ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/8 ojú ìwé 32
  • Kí Ni O Mọ̀ Nípa Jésù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni O Mọ̀ Nípa Jésù?
  • Jí!—1997
Jí!—1997
g97 2/8 ojú ìwé 32

Kí Ni O Mọ̀ Nípa Jésù?

Obìnrin ẹni ọdún 84 kan tí ń gbé United States sọ nípa ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí, ìwé olójú ewé 448, tí ó kún fún àwòrán alápèjúwe nípa ìgbésí ayé Jésù Kristi, pé: “Mo ti ka ìwé náà tán nígbà bíi mélòó kan, ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ náà sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì kíkà mi dáradára.” Ìwé náà mú kí àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìgbésí ayé Jésù gbádùn mọ́ ọn.

Ó kọ̀wé pé: “Kíka ìwé náà kò sú mi rí. Mo ti kà á nígbà méje, mo sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á lẹ́ẹ̀kan sí i. Àwọn ànímọ́ àgbàyanu tí Jésù ní ru ìmọ̀lára ọkàn mi sókè. Nígbà tí mo ka àwọn àkórí tí ń sọ nípa ọ̀sẹ̀ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀nà tí kò dára tí wọ́n gbà bá a lò dùn mí, ní pàtàkì ní àwọn wákàtí tí ó lò gbẹ̀yìn, àti ikú rẹ̀ lórí igi oró. Síbẹ̀, ó fògo fún Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà.”

A sapá láti ṣàgbékalẹ̀ gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nínú ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé sínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Jésù. Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni lórí bí o ṣe lè gba ẹ̀dà kan tàbí tí o bá fẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́