Ojú ìwé 2
Ìráragbaǹkan—Ayé Ha Ti Tàṣejù Bọ̀ Ọ́ Bí? 3-9
Ìráragbaǹkan béèrè ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kò sì rọrùn láti ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ńṣe la dà bí ẹpọ̀n agogo, tí ń fì láti ẹ̀gbẹ́ kan sí èkejì. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a ń ní ìwọ̀n ìráragbaǹkan kíkéré jù; nígbà míràn, ó ń pọ̀ jù.
Irà Oníkoríko ti Florida—Ìpè Kíkankíkan Láti Inú Igbó 13
Àwọn onímọ̀ nípa àyíká tí ń ṣàníyàn ń ké gbàjarè pé Irà Oníkoríko ń tán lọ. A ha lè dáàbò bo àgbàyanu “odò oníkoríko” yìí bí?
“Nígbà Tí Èmi Bá Jẹ́ Aláìlera, Nígbà Náà Ni Mo Di Alágbára” 23
Nígbà tí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ aláàbọ̀ ara bá ń lo ara wọn tokunratokunra dé góńgó nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” ni wọ́n ń lò.—Kọ́ríńtì Kejì 4:7.