ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Owó Gegere Tí Ìwà Ọ̀daràn Ń Náni
  • Àwọn Ọkùnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkangbé Oníwà Wíwọ́
  • Àwọn Ìbọ̀wọ́ Tí Ń Jò
  • Gbígbógun Ti Àwọn Ẹlẹ́tàn Onílèérí Òfo
  • Àwọn Ìṣòro Ìlera ní Ilẹ̀ Brazil
  • Àìtó Ẹ̀yà Ara
  • Aládùúgbò Tí Ń Náni Lówó Gọbọi
  • Adúrótini Ẹja Sea Horse
  • Ìyánhànhàn fún Àwọn Mẹ́táàlì Lílágbára
  • “Síseǹkan—àti Mímí Pẹ̀lú Ìnira—Pẹ̀lú Gáàsì”
  • Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu—Báwo Ni Ohun Tí Ń Náni Ṣe Pọ̀ Tó?
    Jí!—1997
  • Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Á Gba Aráyé Lọ́wọ́ Àìsàn?
    Jí!—2007
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Àjàkálẹ̀ Àrùn ní Ọ̀rúndún Ogún
    Jí!—1997
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Owó Gegere Tí Ìwà Ọ̀daràn Ń Náni

Ẹ̀ka Ìdájọ́ ṣèdíwọ̀n pé nǹkan bí 94,000 ìwà ọ̀daràn ní ń ṣẹlẹ̀ ní United States lójoojúmọ́. Èló ni ìwà ọ̀daràn wọ̀nyí ń ná àwọn aráàlú United States? Gẹ́gẹ́ bí aṣàtúpalẹ̀ ètò ọrọ̀ ajé, Ed Rubenstein, ṣe sọ, iye tí ń náni ní tààrà—títí kan àdánù ohun ìní ara ẹni, bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, owó, àti ohun ọ̀sọ́—sún mọ́ 20 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún. Bí ó ti wù kí ó rí, ìnáwó tí ó kan ẹ̀ka ìgbófinró, ilé ẹjọ́, ọgbà ẹ̀wọ̀n, àti ètò ìdásílẹ̀ ẹlẹ́wọ̀n tí kò tí ì parí ọjọ́ ẹ̀wọ̀n wà láfikún sí i. Èyí mú iye náà lọ sí nǹkan bí 100 bílíọ̀nù dọ́là. Pẹ̀lúpẹ̀lú, níwọ̀n bí àwọn òjìyà ìpalára ìwà ọ̀daràn ti sábà máa ń jìyà ìbẹ̀rù, hílàhílo, tàbí ìsoríkọ́, ọ̀pọ̀ ń kojú ìmọ̀lára òdì wọ̀nyí nípa ṣíṣàìlọ síbi iṣẹ́. Nítorí náà, àdánù lórí ìṣèmújáde lè gbé “àròpọ̀ iye tí ìwà ọ̀daràn ń ná àwọn òjìyà rẹ̀” lọ sókè sí “250 sí 500 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dọọdún,” gẹ́gẹ́ bí Rubenstein ṣe sọ.

Àwọn Ọkùnrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkangbé Oníwà Wíwọ́

Ìwé ìròyìn World Press Review ròyìn pé, àṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkangbé onísìn Búdà kan ní Thailand, tí ó ti sọ oògùn amphetamine di bárakú, ti jẹ́wọ́ pé òun fipá bá arìnrìn àjò afẹ́, ará Britain, ẹni ọdún 23, kan lò, òun sì pa á. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwà ọ̀daràn yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára “ọ̀wọ́ àwọn ìwà láìfí atinilójú” tí ó ti gbilẹ̀ láàárín àwọn àlùfáà ìsìn Búdà ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ni. “Ní àfikún sí iye ẹ̀ṣẹ̀ ìwà ọ̀daràn tí ń pọ̀ sí i, ìwọra ohun ìní ń ba ìsìn Búdà jẹ́.” Lọ́nà wo? “Títa àwọn oògùn oríire jẹ́ òwò tí ń mówó wọlé gan-an fún àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkangbé mélòó kan tí ń gun ọ̀bọ̀kún ọkọ̀ dọ̀ọ̀mìdọ̀ọ̀mì kiri pẹ̀lú awakọ̀ tí ń wà wọ́n.” Ní ìyọrísí rẹ̀, “ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn nínú àwùjọ àlùfáà ìsìn Búdà tí wọ́n ń bọlá fún tẹ́lẹ̀ ti ń rùbéèrè sókè.” Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé, nínú ìsapá kan láti kápá “ìlòkulò oògùn” láàárín àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkangbé, “àwọn ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti ṣí ibùdó ìdínkù agbára oògùn líle.”

