ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 3/22 ojú ìwé 24-27
  • Àkókò Ìrọ́gììrì Níbi Ìrugùdù Òkun Gíga

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àkókò Ìrọ́gììrì Níbi Ìrugùdù Òkun Gíga
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjẹ́pàtàkì Àwọn Ẹnu Odò
  • Ìrugùdù Ìgbà Ìrúwé
  • Ìrugùdù Tí Ń Ga Sókè Sí I Náà
  • Ìrọ́gììrì Náà Bẹ̀rẹ̀
  • Bíbà Náà
  • Ǹjẹ́ O Ti Ríbi Tí Ẹja Ti Ń Rìn Rí?
    Jí!—1999
  • Wíwo Ẹyẹ—Ìgbòkègbodò Àfipawọ́ Tí Gbogbo Ènìyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí Ni Bí?
    Jí!—1998
  • Bí Ẹja Grunion Ṣe Ń Yé Ẹyin
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Jí!—1997
g97 3/22 ojú ìwé 24-27

Àkókò Ìrọ́gììrì Níbi Ìrugùdù Òkun Gíga

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní ilẹ̀ Britain

NǸKAN bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọ̀kẹ́ ẹyẹ ń lo ìgbà òtútù ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn Europe lọ́dọọdún. Ibi ìpamọ ilẹ̀ olótùútù nini nìkan kọ́ ni wọ́n ti ń wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń wá láti àwọn ibi jíjìnnà réré tó Kánádà àti àárín gbùngbùn Siberia. Nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí Áfíríkà, ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ń kóra jọ pọ̀ ní Ojú Ọ̀nà Ìgbà Gbogbo ti Ìlà Oòrùn Àtìláńtíìkì, ojú ọ̀nà ìṣíkiri kan tí ó la Àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Britain já.

Ọ̀wọ́ ẹnu odò ńláńlá tí ó lé ní 30 ń pèsè oúnjẹ ati ibùdó ìsinmi nínú òkun ilẹ̀ Britain. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń pèsè fún àwọn ẹyẹ tí ó lé ní 20,000, ṣùgbọ́n èyí tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni ti The Wash, tí ó wà ní etíkun ìlà oòrùn England, tí ń gbàlejò àwọn ẹyẹ tí ó lé ní ìlàrin mílíọ̀nù—tí ó ní àwọn ẹyẹ curlew, dunlin, godwit, knot, oystercatcher, plover, redshank, àti turnstone nínú. Irú oúnjẹ wo ni àwọn ẹnu odò ń pèsè, èé ṣe tí wọ́n sì fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?

Ìjẹ́pàtàkì Àwọn Ẹnu Odò

Àwọn ẹnu odò jẹ́ àwọn àgbègbè etíkun níbi tí omi òkun ti dà pọ̀ mọ́ omi aláìníyọ̀. Níhìn-ín, àwọn omi lílọ́ wọ́ọ́rọ́ náà, tí ó ní àwọn èròjà aṣaralóore kòṣẹ̀fọ́-kòṣẹran àti àwọn ti ìṣẹ̀fọ́-ìṣẹran nínú ń gbé ìwàláàyè ìlàjì àwọn ohun alààyè inú agbami òkun àgbáyé ró. A ń rí àwọn edé, kòkòrò sand hopper, àti àwọn ohun alààyè míràn nínú iyanrìn, ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àwọn ẹnu odò ń gbé ìwàláàyè ọ̀pọ̀ yanturu ohun alààyè púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ ró.

Ẹrẹ̀ máa ń yàtọ̀ síra ní ìbámu pẹ̀lú bí àwọn gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ tí ó mú un jáde ṣe tóbi tó. Oríṣi ẹrẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àrà ọ̀tọ̀ ẹran omi tirẹ̀, tí ó jẹ́ oúnjẹ tí àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò máa ń jẹ.a Bí àpẹẹrẹ, oríṣi ẹrẹ̀ kan tí ó fẹ̀ ní mítà kan níbùú lóròó lè ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹran abìkarawun, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan kò gùn tó mìlímítà mẹ́ta nínú! Láfikún, àwọn ẹran oníkarawun, ekòló lugworm, àti ekòló rag worm, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá aláìléegun ẹ̀yìn míràn máa ń dàgbà nínú ẹrẹ̀.

