Ojú ìwé 2
Igbó Kìjikìji Amazon Àwọn Àròsọ àti Ìṣẹ̀lẹ̀ Gidi 3-13
Àwọn tí ń la ọ̀nà, àwọn agégẹdú, àwọn awakùsà, àwọn àgbẹ̀ ọlọ́sìn ẹran, àti àwọn àgbẹ̀ aládàá ńlá ń pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ilẹ̀ igbó kìjikìji Amazon run lọ́dọọdún. Ìfojúdíwọ̀n ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára igbó náà ni ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti pa run ná. Bíbá a lọ láti máa pa á run yóò ní àbájáde búburú jákèjádò ayé.
A Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láre ní Gíríìsì 14
Ìsìn tí ó gbé ìlànà ìwà rere ró, tí ó sì fìdí múlẹ̀ ṣinṣin ni ìsìn wọn, àwọn mẹ́ńbà wọn sì ti dá kún ìdùnnú tí ń wà ní àwọn àdúgbò tí wọ́n ń gbé.
Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀? 17
Bí o bá ní ìtẹ̀sí láti máa bú mọ́ni, rántí pé Ọlọ́run pa àwọn abúmọ́ni ìgbàanì, tí a mọ̀ sí “Néfílímù,” run!—Jẹ́nẹ́sísì 6:4-7.