Àwọn Ìbọ̀wọ́ Tí Ń Jò

Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé ìbọ̀wọ́ tọ̀tún-tòsì onírọ́bà kan ṣoṣo lè ṣàìtó láti dáàbò bo ẹni tí ó wọ̀ ọ́ lọ́wọ́ fáírọ́ọ̀sì HIV tàbí àrùn mẹ́dọ̀wú. Òpin èrò tí àwọn olùwádìí ní Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìṣègùn ti Wisconsin dé nìyẹn, nígbà tí wọ́n ṣàwárí pé “ìbọ̀wọ́ kan nínú mẹ́ta máa ń fàyè gba àwọn fáírọ́ọ̀sì tí ó tóbi ní ìwọ̀n fáírọ́ọ̀sì HIV tàbí ti àrùn mẹ́dọ̀wú.” Jordan Fink, olórí ẹ̀ka egbòogi tí kò bára dé ní yunifásítì náà, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn ìbọ̀wọ́ onírọ́bà lẹ́yìn tí àwọn dókítà àti àwọn olùtọ́jú aláìsàn ti ṣàròyé nípa ìhùwàpadà àìbáradé ní 1992. Ọdún yẹn ni ìjọba United States bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè pé kí àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn máa wọ ìbọ̀wọ́ onírọ́bà bí ó bá ṣeé ṣe kí wọn fara kan ẹ̀jẹ̀ tàbí omi ara aláìsàn. Ìwé ìròyìn náà sọ pé, gẹ́gẹ́ bi Fink ṣe wí, àwọn òṣìṣẹ́ ìtọ́jú ìlera tí wọ́n bá ní ibi tí nǹkan ti gé wọn lára tàbí ibi tí ó ṣí sílẹ̀ nínú awọ ara gbọ́dọ̀ ronú nípa wíwọ àkànpọ̀ ìbọ̀wọ́. Bí ó ti wù kì ó rí, àwọn òṣìṣẹ́ ìṣègùn tí kò ní ibi tí ó là lára kò gbọ́dọ̀ ṣèyọnu láìnídìí. Fink sọ pé: “Awọ ara tí kò ní ibi tí ó bù kankan jẹ́ ìdíwọ́ gbígbéṣẹ́ kan.”

Gbígbógun Ti Àwọn Ẹlẹ́tàn Onílèérí Òfo

Lẹ́yìn tí Paula Lyons ti lo ọdún 17 bí oníròyìn ọjà rírà fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àdúgbò kan ní Boston, Massachusetts, ó ti ṣàkójọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ọ̀nà kan láti ṣẹ́pá “ọgbọ́n iṣẹ́ àti àìdẹwọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.” Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Ladies’ Home Journal ṣe wí, lára àwọn àbá Lyons ni pé: Kọ̀ jálẹ̀ láti bá àjèjì tí ó bá tẹ̀ ọ́ láago dòwò pọ̀ lórí tẹlifóònù. Má ṣe dókòwò lórí ohun tí kò yé ọ. Má ṣe san ohunkóhun kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ẹ̀bùn “ọ̀fẹ́.” Má ṣe ní ìgbàgbọ́ dan-indan-in nínú àwọn ìlérí láti sanwó rẹ padà bí ọjà kò bá tẹ́ ọ lọ́rùn. Yẹra fún ṣíṣètọrẹ fún ẹgbẹ́ aláàánú tí o kò mọ̀. Má ṣe ra àlòkù ọkọ̀ láìjẹ́ pé, mẹ́káníìkì adáṣẹ́ṣe kan kọ́kọ́ yẹ̀ ẹ́ wò. Lyons sọ pé: “Àwọn ìlànà wọ̀nyí lè dà bí arọ̀mọ́pìlẹ̀ lọ́nà kan ṣáá,” ṣùgbọ́n, “wọ́n lè gbà ọ́ lọ́wọ́ díẹ̀ lára ìwà ìbàjẹ́ bíburú jáì tí ó wà lọ́jà.”

