀ gba ọgbọ́n ọnà pẹ̀lú. Ẹni tí ń fòrùka bọ ẹsẹ̀ ẹyẹ kò jẹ́ ju ẹyẹ sáfẹ́fẹ́, bí o ti sábà máa ń rí i lórí tẹlifíṣọ̀n. Ó wulẹ̀ ń jẹ́ kí wọ́n lọ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ láti lọ ni. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ẹyẹ swift yóò dì mọ́ aṣọ ẹni, wọn yóò sì fò lọ nígbà tí wọ́n bá ṣe tán.
“Ìrírí fífani lọ́kàn mọ́ra kan ni, nítorí èyí tí mo gba ìsinmi ọ̀sẹ̀ mẹ́fà lẹ́nu iṣẹ́—tí mo sì pàdánù iṣẹ́ mi! Àbájáde rẹ̀ ni pé, mo pinnu láti ṣe ìyípadà òjijì, mo sì dáwọ́ lé iṣẹ́ tí mo fẹ́ràn—ìdáàbò bo ìṣẹ̀dá, ní pàtàkì, àwọn ẹyẹ. Mo láyọ̀ gan-an nígbà tí ẹgbẹ́ RSPB ké sí mi láti dara pọ̀ mọ́ wọn ní 1967.”
Ìníyelórí Orin àti Ìró Ẹyẹ
Báwo ni a ṣe ń dá ẹyẹ kan mọ̀? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, nípa rírí i, ṣùgbọ́n ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nípa orin, tàbí ìró ẹyẹ́ túbọ̀ láyọ̀lé gan-an. Ìjáfáfa Jeremy ní apá yìí gbàfiyèsí. Onímọ̀ ìṣẹ̀dá David Tomlinson kọ̀wé pẹ̀lú ìkansáárá pé Jeremy “kò wulẹ̀ ń fi orin wọn dá àwọn ẹyẹ mọ̀, ṣùgbọ́n mo lè fàda rẹ̀ gbárí pé, ó lè fí ìyàtọ̀ nínú bí wọ́n ṣe ń fa afẹ́fẹ́ tó láàárín orin wọn sọ ìyàtọ̀ láàárín wọn!”
Jeremy ṣàlàyé pé: “Àwọn ẹyẹ ń fọ̀rọ̀ wérọ̀. Ìró kọ̀ọ̀kán ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Fún àpẹẹrẹ, bí apanijẹ kán bá wà nítòsí, àwọn ẹyẹ avocet, lapwing, àkẹ̀, àti àwọn redshank, gbogbo wọ́n ní ìró pàtó tiwọn, ṣùgbọ́n ìró kọ̀ọ̀kán túmọ̀ sí ohun kan náà pé: ‘Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan ń bẹ nítòsí!’ Mo lè ta jí lójú oorun àsùnwọra, kí n sì mọ ibi tí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kán wà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nítorí irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí ń ké. Ṣùgbọ́n má ṣe gbàgbé pé àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní agbára ìgbọ́rọ̀ títayọ lọ́lá pẹ̀lú. A ṣe kàyéfì lórí ìdí tí àwọn ẹyẹ tern kò fi ṣàṣeyọrí ní pípamọ lọ́dún kan, a sì ṣàwárí pé kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan ń tẹ́tí sí igbe àwọn ọmọ ẹyẹ náà láti inú ẹyin wá, kété kí a tóó pa wọ́n. Gbàrà tí ó bá ti mọ ibi tí wọ́n wà, ó ń kó wọn jẹ!”
Iṣẹ́ Ọnà Ṣíṣọ́ Ẹyẹ
Olùṣọ́ ẹyẹ dídáńgájíá kan ní Britain lè ṣàkọsílẹ̀ 220 irú ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ọdún kan. Àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹyẹ ṣíṣọ̀wọ́n, àwọn akíyànyán olùṣọ́ ẹyẹ́ lè dá iye tí ó tó 320 mọ̀.b Bí wọ́n bá ti gbọ́ pé a kófìrí ọ̀kan, yóò ta wọ́n nídìí páá la orílẹ̀-èdè náà já, kí wọ́n lè lọ fojú ara wọn rí i. Jeremy ti túbọ̀ nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ó sọ ọ́ láṣìírí pé: “Èmi kì yóò wakọ̀ lọ kọjá máìlì mẹ́wàá [kìlómítà 16] nítorí irú ọ̀wọ́ ṣíṣọ̀wọ́n kankan. Ní ti gidi, mẹ́ta péré ni mo tí ì wá lọ rí: nutcracker kan, sandpiper aláwọ̀ òfefèé láyà kan, àti bustard bàgùjẹ̀ kan, tí gbogbo wọn kò jìnnà ju máìlì mẹ́wàá lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ 500 irú ọ̀wọ́ dunjú, ìwọ̀n kéréje kan péré ni mo mọ̀ yẹn. O jẹ́ mọ̀ pé nǹkan bí 9,000 irú ọ̀wọ́ ẹyẹ ní ń bẹ kárí ayé!”
