Nígbà Tí Ilẹ̀ Bá Di Aṣálẹ̀
A TI gbọ́ pé ilẹ̀ ti ń di aṣálẹ̀ díẹ̀díẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100, tí ó sì ń nípa lórí àwọn ènìyàn tí ó lé ní 900 mílíọ̀nù, tí ó sì tún ń fa àdánù ọdọọdún tí a fojú bù pé ó jẹ́ bílíọ̀nù 42 dọ́là nínú owó tí ń wọlé lágbàáyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbègbè tí ó tòṣì ni ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ń pa lára jù, (81 lára àwọn orílẹ̀-èdè náà jẹ́ àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà), ó ń wu àwọn orílẹ̀-èdè léwu ní gbogbo àgbáálá ilẹ̀.
Ètò Àbójútó Àyíká ti Àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè (UNEP) pe ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ní “ọ̀kan nínú àwọn ìṣòro àyíká líle koko jù lọ tí àgbáyé dojú kọ.” Nígbà kan náà, àwọn olùṣèwádìí pẹ̀lú sọ pé “aṣálẹ̀ kò gbòòrò sí i.” Báwo ni irú ohun tí ó jọ ìtakora bẹ́ẹ̀ ṣe lè wà?
Aṣálẹ̀ Kò Dúró Sójú Kan, Àwọn Ìtúmọ̀ Ń Yí Pa Dà
Lẹ́yìn ọ̀dá ọlọ́jọ́ pípẹ́ ní ẹkùn ilẹ̀ Sahel ti Áfíríkà (1968 sí 1973), a tẹ èrò nípa aṣálẹ̀ tí ń gba ilẹ̀ oko mọ́ni lọ́wọ́ mọ́ àwọn ènìyàn lọ́kàn. Bí ó ti wù kí ó rí, Donald A. Wilhite, olùdarí Ibùdó Ìsọfúnni Nípa Ọ̀dá Lágbàáyé ní Yunifásítì ti Nebraska (U.S.A.), sọ pé, “àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò onídàágùdẹ̀ àti aṣèparun” tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàpèjúwe nígbà náà ni wọ́n “gbé karí àwọn ìsọfúnni oníṣirò tí kò pọ̀ tó, tí wọ́n kó jọ láàárín ìwọ̀n àkókò kúkúrú, tí kò fúnni ní òye pípéye.”
Àwọn àwòrán sátẹ́láìtì ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ gíga tí ó ṣàwárí biomass (ìwọ̀n ohun alààyè) ń fi hàn pé ìwọ̀n ewéko kì í dúró sójú kan náà ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òjò. Àwọn ògbóǹkangí sọ pé, àwọn ìyàtọ̀síra wọ̀nyí “máa ń fúnni ní èrò pé aṣálẹ̀ ń gbòòrò sí i tàbí ó ń sún kì.” Nítorí náà, àwọn aṣálẹ̀ “kì í dúró sójú kan” àmọ́ kì í ṣe pé wọ́n ṣáà “ń gbòòrò sí i” ṣáá. Ọ̀mọ̀wé Wilhite tẹnu mọ́ ọn pé, àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, “ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ń ṣẹlẹ̀.” Ṣùgbọ́n kí ni èyí túmọ̀ sí gan-an?
Ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀
A sábà máa ń ṣi “ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀” mú fún ìgbòòrò àti ìsúnkì àwọn aṣálẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ jẹ́ ohun ọ̀tọ̀. Nígbà tí ìgbòòrò àti ìsúnkì ń ṣẹlẹ̀ léteetí àwọn aṣálẹ̀ tí ó wà lọ́wọ́lọ́wọ́, ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ tí ó gbẹ jù, tí àwọn kan lára wọn lè wà níbi jíjìnnà púpọ̀ sí aṣálẹ̀ kankan. Àwọn àgbègbè irú ilẹ̀ oko gbígbẹ tí ó gbòòrò bẹ́ẹ̀, tí ó jẹ́ ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ojú ilẹ̀ ayé, ń di aṣálẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ni a ń wò bí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ nísinsìnyí.