Àwọn Ìṣòro Ìlera ní Ilẹ̀ Brazil

Olùdarí ibùdó ẹ̀kọ́ nípa àrùn ní orílẹ̀-èdè Brazil, Dókítà Eduardo Levcovitz, kédàárò pé: “Àwọn ènìyàn wa ti ṣàìrìnnà kore láti ní àpapọ̀ ìṣòro ìlera àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ Tí Ó Ti Gòkè Àgbà àti àwọn àrùn tí ó ṣeé dènà ti Àwọn Ilẹ̀ Tí Kò Tí Ì Gòkè Àgbà.” Bí a ṣe fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Medical Post, Dókítà Levcovitz mẹ́nu ba àwọn olórí okùnfà ìṣòro ìlera láàárín àwọn ará Brazil. Àkọ́kọ́ nínú àkọsílẹ̀ náà ni àrùn ọkàn àyà, jẹjẹrẹ, àti àwọn àrùn èémí. Tẹ̀ lé ìwọ̀nyí ni ikú tí ìwà ọ̀daràn oníjàgídíjàgan àti ìjàm̀bá ń fà. Tẹ̀ lé àwọn àrùn “Àwọn Ilẹ̀ Tí Ó Ti Gòkè Àgbà” ni àwọn àrùn tí ń gbèèràn tí ń jẹ yọ láti inú ipò ìgbésí ayé tí ko dára tó. Ìwé agbéròyìnjáde The Medical Post sọ pé: “A fojú díwọ̀n pé ìdajì àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Brazil ní oríṣi èèràn àfòmọ́ kan.” Ibà nìkan ń pọ́n nǹkan bí 500,000 àwọn ará Brazil lójú lọ́dọọdún. Àwọn àrùn míràn tí àfòmọ́ ń fà tí ó wọ́pọ̀ ní Brazil ni àrùn Chagas, àtọ̀sí ajá, hookworm, leishmaniasis, àti filariasis.

Àìtó Ẹ̀yà Ara

Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé, ní 1994, “iye àwọn ènìyàn tí ó nílò ìpààrọ̀ ẹ̀yà ara” ní United States “fi nǹkan bí ìdá mẹ́ta ju iye àwọn olùfitọrẹ lọ.” Láti 1988 sí 1994, iye àwọn ènìyàn tí a ń pààrọ̀ ẹ̀yà ara wọn ti fi ìpín 49 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè, nígbà tí àwọn tí ń fi ẹ̀yà ara tọrọ lọ sókè ní kìkì ìpín 37 nínú ọgọ́rùn-ún. Pẹ̀lú iye ẹ̀yà ara tí a nílò tí ń pọ̀ ju iye tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó lọ, ọ̀pọ̀ aláìsàn ti kú níbi ti wọ́n ti ń retí ìgbà tí ẹ̀yà ara yóò wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Nígbà tí ìwé ìròyìn New Scientist ń sọ̀rọ̀ lórí ẹtì yìí, ó sọ pé: “Bí iṣẹ́ abẹ ìpààrọ̀ ẹ̀yà ara ṣe ń di ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbà gbogbo, ènìyàn púpọ̀ sí i ń fẹ́ ẹ, iye náà sì ń pọ̀ sí i.” Ìròyìn náà tipa bẹ́ẹ̀ mẹ́nu bà á pé “ìpààrọ̀ ẹ̀yà ara ti wáá ń jìyà àṣeyọrí rẹ̀ fúnra rẹ̀.”

Aládùúgbò Tí Ń Náni Lówó Gọbọi

Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ròyìn pé, ní Britain, nígbà tí àwọn onílé kan bá ta ilé wọn, ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún wọn lábẹ́ òfin láti ṣí gbogbo èdèkòyédè àtẹ̀yìnwá tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn payá. Wọ́n ṣe àṣeyọrí láti pe opó ẹni 80 ọdún kan, tí ó kùnà láti fi tó àwọn olùrà létí pé òun ti fẹjọ́ aládùúgbò kan tí ó máa ń pariwo sun àwọn aláṣẹ àdúgbò nígbà méjì rí, lẹ́jọ́ pé kò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀. Ní báyìí, ó ti wọko gbèsè lẹ́yìn tí wọ́n ti dá a lẹ́jọ́ láti san 45,000 dọ́là. Àwọn onílé tuntun náà gbé inú ilé náà lọ́dún mẹ́fà, ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún ilé ẹjọ́ pé àwọn kò gbádùn ìgbésí ayé ní mímúlé gbe aládùúgbò wọn, wọn kò sì ní ọ̀nà míràn ju kí wọ́n ta ilé náà lọ. Láti yẹra fún irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, àwọn olùrà díẹ̀ ti yíjú sí híháyà àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ abẹ́lẹ̀ láti ṣèwádìí lórí ìwà àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di aládùúgbò wọn. Àyẹ̀wò ráńpẹ́ kan lè náni ní owó pọ́ọ́kú bíi dọ́là 75, ṣùgbọ́n àwọn olùrà kan múra tán láti san 1,500 dọ́là fún àyẹ̀wò tí ó túbọ̀ kúnná.