Bí a ti ń darí awò wa sí àwọn àfọ̀ náà, Jeremy fi kún un pẹ̀lú ìyánhànhàn pé: “Ní pàtàkì, nípa ọdún 16 tí mo ti lò ní Minsmere, n kò lè ronú ìgbésí ayé aláyọ̀ tàbí aláǹfààní kan tí ó sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ!” Mo yíjú wo ọ̀dọ rẹ̀, mo sì rántí àpilẹ̀kọ tí ó jáde láìpẹ́ nínú ìwé agbéròyìnjáde London náà, The Times. Ó sọ pé: “Minsmere ní ń dé àṣeyọrí rẹ̀ [Jeremy] ládé, iṣẹ́ ìgbésí ayé rẹ̀.” Jeremy fẹ́ẹ́ fi Minsmere sílẹ̀. Èé ṣe?
Hóró Irúgbìn àti Ìdàgbà
Ṣáájú lọ́jọ́ náà, a ti fojú rí ìran àrà ọ̀tọ̀ ìbádàpọ̀ láàárín àwọn ẹyẹ avocet. Jeremy sọ pé: “A kò lè so ẹwà inú rẹ̀ pọ̀ mọ́ oríṣi ìlàájá ẹfolúṣọ̀n kankan. Ṣùgbọ́n mo rántí pé, ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, nígbà tí a bi mí bóyá mo gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kan ń bẹ, mo jẹ́wọ́ gbà pé: ‘N kò ní èrò kankan nípa rẹ̀—bẹ́ẹ̀ sì ni n kò mọ bí mo ṣe lè ṣàwárí rẹ̀!’ Nítorí náà, nígbà tí a rọ̀ mí láti ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì wí, mo gbà láìjampata. N kò mọ ohun púpọ̀ nípa rẹ̀, mo sì rò pé kò pa mí ládàánù kankan—àti bóyá ó tilẹ̀ lè ṣe mí láǹfààní. Nísinsìnyí, nítorí àwọn ohun tí mo ti kọ́, mo ń fi Minsmere sílẹ̀ láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.”
Fún ọdún mẹ́wàá, Michael, ẹ̀gbọ́n Jeremy ọkùnrín ti jẹ́ “aṣáájú ọ̀nà,” èdè ọ̀rọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò láti júwe àwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún wọn. Bí a ti jókòó, tí a ń mu tíì wa, Jeremy bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn ìwéwèé rẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ arákùnrin rẹ̀. Jeremy ṣàlàyé pé: “Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tí mo ṣe. Ẹgbẹ́ RSPB lọ́kàn ìfẹ́, wọ́n sì bìkítà. Wọ́n ti fún mi ní ìtìlẹ́yìn wọn kíkún, wọ́n sì tilẹ̀ tún dámọ̀ràn mi fún ẹ̀bùn ìtóótun kan tí orílẹ̀-èdè ń fi fúnni.”
Síbẹ̀, mo mọ̀ pé àwọn ìṣelámèyítọ́ kan ti wà tẹ́lẹ̀.
Àìní Láti Wà Déédéé
Jeremy sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló tì mí lẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó dunni pé, ó jọ pé àwọn mìíràn ní ojú ìwòye tí kò tọ̀nà nípa iṣẹ́ mi níhìn-ín. Wọ́n rò pé ààbò títóbi jù lọ sí jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí ni sísún mọ́ ìṣẹ̀dá, bíbójú tó ìṣẹ̀dá inú igbó—ṣíṣiṣẹ́ fún ìdáàbòbò. Wọ́n ń sọ fún mi pé gbogbo bí o ṣe lè sún mọ́ párádísè tó nìyí, èé ṣe tí o fi ń lọ nígbà náà?
“Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ náà ní ìhà tẹ̀mí kan, ṣùgbọ́n ìyẹn kò mú kí ó dọ́gba pẹ̀lú jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí. Jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí jẹ́ ohun àdáni, ànímọ́ kan tí ń gba àkókò láti mú un dàgbà. Ó kan àìní láti kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ Kristẹ̀nì, kí o sì bójú tó o, láti gbéni ró, kí a sì gbé ọ ró. Nígbà míràn, mo ti máa ń nímọ̀lára pé mo ti ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí Jésù sọ pé a kò lè ṣe—sìnrú fún ọ̀gá méjì. Mo wáá mọ̀ nísinsìnyí pé àyíká tí ó láàbò jù lọ wà láàárín ìjọ Kristẹni, ọ̀nà láti débẹ̀ sì ni láti ṣe aṣáájú ọ̀nà!”