Síbẹ̀, láìka ojú ìwòye tí ó túbọ̀ gbòòrò yí nípa ibi tí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ sí, ìdàrúdàpọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì náà ń bá a lọ. Èé ṣe? Panos, ẹgbẹ́ kan tí ń pèsè ìsọfúnni nípa àwọn ọ̀ràn ìdàgbàsókè, tí ó fi London ṣe ibùjókòó, tọ́ka sí ìdí kan. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí ń ṣèpinnu ń tẹnu mọ́ èrò nípa aṣálẹ̀ tí ń gbòòrò sí i, nítorí pé ó jẹ́ “èrò kan tí ó rọrùn láti fi fa èrò sẹ́yìn fún ète ìṣèlú ju ti ‘ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀’ tí ó túbọ̀ díjú lọ.”
Ẹgbẹ́ Panos tọ́ka sí i pé, “èrò tí ń yí pa dà ti fa ìjiyàn rẹpẹtẹ lórí ohun tí ‘ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀’ jẹ́ ní gidi.” Kí ni kókó ọ̀ràn náà? Ẹ̀dá ènìyàn tàbí ipò ojú ọjọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, àjọ UN dábàá láti túmọ̀ ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ sí “bíba ilẹ̀ jẹ́ ní àwọn àgbègbè gbígbẹ koránkorán, gbígbẹ níwọ̀nba díẹ̀ àti èyí tí ó lọ́rinrin níwọ̀nba díẹ̀, tí ó jẹ́ àbájáde ipa búburú ti ẹ̀dá ènìyàn.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Camilla Toulmin, olùdarí Ìdáwọ́lé Àwọn Ilẹ̀ Gbígbẹ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àgbáyé fún Àyíká òun Ìdàgbàsókè, sọ pé, ìtúmọ̀ yí kò tẹ́ ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn, nítorí pé ó ń di ẹrù ẹ̀bi ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ru ènìyàn. Nípa bẹ́ẹ̀, láìpẹ́ yìí, wọ́n yí apá tó kẹ́yìn nínú ìtúmọ̀ náà sí “tí ó jẹ́ àbájáde ìyàtọ̀ nínú ipò ojú ọjọ́ àti ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ìtúmọ̀ tuntun yìí di ẹ̀bi ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ru ẹ̀dá ènìyàn àti ipò ojú ọjọ́ lápapọ̀, ṣùgbọ́n kò fòpin sí ìjiyàn náà. Èé ṣe tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?
Ẹgbẹ́ Panos sọ pé: “Àwọn ògbóǹkangí kan gbà gbọ́ pé àwọn ìtúmọ̀ tí ń di rẹpẹtẹ àti àríyànjiyàn tí ń tibẹ̀ jẹ yọ jẹ́ ìgbìyànjú kan ní ti gidi, láti rí àfikún owó ìrànwọ́ gbà fún ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí a kà sí pé wọ́n wà nínú ewu.” Àbájáde àríyànjiyàn tí ń bá a lọ náà ni pé “èdè ọ̀rọ̀ náà fúnra rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di aláìnítumọ̀ mọ́.” Àwọn ènìyàn kan tilẹ̀ rò pé ńṣe ló yẹ kí a pa èdè ọ̀rọ̀ náà, “ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀,” tì pátápátá. Síbẹ̀, ó dájú pé fífi ọ̀rọ̀ míràn dípò ọ̀rọ̀ náà kò níí tán ìṣòro náà, tàbí kí ó fòpin sí àwọn okùnfà rẹ̀. Àwọn ohun wo ní ń fa ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀?
Àwọn Lájorí Okùnfà àti Ìyọrísí
Ìwé náà, Desertification, láti ọwọ́ Alan Grainger, wí pé, àwọn lájorí okùnfà náà ni rírolẹ̀lárojù, fífẹranjẹkojù, pípagbórun, àti àwọn àṣà bíbomirinlẹ̀ tí kò dára tó. Nígbà tí méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú àwọn okùnfà wọ̀nyí bá ṣẹlẹ̀ pọ̀, ó sábà máa ń yọrí sí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀. Síwájú sí i, àwọn kókó tí ń dá kún un—bí ìyípadà nínú iye ènìyàn, ipò ojú ọjọ́, àti àwọn ipò ètò ọrọ̀ ajé àti àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà—ń mú kí ìṣòro náà túbọ̀ burú sí i.