Adúrótini Ẹja Sea Horse

Onímọ̀ nípa ẹranko ní Oxford, Amanda Vincent, ti ṣàwárí pé àwọn ẹja sea horse máa ń dúró ti èkejì wọn jálẹ̀ ìgbésí ayé ni. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé, nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Vincent ń ṣe ìwádìí lórí irú ọ̀wọ́ Hippocampus whitei tí ń gùn ní sẹ̀ǹtímítà mẹ́wàá, ní ìhà gúúsù ìlà oòrùn etíkun Australia, ó ṣe é ní kàyéfì láti rí irú ìfọkàntánni bẹ́ẹ̀ láàárín àwọn ẹja. Ó ṣàkiyèsí pé, lóròòwúrọ̀, akọ máa ń dúró de èkejì rẹ̀ níbi tí wọ́n ti fètò sí tẹ́lẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pàdé, àwọn ẹja sea horse náà máa ń pa àwọ̀ dà, wọ́n sì máa ń jó. Mímú irú ọmọ jáde jẹ́ ìrírí tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣàjọpín rẹ̀. Abo náà yóò yé ẹyin rẹ̀, yóò sì kó wọn sínú àpò ìsàba àrà ọ̀tọ̀ kan nínú ìrù akọ. Nígbà náà ni akọ yóò sọ wọ́n dọmọ, wọn yóò sì wà nínú àpò náà títí a óò fi bí wọn. Bí ọ̀kan bá kú, èyí tí kò kú yóò tún dà pọ̀ pẹ̀lú ẹja sea horse mìíràn tí kò ní èkejì rí. Ó bani nínú jẹ́ pé, ìlàájá àwọn ẹ̀dá amúniyọ̀ wọ̀nyí wà nínú ewu, níwọ̀n bí a ti ń kó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn lọ síbi ọ̀sìn ẹja, tí a sì ń lò wọ́n nínú ìṣègùn ìbílẹ̀ Éṣíà lọ́dọọdún.

Ìyánhànhàn fún Àwọn Mẹ́táàlì Lílágbára

Nígbà tí àwọn mẹ́táàlì lílágbára, irú bíi nickel, òjé, zinc, àti cadmium, bá kó èérí bá ilẹ̀, ilẹ̀ náà di eléwu, kò sì ṣeé lò. Àwọn ọ̀nà ìpalẹ̀mọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́ ń béèrè pé kí a ha ilẹ̀ òkè téńté dà nù, kí a lọ fi dí kòtò, tàbí kí a kó ilẹ̀ tí ó bà jẹ́ náà kúrò, kí a sì da àwọn ásíìdì lílágbára tí ń kó àwọn mẹ́táàlì tí ó há sínú rẹ̀ náà kúrò. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀nà ìpalẹ̀mọ́ wọ̀nyí gbówó lérí gọbọi. Ní báyìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń ṣèwádìí nípa ọ̀nà tí ó túbọ̀ dínwó, tí ó sí túbọ̀ mọ́ sí i láti yanjú ìṣòro náà. Èyí ni wọ́n ń pè ní ìtánbàjẹ́. Ìlànà náà ní lílo àwọn ewéko tí ń gba àwọn mẹ́táàlì lílágbára láti inú ilẹ̀ sára, kí wọ́n sì fa àwọn mẹ́táàlì náà sínú ewé, ìtì, àti àwọn ẹ̀yà ara ewéko náà míràn tí ó hù lókè erùpẹ̀ nínú. Ìwé ìròyìn Science sọ pé, ní gbàrà tí a bá ti fa àwọn mẹ́táàlì lílágbára náà jáde kúrò nínú ilẹ̀, a lè ṣiṣẹ́ lórí àwọn ewéko náà, kí a sì ṣàyípoyípo àwọn mẹ́táàlì tí ó wúlò lára rẹ̀.

“Síseǹkan—àti Mímí Pẹ̀lú Ìnira—Pẹ̀lú Gáàsì”

Lábẹ́ àkọlé yẹn, ìwé ìròyìn Science News ròyìn pé àwọn olùṣèwádìí ọmọ ilẹ̀ Britain ti ṣàwárí pé “ó ṣeé ṣe kí àwọn obìnrin tí ń fi gáàsì se nǹkan ní ìrírí mímí pẹ̀lú ìnira, èémí tí kò délẹ̀, àti àwọn àmì àrùn òtútù àyà míràn ní ìlọ́po méjì sí èyí tí àwọn tí ń lo ìseǹkan oníná mànàmáná àti ààrò ń ní.” Ìwádìí náà, tí a ṣe ní Ilé Ìwòsàn Thomas Mímọ́ ní London, sọ pé àwọn àmì àrùn náà ń bá a lọ, àní nígbà tí a bá tilẹ̀ lo àwọn abẹ̀bẹ̀ òyìnbó afátẹ́gùn-jáde. Nígbà tí ó jẹ́ pé tọkùnrin tobìnrin ni ó sì lọ́wọ́ nínú ìwádìí náà, “àwọn ipa náà fara hàn lára àwọn obìnrin nìkan—bóyá nítorí pé wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ nílé ìdáná ju àwọn ọkùnrin lọ.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́