Ìrugùdù Ìgbà Ìrúwé

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹyẹ tí ń wọ́dò lè wà ní ẹnu odò kan, ó lè ṣòro láti rí wọn, nítorí pé, ńṣe ni wọ́n máa ń tú ká sí àgbègbè gbígbòòrò. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ìrugùdù ìgbà ìrúwé bá dé, ipò náà ń yí pa dà lọ́nà pípàfiyèsí. Ìrọ́gììrì omi gíga máa ń mú kí àwọn ibi títẹ́jú iyanrìn àti ẹrẹ̀ kún ya, ó sì ń fipá lé àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò sí ibi ilẹ̀ tí omi ń ru bò déédéé àti àwọn ibi tí ó tún ga jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń túbọ̀ rọrùn láti kíyè sí wọn bí wọ́n ti ń kóra jọ, tí wọ́n ń wọ̀ lágbolágbo ńláńlá aládàlú.

Lónìí, òwúrọ̀ ọjọ́ olóòrùn tí kò ní kùrukùru nínú oṣù April, ó yẹ kí ìrugùdù ìgbà ìrúwé kan wáyé. Ẹ̀fúùfù títutù nini láti ìhà àríwá ìlà oòrùn ń fẹ́, bí a ṣe ń wakọ̀ lọ sí ẹnu odò kékeré kan, tí ó dára lójú, níbi ìlọ́kọ́lọkọ̀lọ odò Alde gba ìhà àrọko Suffolk ti England lọ sínú Òkun Àríwá. Níhìn-ín ni àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò ti ń pọ̀ tó iye tí ó lé díẹ̀ ní 11,000, yóò sì rọrùn púpọ̀ fún wa láti kíyè sí àwọn ìgbòkègbodò wọn, níwọ̀n bí ẹnu odò náà ti fẹ̀ mọ níwọn 800 mítà.

Àfọ́kù odi tí a fi sé òkun mọ́ wà ní ipa odò náà. Esùsú bo àwọn etídò kan nígbà tí koríko marram bo àwọn mìíràn. Àwọn igi gẹdú dúdú àti àwọn òkúta ló wà ní àwọn ibi yòó kù. Gẹ́lẹ́ lókè odò, láàárín àgbájọ àwọn ilé ìgbà ìṣàkóso Victoria, ni Gbọ̀ngàn Ìṣeré Snape Maltings, orírun àjọ̀dún orin ìlú Aldeburgh. Ṣùgbọ́n a ní láti rìn lọ síhà ìsàlẹ̀ odò, kí a sì gba ibi fífara sin kan lọ. Ẹ̀fúùfù náà lágbára nísinsìnyí, ojú yóò sì máa gún wa láìpẹ́.

Kété tí a dé etídò náà (wo àwòrán, ojúkò A), igbe olóhùn orin jíjá geere ti àwọn ẹyẹ avocet méjì, tí ń dún ketekete, ló ki wa káàbọ̀. Wọn kò jìnnà sí wa ju nǹkan bí 40 mítà lọ, ní ìhà kan náà tí a wà sí ẹnu odò náà, tí wọ́n ń bá ara wọn fi àgógó túnra ṣe ní takọtabo lọ́wọ́. Ẹyẹ kọ̀ọ̀kan rọra ń fi ṣóńṣó àgógó rẹ tín-ínrín tí ó tẹ̀ sókè ṣá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ apá òkè àyà rẹ̀. Ìran yìí dùn láti wò, ṣùgbọ́n a ní láti tẹ̀ síwájú, níwọ̀n bí a ti ní ohun púpọ̀ sí i láti wò.

Ìrugùdù Tí Ń Ga Sókè Sí I Náà

Ní báyìí, ìrugùdù náà ń yára ga, nítorí náà, a tètè kọjá síbi ìwòran tí a yàn. (Wo àwòrán, ojúkò B.) Lọ́nà, ẹyẹ redshank kan—tí ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alóre ẹnu odò náà—gbéra sọ láti ibi ilẹ̀ tí omi ń ru bò déédéé náà, ó sì ń kígbe ìdágìrì rẹ̀, “túùhùhù-túùhùhù!” Àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ pupa hàn yàtọ̀ sí eteetí ìyẹ́ rẹ̀ tí ó funfun báláú tí ń kọná yẹ̀rì nínú ìmọ́lẹ̀ oòrùn náà. Bí a ṣe dé ibi tí a ń lọ, a yára wojú ilẹ̀ iyanrìn àti ẹrẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ tí ń rì náà.