Àbájáde híhàn gbangba kan, tí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ń fà, ni bíba agbára tí ilẹ̀ gbígbẹ ní láti pèsè oúnjẹ jẹ́. Ó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé, ṣùgbọ́n ní pàtàkì, ní Áfíríkà, níbi tí ìpín 66 nínú ọgọ́rùn-ún àgbáálá ilẹ̀ náà ti jẹ́ aṣálẹ̀ tàbí ilẹ̀ gbígbẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ní àwọn àbájáde bíbanilọ́kànjẹ́. Ó ń yọrí sí ogun. Ìwé náà, Greenwar—Environment and Conflict, sọ pé: “Bíbàyíkájẹ́ ń kó ipa tí ń pọ̀ sí i nínú àhunmọ́ra lílọ́júpọ̀ àwọn okùnfà tí ń yọrí sí àìdúró-déédéé àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn àti ìṣèlú, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ogun.”
Kódà, àwọn ìsapá láti dènà ogun ń pa àyíká lára, ó sì ń mú kí ipò òṣì burú sí i. Báwo? Ẹgbẹ́ Panos ṣàlàyé pé: “Nígbà tí àwọn ìjọba bá ń kojú àìdúró-déédéé ìṣèlú, tí ìjàkadì lórí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tí ń lọ sílẹ̀ nítorí bíba ilẹ̀ jẹ́ ń fà, wọ́n sábà máa ń hùwà padà ní ọ̀nà ti ológun láti ṣẹ́pá ìwà ipá náà. Lọ́nà yí, àwọn ìjọba máa ń darí owó tó wà lọ́wọ́ sórí ìwéwèé ìnáwó ológun, dípò kí wọ́n darí rẹ̀ sórí dídín ipò òṣì kù.” Bí ó ti wù kí ó rí, dípò gbígbógun ti àwọn ìyọrísí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀, kí ni a lè ṣe láti gbógun tí àwọn okùnfà rẹ̀?
Kò Sí Ojútùú Ojú Ẹsẹ̀
Lẹ́yìn tí àwọn aṣojú láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 100 ti sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí ìbéèrè yẹn fún oṣù 13, wọ́n fọwọ́ sí “Àdéhùn Àjọ UN Láti Gbógun Ti Ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀,” ìwéwèé kan tí àjọ UN sọ pé, ó jẹ́ “ìgbésẹ̀ ìtẹ̀síwájú pípọndandan kan” ní gbígbógun ti ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀. Láàárín àwọn ohun mìíràn, àdéhùn náà gbà pé ó pọndandan pé kí a máa kó ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ agbógun-tìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ lọ láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, kí a máa dá àwọn ètò ìwádìí àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀, àti ní pàtàkì, kí a máa lo ìmọ̀ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ lọ́nà dídára jù. (UN Chronicle) Àdéhùn tuntun yìí yóò ha dá bíba ilẹ̀ gbígbẹ jẹ́ dúró bí?
Ẹgbẹ́ Panos sọ pé, a nílò ọ̀rọ̀ ẹnu pa pọ̀ mọ́ ìtìlẹ́yìn gidi, kí a lè ṣàṣeyọrí. Hama Arba Diallo, ọ̀kan lára àwọn olùṣètò àdéhùn náà, ròyìn pé láàárín 1977 sí 1988, wọ́n ná nǹkan bíi bílíọ̀nù kan dọ́là sórí àwọn ìgbésẹ̀ ìgbógun-tìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ lọ́dọọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí UNEP ṣe wí, àwọn orílẹ̀-èdè 81 tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà náà ní láti ná nǹkan bí ìlọ́po mẹ́rin sí mẹ́jọ iye yẹn, kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú ní ti gidi.
Ṣùgbọ́n ta ni yóò gbé ẹrù ìnáwó náà? Ẹgbẹ́ Panos kìlọ̀ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè oníléeṣẹ́ ẹ̀rọ kò níí mú owó wá fún iṣẹ́ ìgbógun-tìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ ju èyí tí wọ́n ti ń mú wá lọ,” ní ṣíṣàfikún pé, “kò bọ́gbọ́n mu fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí ń jìyà lọ́wọ́ ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀, láti máa retí pé kí àdéhùn náà mú ọ̀nà àjàbọ́ rírọrùn tàbí yíyá kánkán wá.” Ẹgbẹ́ Panos parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìfojúsọ́nà rere pé, síbẹ̀síbẹ̀, jíjíròrò tí a ń jíròrò ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ kárí ayé nísinsìnyí ń fi kún ìwọ̀n ìmọ̀ ará ìlú nípa ìṣòro náà, “èyí tí ó jẹ́ àṣeyọrí kan fúnra rẹ̀.”
