“Iṣẹ́ Ribiribi fún Aráyé”
“Ẹ ti ṣe iṣẹ́ ribiribi fún aráyé nípa títẹ ìwé yìí jáde. Àgbàyanu ni. Àkójọ títayọlọ́lá ni. Ó yẹ ní mímọrírì.
“Ẹwà ìwé náà ni pé ó sọ̀rọ̀ lórí gbogbo onírúurú ẹ̀ka tí ìsìn ní, bí ó sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó lo ìṣọ́ra láti má ṣe àríwísí. Ẹ káre. Ẹ káre láé.”
Ìwé wo ni ọ̀mọ̀wé láti Tiruchchirappalli, Íńdíà, tí ó kọ lẹ́tà yìí ń tọ́ka sí? Ìwé Mankind’s Search for God, olójú ewé 384, tí ó ṣe àkójọ orírun àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀sìn pàtàkì lágbàáyé—ẹ̀sìn Híńdù, Búdà, Tao, Confucian, Shinto, àwọn Júù, Kristẹni, àti Ìsìláàmù. Àwọn orí tí ó kẹ́yìn ṣàlàyé nípa èrò àìgbàgbọ́ lóde òní àti ìyípadà sí Ọlọ́run tòótọ́. A ti tẹ ẹ̀dà ìwé yìí tí ó lé ní mílíọ̀nù 16 jáde ní èdè 37.
Ọ̀mọ̀wé náà ti yá ẹ̀dà kan kà. Ó fẹ́ẹ́ gba ọ̀kan fún ara rẹ̀. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ìwé aláwòrán mèremère yìí fúnra rẹ, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ nínú àwọn tí ó wà ní ojú ìwé 5, ìwé ìròyìn yí.