Ohun Àkọ́múṣe ti Àbójútó
“Má ṣì mí gbọ́ o. Ṣíṣàbójútó gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́gbà jẹ́ ìrírí afani lọ́kàn mọ́ra tí ó sì ṣàǹfààní, bí ó tilẹ̀ ń tánni ní sùúrù nígbà míràn. Fún àpẹẹrẹ, ìbàjẹ́ tí PCB àti mercury ń ṣe ní ibùgbé yìí ti dé ìpele tí ń dani láàmú—a kò sì mọ ìdí rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fura pé àwọn ẹja àdàgbá ní ń kó o wọlé.c Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí mo lè ṣe láti ṣàtúnṣe ìwàdéédéé náà láàlà. Kò sí iru ẹni tí a lè pè ní onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti pẹ̀lú ibùgbe wọn, tí ó pegedé. Gbogbo wá wulẹ̀ ń táràrà ká ni, tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ bí a ti lè ṣe tó. A nílò ìtọ́sọ́nà. Ẹlẹ́dàá wa nìkan ni ó mọ bí ó ṣe yẹ kí a gbé ìgbésí ayé, kí a sì bójú tó ilẹ̀ ayé àti onírúurú ohun alààyè rẹpẹtẹ inú rẹ̀.”
Jeremy ṣàkópọ̀ ìmọ̀lára rẹ̀ ní jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ báyìí: “N kò ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà láti máà dáàbò bo ohun alààyè inú ìgbẹ́; òun fúnra rẹ̀ tóótun lọ́nà pípegedé láti ṣe ìyẹn. Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, yóò rí i dájú pé àwa ń bójú tó àwọn ohun alààyè inú ìgbẹ́ lọ́nà tí òún fẹ́ kí a gbà ṣe bẹ́ẹ̀ títí. Wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà gbọ́dọ̀ gba ipò àkọ́kọ́ nísinsìnyí, bí n óò bá bójú tó ẹrù iṣẹ́ mi láti bìkítà fún àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ mi.”
Mo tún bá Jeremy pàdé láìpẹ́ yìí. Ó ti di ọdún mẹ́ta sẹ́yìn tí a ti jọ lo ọjọ́ aláyọ̀ yẹn pọ̀ nínú igbó àìro yẹn. Nísinsìnyí, ó ń gbé ní kìlómítà mẹ́jọ sí Minsmere tí ó fẹ́ràn gan-an yẹn, ó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó sọ fún mi pé, àwọn kán sọ pé ó ṣì ṣòro fún àwọn láti lóye ìdí tí ó ṣe fi iṣẹ́ sílẹ̀. Ìwọ ńkọ́? Ní ti Jeremy, ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ohun àkọ́múṣe kan lásán ni.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Mẹ́táàli Monel jẹ́ àdàlú nickel àti bàbà tí ó lágbára, tí kì í sì í dógùn-ún.
b Ní United States, a mọ àwọn tí ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹyẹ ṣíṣọ̀wọ́n dunjú gẹ́gẹ́ bíi listers [àwọn aṣàkọsílẹ̀ ẹyẹ ṣíṣọ̀wọ́n].
c Àpèjá PCB ni polychlorinated biphenyl, àṣẹ́kù pàǹtírí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìdùnnú Tí Ń gbani Lọ́kàn
Kìki ènìyàn 1 nínú 10 ni yóò lè rí olóbùró tí wọ́n ń gbúròó rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ènìyán bá ti gbọ́ orin rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, kò ṣeé gbàgbé mọ́. Simon Jenkins kọ̀wé nínú ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London pé: “Ògidì orin ni, ohun kan tí ó pé pérépéré, tí a sì ti ṣe parí.” Àkọọ̀dánudúró ni ẹyẹ náà sábà máa ń kọrin—àkọsílẹ̀ wà pé ọ̀kán kọrin fún wákàtí márùn-ún àti ìṣẹ́jú 25. Kí ló mú orin náà jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́? Gògóńgò olóbùró lè mú oríṣi ohun orin mẹ́rin jáde lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó sì ní tán-ánná tí ó pegedé fún orin kíkọ. Ó sì lè ṣe èyí nígbà tí àgógó ẹnu rẹ̀ bá wà ní pípadé tàbí tí ó di oúnjẹ tí yóò fún ọmọ rẹ̀ sẹ́nu. Èé ṣe tí ó fi máa ń kọrin pẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Àwọn olùkíyèsí kán sọ pé, ó jẹ́ nítorí ìdùnnú tí ó ń mú wá lásán. Jenkins parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Ǹjẹ́ gbogbo ìṣẹ̀dá lápapọ̀ ní ẹ̀dá kan tí ń ṣeni ní kàyéfì ju gògóńgò olóbùró kan lọ bí?”
[Credit Line]
Roger Wilmshurst/RSPB
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Scrape náà
[Credit Line]
Ìyọ̀ǹda onínúure Geoff Welch
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹyẹ àkẹ̀ olórí dúdú
[Credit Line]
Ìyọ̀ǹda onínúure Hilary & Geoff Welch
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹyẹ “avocet”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹyẹ “Sandwich tern”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ẹyẹ “Redshank”