Ojú ìwé 2
Ìrànwọ́ fún Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Ní Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́ 3-10
Kí ni àwọn ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́ tó wọ́pọ̀? Kí ló ń fa Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Àìlèpọkànpọ̀? Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe lè kápá rẹ̀?
Ohun Tí Ó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Irọ́ Pípa 17
Lọ́nà kan náà tí àgé òdòdó kan lè gbà fọ́ yángá bí o bá là á mọ́lẹ̀ ni ìbátan oníyebíye kan lè gbà rún jégé nítorí irọ́ pípa. Kí ni òtítọ́ tí a gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa irọ́ pípa?
A Ṣe Àwọn Àpéjọpọ̀ Romania Láìka Àtakò Sí 24
Romania kọ́kọ́ fi àṣẹ láti ṣe àwọn àpéjọpọ̀ du Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èé ṣe? Èé sì ti ṣe tí a fi fún wọn láṣẹ lẹ́yìn náà?