Ojú ìwé 2
Láti Ọ̀rọ̀ Dídunni sí Ọ̀rọ̀ Atunilára 3-11
Báwo ni èébú ṣe ń ba ipò ìbátan jẹ́ tó? Kí ló dé tí àwọn ènìyàn kan máa ń na ẹni tí wọ́n sọ pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ ní pàṣán ọ̀rọ̀? Kí ni a lè ṣe láti mú èébú kúrò nínú ìgbésí ayé ẹni?
Òtítọ́ Fún Mi Ní Ìwàláàyè Mi Padà 12
Ó ti jẹ́ ajoògùnyó nígbà tí ó ti wà lọ́mọ ọdún 14, ó sì bá ìjoògùnyó àti àìnírètí jìjàkadì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mọ nípa bí òtítọ́ Bíbélì ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.
Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí? 21
Sìgá tí ó ṣètẹ́wọ́gbà, tí wọ́n sì fi ń ṣafẹ́ nígbà kan rí, ti di ohun ìyọṣùtì sí. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a kọ̀ ọ́?