‘Aginjù Yóò Yọ̀’
Láìṣe àní-àní, láàárín àwọn ẹ̀wádún tí ó kọjá, ọ̀pọ̀ ọkùnrin àti obìnrin nínú aráyé ti túbọ̀ mọ̀ nípa àjálù tí ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ tí ń bá a lọ lè mú wá. Àwọn ọ̀rọ̀ apàfíyèsí bíi “Kí ènìyàn tóó wà ni igbó ti ń bẹ, àmọ́ aṣálẹ̀ ni àbájáde wíwà ènìyàn,” ń pe àwọn ènìyàn níjà láti yí ìtòtẹ̀léra yẹn pa dà.
Síbẹ̀, àwọn olóye ènìyàn mọ̀ pé ìṣòro ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ díjú. Wọn kò jẹ́ tan ara wọn jẹ tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi jẹ́wọ́ pé, bí ó ti wù kí ènìyàn ní èrò rere tó, ó ní ibi tí agbára rẹ̀ mọ bí ọ̀ràn bá kan kíkojú àwọn okùnfà àwọn ìṣòro kárí ayé òde òní.
Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà kan náà, ó ń mú àwọn ènìyàn tí ń ṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la pílánẹ́ẹ̀tì wa lọ́kàn yọ̀ láti mọ̀ pé Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé ti ṣèlérí láti kojú èyí àti àwọn ìṣòro àyíká mìíràn lọ́nà gbígbéṣẹ́. Níwọ̀n bí àwọn ìlérí Ọlọ́run, tí a kọ sínú Bíbélì sì ti sábà máa ń ṣẹ, kì í ṣe ẹ̀tàn láti máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ ohun tí Jèhófà mí sí wòlíì Aísáyà láti kọ sílẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la àwọn aṣálẹ̀ àti ilẹ̀ tí a ti bà jẹ́ pé: “Aginjù àti ilẹ̀ gbígbẹ yóò yọ̀ . . . ; ijù yóò yọ̀, yóò sì tanná bíi lílì. . . . Nítorí omi yóò tú jáde ní aginjù, àti ìṣàn omi ní ijù. Ilẹ̀ yíyan yóò sì di àbàtà, àti ilẹ̀ òùngbẹ yóò sì di ìsun omi.” (Aísáyà 35:1-7; 42:8, 9; 46:8-10) Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun ìdùnnú tó láti rí i pé a dá ìgbésẹ̀ ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ dúró, tí a sì yí i pa dà lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 16]
Ìpín Nínú Ọgọ́rùn-ún Ilẹ̀ Tí Ó Jẹ́ Aṣálẹ̀ Tàbí Ilẹ̀ Gbígbẹ
Áfíríkà 66%
Éṣíà 46%
Australia 75%
Europe 32%
Àríwá America 34%
Gúúsù America 31%
Àgbáyé 41%
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìbomirinlẹ̀ Ha Ń Sọ Ilẹ̀ Di Aṣálẹ̀ Bí?
Ǹjẹ́ ìbomirinlẹ̀ lè sọ ilẹ̀ di aṣálẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ìbomirinlẹ̀ tí ó lábùkù ń ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ tí a bomi rin kò bá jo omi dà nù dáradára. Lákọ̀ọ́kọ́, ilẹ̀ náà ń gbomi dúró; lẹ́yìn náà, ó ń di oníyọ̀; àti nígbẹ̀yìn, ekuru oníyọ̀ ń kóra jọ lójú ilẹ̀ náà. Ẹgbẹ́ Panos sọ pé: “Ìbomirinlẹ̀ tí ó lábùkù ń sọ ilẹ̀ di aṣálẹ̀ ní kánmọ́kánmọ́ tí ọ̀nà ìbomirinlẹ̀ tuntun bá ti yọjú.”
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
AṢÁLẸ̀
NÍNÚ EWU
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ilẹ̀ oko ń di aṣálẹ̀ díẹ̀díẹ̀