ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 9/22 ojú ìwé 31
  • Àwùjọ Onílé Orí Òpó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwùjọ Onílé Orí Òpó
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ibi Ìlùmọ́ sí Ibi Tí Ń Fa Àwọn Arìnrìn Àjò Afẹ́ Mọ́ra
  • Adágún Victoria—Òkun Ńlá Tí Ilẹ̀ Yí Ká ní Áfíríkà
    Jí!—1998
  • Àwọn Ohun Ṣíṣeyebíye Tó Wà Ní Adágún Títóbi Jù Lọ Ní Amẹ́ríkà Àárín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ká Lọ sí Ọjà Ẹja Tó Tóbi Jù Lọ Lágbàáyé
    Jí!—2004
  • Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Jí!—1996
g96 9/22 ojú ìwé 31

Àwùjọ Onílé Orí Òpó

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Benin

“GANVIÉ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí ń fa àwọn arìnrìn àjò afẹ́ mọ́ra jù lọ ní ilẹ̀ Benin,” èyí ni ohun tí ìwé atọ́nisọ́nà kan sí Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ. Òmíràn sọ pé: “Ganvié máa ń fa àwọn ará Áfíríkà fúnra wọn mọ́ra; ìwọ yóò rí àwọn ará Áfíríkà tí wọ́n jẹ́ arìnrìn àjò afẹ́ lọ́pọ̀ yanturu bí àwọn ti ìhà ìwọ̀ oòrùn ayé.”

Ganvié kò láfiwé ní tòótọ́. Abúlé tí ó ní 15,000 olùgbé, tí a kọ́ sórí òpó lórí omi Adágún Nokoué, àríwá Kútọnu, Benin. Kò sí kẹ̀kẹ́, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀, àti títì ní Ganvié. Bí àwọn olùgbé ibẹ̀ bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́, ọjà, ilé ìwòsàn, ilé aládùúgbò wọn, tàbí ibikíbi mìíràn, ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ tí a fi igi ìrókò gbẹ́ ni wọn yóò wọ̀ lọ.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìdílé ló ní ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ bíi mélòó kan—ọ̀kan fún Bàbá, ọ̀kan fún Ìyá, àti nígbà míràn, ọ̀kan fún àwọn ọmọ. Àwọn ọmọ máa ń tètè kọ́ bí a ṣe ń tu ọkọ̀. Ní ọmọ ọdún márùn-ún, ọmọ kan lè máa dá nìkan gbé ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ kan kiri. Kì yóò pẹ́ tí yóò ti gbóyà tó láti dúró nínú ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀, kí ó sì ju àwọ̀n ìpẹja sódò. Àwọn ọmọdé kan fẹ́ràn láti máa ṣe fọ́ńdá lójú àwọn àlejò nípa fífi orí dúró nínú ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn.

Ní ọjà ojú omi Ganvié, àwọn oníṣòwò, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọ́n jẹ́ obìnrin, máa ń jókòó sínú ọkọ̀ ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn pẹ̀lú ọjà wọn tí wọ́n tò gègèrè síwájú—àwọn ohun afóúnjẹládùn, èso, ẹja, egbòogi, igi ìdáná, ọtí bíà, àti rédíò pàápàá. Pẹ̀lú akẹ̀tẹ̀ fífẹ̀ dáradára tí wọ́n fi ń gba oòrùn ganrínganrín, wọ́n ń tajà fún àwọn mìíràn tí wọ́n tu ọkọ̀ wọn wá síbẹ̀ láti rajà. Nígbà míràn, àwọn ọmọbìnrin kéékèèké ló máa ń jẹ́ òǹtajà náà. Má ṣe jẹ́ kí ọjọ́ orí wọn tàn ọ́ jẹ! Wọ́n tètè máa ń kọ́ ọ̀nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí àwọn òǹtajà máa ń gbà dúnàádúrà.

Bí àwọn obìnrin ti ń rà, tí wọ́n sì ń tà ní ọjà náà, ni àwọn ọkùnrin máa ń dojú kọ ẹja pípa, tàbí ní pàtó, dídọ́sìn ẹja. Wọ́n máa ń pa ẹja nípa dída ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀ka igi sínú odò ẹlẹ́rẹ̀, tí ń jẹ́ kí ibẹ̀ ní ìrísí igbó onígi dídí. Àwọn ẹja yóò rọ́ lọ jẹ àwọn ẹ̀ka igi tí ń jẹrà náà. Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan, àwọn ọkùnrin náà yóò padà lọ pẹ̀lú àwọ̀n wọn láti kó àwọn ẹja náà.

Láti Ibi Ìlùmọ́ sí Ibi Tí Ń Fa Àwọn Arìnrìn Àjò Afẹ́ Mọ́ra

Àwọn Toffinu ní Ganvié kì í ṣe “Ará Orí Omi,” gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wọ́n lónìí láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejìdínlógún, wọ́n sá lọ sí ibi tí adágún omi àti irà wà láti bọ́ lọ́wọ́ inúnibíni láti ilẹ̀ ọba Áfíríkà kan tí ó múlé gbè wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé orúkọ náà Ganvié gbé ìtàn yìí yọ, níwọ̀n bí a ti lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ èdè Toffin náà gan sí “a rí ààbò,” tí ọ̀rọ̀ náà vie sì túmọ̀ sí “ẹgbẹ́ àwùjọ.” Nípa bẹ́ẹ̀, a lè túmọ̀ orúkọ olórí lára àwọn ìlú pàtàkì pàtàkì orí adágún omi yìí ní òwuuru sí “àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n rí àlàáfíà nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín.”

Sísálà sí agbègbè irà àyíká Adágún Nokoué jẹ́ ọgbọ́n ìwéwèé tí ó gbéṣẹ́, níwọ̀n bí àwọn èrò ìgbàgbọ́ ilẹ̀ ọba tí ó gbéjà kò wọ́n kò ti fàyè gba sójà èyíkéyìí láti fẹ̀mí wewu wọnú omi tàbí àwọn àgbègbè tí àkúnya omi ti lè ṣẹlẹ̀. Nítorí náà, adágún náà pèsè àpapọ̀ ọ̀nà ìṣètìlẹ́yìn fún ìgbésí ayé àti ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá. Ó jẹ́ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ pé àwùjọ lílókìkí nísinsìnyí, tí ogunlọ́gọ̀ àwọn arìnrìn àjò afẹ́ ń wọ ọkọ̀ ẹlẹ́ńjìnnì wa wò yìí, jẹ́ ibi ìlùmọ́ tẹ́lẹ̀ rí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́