Alẹ́ Tí Ó Yẹ Kí A Rántí
SUNDAY, MARCH 23, 1997
NÍ ALẸ́ ỌJỌ́ tí ó ṣáájú ikú rẹ̀, Jésù Kristi dá Ìṣe Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Níbi oúnjẹ rírọrùn kan nínú èyí tí ó ti lo wáìnì àti àkàrà aláìwú bí ohun ìṣàpẹẹrẹ, Jésù pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ké sí ọ tọ̀yàyàtọ̀yàyà láti ṣàjọpín pẹ̀lú wọn ní ṣíṣe Ìṣe Ìrántí ọlọ́dọọdún yìí. Lọ́dún yìí, a óò ṣe é lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ ní Sunday, March 23, déètì tí ó bára dọ́gbà pẹ̀lú Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àfòṣùpákà Bíbélì. Jọ̀wọ́ wádìí lọ́dọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa àkókò pàtó àti ibi tí a óò ti ṣe é ládùúgbò rẹ.