Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 21. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)
1. Kí ni Jésù ti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ láti má ṣe mú dání nígbà tí wọ́n bá ń wàásù lákọ̀ọ́kọ́ tí ó wáá sọ pé kí wọ́n mú dání lẹ́yìn náà? (Lúùkù 22:35, 36)
2. Láìdà bí ẹ̀jẹ̀, kí ni a kà léèwọ̀ fún orílẹ̀-ède Ísírẹ́lì nìkan láti má ṣe jẹ? (Léfítíkù 3:17)
3. Níbo ni Gídéónì wà nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà yanṣẹ́ fún un láti jẹ́ olùgbàlà fún Ísírẹ́lì? (Àwọn Onídàájọ́ 6:11-14)
4. Wòlíì wo ni òun nìkan, láàárín nǹkan bí 400, sọ òtítọ́ fún Ọba Áhábù nípa ìgbétásì ológun rẹ̀ tí ó fẹ́ẹ́ ṣe lòdì sí àwọn ará Síríà? (Àwọn Ọba Kìíní 22:13)
5. Kí ni òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun gbígbẹ ti Hébérù tí a fi ń wọn mánà fún ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan lójoojúmọ́ láàárín 40 ọdún ìrìn àjo wọn nínú aginjù? (Ẹ́kísódù 16:16)
6. Kí ni a sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú alágbára ńlá Nínéfè yóò dà? (Sefanáyà 2:13)
7. Orí òkè ńlá wo ni Mósè kú sí lẹ́yìn tí ó ti wo Ilẹ̀ Ìlérí? (Diutarónómì 32:49, 50)
8. Ẹranko wo, tí ó máa ń padà sínu yíyí gbiri nínú ẹrẹ̀ lẹ́yìn tí a ti wẹ̀ ẹ́, ni Pétérù fi àwọn Kristẹni tí wọ́n padà sínú ọ̀nà ìgbésí ayé wọn àtẹ̀yìnwá wé? (Pétérù Kejì 2:22)
9. Irú ilé wo ni a mẹ́nu kàn nínu Bíbélì, kìkì nínú ìwe Kíróníkà Kìíní, Nehemáyà, Ẹ́sítérì, àti Dáníẹ́lì? (Dáníẹ́lì 8:2, NW)
10. Kí ni Òwe 23:27 fi àgbèrè wé?
11. Orúkọ oyè wo ni Fẹ́sítọ́ọ̀sì lò nígbà tí ó ń tọ́ka sí Késárì Nérò? (Ìṣe 25:21)
12. Àwọn alábòójútó arìnrìn àjò méjì wo ni ó wà pẹ̀lu Tímótì ní Kọ́ríńtì nígbà tí a ń fi ìkíni àti ìṣírí ránṣẹ́ sí ìjọ tí ó wà ní Tẹsalóníkà? (Tẹsalóníkà Kìíní 1:1)
13. Kí ni Jákọ́bù sọ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà gẹ́gẹ́ bí èyí “tí ó mọ́ tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin” kìkì bí ẹnì kán bá pa ara rẹ̀ mọ́ “láìní èérí kúrò nínú ayé”? (Jákọ́bù 1:27)
14. Ìgbà mélòó lọ́dọọdún ni gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ní láti “fara hàn níwájú [Jèhófà]” ní Jerúsálẹ́mù? (Diutarónómì 16:16)
15. Kí ni Jésù jẹ láti fi han àwọn aposteli rẹ̀ pé ẹ̀mí kan kọ́ ni wọ́n ń rí nígbà tí ó fara hàn wọ́n lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀? (Lúùkù 24:36-43)
16. Kí ni Orin Dáfídì 146:3 sọ pé o kò gbọdọ̀ ṣe, nítorí pé àwọn ènìyàn kì í ṣe orísun ìgbàlà?
17. Láàárín oríṣi ewéko wo ni a fi ọmọdé náà, Mósè, pa mọ́ sí nínú ìgbìyànjú láti dáàbò bò ó kí Fáráò má pa á? (Ẹ́kísódù 2:3)
18. Òrìṣa Filistini wo ni a tẹ́ lógo níwájú àpótí mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti Jèhófà? (Sámúẹ́lì Kìíní 5:2-7)
19. Kí ni Ọlọ́run pè ní “àpótí ẹsẹ̀” rẹ̀? (Ìṣe 7:49)
20. Igi ṣíṣọ̀wọ́n, tí ó sì ṣeyebíye, wo ni a lò nínu kíkọ́ tẹ́ḿpìlì àti àwọn ohun èlò orin? (Àwọn Ọba Kìíní 10:12)
21. Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì wo ni ó sọ ọ̀rọ̀ “láti ẹnu Ọlọ́run wá” sí Ọba Jòsáyà, tí kò gbọ́ràn, tí a sì pa? (Kíróníkà Kejì 35:22)
22. Kúrò nínú kí ni obìnrin kán di òmìnira nígbà tí ọkọ rẹ̀ bá kú? (Róòmù 7:3)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Àsùnwọ̀n oúnjẹ
2. Ọ̀rá
3. Ní Ọ́fírà
4. Mikáyà
5. Ómérì
6. Ahoro gbígbẹ bí aginjù
7. Òkè Ńlá Nébò
8. Abo ẹlẹ́dẹ̀
9. Ilé ńlá olódi (NW)
10. Ihò jíjìn
11. Ẹni Ọlọ́lá
12. Pọ́ọ̀lù àti Sílífánù
13. Irú ọ̀nà ètò ìjọsìn
14. Mẹ́ta
15. Ẹyọ ẹja sísun kan
16. Gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn
17. Koríko odò
18. Dágónì
19. Ilẹ̀ ayé
20. Algumu
21. Nékò
22. Òfin rẹ̀