Ìtùnú fún Tẹbítọ̀rẹ́
NÍGBÀ tí ọkọ̀ òfuurufú TWA 800 já bọ́ sínú Òkun Ńlá Àtìláńtíìkì ní July 17 tó kọjá, gbogbo 230 ènìyàn tó wà nínú rẹ̀ ṣègbé. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 16, tí ń kọ́ èdè Faransé nílé ẹ̀kọ́ gíga, àti àwọn àgbàlagbà márùn-ún tí ń bójú tó wọn, láti Montoursville, ìlú kékeré kan tí ó ní nǹkan bí 5,000 olùgbé ní Pennsylvania, wà lára wọn. Níbi ààtò ìrántí ìsìnkú kan tí ìlú ṣe ní August 17, ọ̀kan lára àwọn asọ̀rọ̀ náà, Rudolph Giuliani, olórí ìlú New York City, sọ pé, bí ó bá jẹ́ pé iye ìpín kan náà nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé ìlú New York City ni ó kú, 35,000 ènìyàn ni ì bá ti kú yẹn!
Wọ́n ké sí ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga náà, Dan Chandler, láti sọ̀rọ̀ níbi ètò ìsìnkú àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó ṣàyọlò ìlérí inú Bíbélì ní Ìṣípayá 21:4, tí ó sọ pé, nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tuntun ti Ọlọ́run, “ikú kì yóò . . . sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” Lórí ìdí tí irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀ fi ń ṣẹlẹ̀, ó tọ́ka sí Oníwàásù 9:11, tí ó sọ pé “ìgbà àti èṣe” ń ṣe sí gbogbo wa. Ó ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu láti gbọ́ tí ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ gíga wọn ń fúnni ní irú àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú bẹ́ẹ̀.
Kí Chandler lè ṣèrànwọ́ síwájú sí i, ó gbé tábìlì kan kalẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga náà, níbi tí àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé pẹlẹbẹ olójú ìwé 32 náà, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti ìwé ìléwọ́ náà, Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú?, gbé wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Àwọn ènìyàn gba ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọ̀pọ̀ sì dúpẹ́ fún ìtùnú tí ìwọ̀nyí pèsè.
Ìwọ pẹ̀lú lè rí ìtùnú tí o nílò láti inú ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìléwọ́ tí a mẹ́nu bà lókè yìí. Bí o bá fẹ́ láti gba ìsọfunni lórí bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan wọn gbà, tàbí tí o bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé lọ́fẹ̀ẹ́, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú nínú àwọn tí ó wà lójú ìwé 5.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Pẹ̀lú ìyọ̀ǹda onínúure Williamsport Sun-Gazette
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Corey Sipkin/Sipa Press