Lọ́ọ̀ọ́kán, àwùjọ àwọn ẹyẹ redshank kan ń jẹun lọ ní tiwọn, wọ́n rọra ń tan ẹrẹ̀ náà, nígbà tí àwọn mìíràn ń wá oúnjẹ ní àwọn ibi tí ó túbọ̀ fara sin. Àwọn ẹyẹ dunlin, pẹ̀lú àwọn àgógó wọn títẹ̀ kọrọdọ sísàlẹ̀ tí a fi ń dá wọn mọ̀, sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí sí i, ní àwọn àwùjọ kéékèèké. Nínú ìlà tí kò gún, wọ́n ń kánjú ṣa oúnjẹ inú ẹrẹ̀ náà jẹ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ, wọ́n sì ní ìtẹ̀sí láti má lọ jìnnà sí etí omi. Àwọn ẹyẹ curlew tí wọ́n tú káàkiri ń rin gbẹ̀rẹ́, wọ́n rọra ń tan ilẹ̀ rírọ̀, tí ń yọ̀ náà, wò. Níwájú lókè odò náà, àwọn ẹyẹ turnstone mélòó kan ń fi àgógó wọn kúkúrú, tí ó rọra tẹ̀ sókè díẹ̀, tan àwọn pàǹtírí etíkun náà, bí wọ́n ṣe ń wá oúnjẹ.

Lójijì, ìró ìfé rírinlẹ̀ onísílébù mẹ́ta “tlee-oo-ee,” ti ẹyẹ plover aláwọ̀ eérú gba afẹ́fẹ́ kan. Bí ẹyẹ náà ṣe ń fò lọ lókè, ìyẹ́ abẹ́ apá rẹ̀ tó dúdú hàn ketekete yàtọ̀ sí ìyókù ìyẹ́ abẹ́ rẹ̀ ṣíṣì. Nǹkan bí 400 ẹyẹ plover aláwọ̀ wúrà, tí wọ́n sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí ní ìrísí ẹyin, ń sinmi pẹ̀lú orí wọn tí wọ́n kì sábẹ́ ìyẹ́ apá wọn, tí gbogbo wọn sì dojú kọ ẹ̀fúùfù náà. Awuyewuye ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láàárín àwọn mélòó kan bí wọ́n ṣe ń fìdí ètò ìfàgbàrẹ́nijẹ láàárín àwùjọ wọn múlẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ṣì wà nínú ìyẹ́ alámì tóótòòtó tí wọ́n ń ní nígbà òtútù—tí wọ́n ní àwọ̀ wúrà àti dúdú níhà òkè; tí àwọ̀ ẹyinjú, iwájú, àti ìhà ìsàlẹ̀ wọn ṣì; tí àgógó wọn sì dúdú. Bí a ṣe ń yí awò awọ̀nàjíjìn wa síhìn-ín sọ́hùn-ún, a rí àwọn ẹyẹ plover alámì róbótó pẹ̀lú.

Agbo nǹkan bí 1,000 ẹyẹ lapwing tí wọ́n ṣe gátagàta dé lójijì. Àwọn ẹyẹ náà yọ bíi pé wọn kò ní ìṣọ̀kan àti ìbáwí, tí wọ́n ń fò ká òfuurufú lọ́nà tí kò ṣeé fara wé. Àwọn ẹyẹ lapwing àti ẹyẹ plover aláwọ̀ wúrà ti lọ sí ilẹ̀ adárafọ́gbìn ti ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbègbè ìjẹ tí wọ́n yàn láàyò jù. Kì í ṣe kìkì láti jẹun ni wọ́n ṣe wá sí ẹnu odò náà, bí kò ṣe láti wẹ̀, kí wọ́n sì baralẹ̀ ṣàtúntò àwọn ìyẹ́ wọn.

Àwọn ariwo tí ń wá láti ọwọ́ ẹ̀yìn jẹ́ igbe àwọn ẹyẹ curlew, ìfé olóhùn orin bí ẹni tí ara rọ̀, ti àwọn ẹyẹ redshank, àti igbe àwọn ẹyẹ àkẹ̀ olórí dúdú. Àwọn ẹyẹ godwit atẹ́rẹrẹnírù méjì walẹ̀ jìn nínú ẹrẹ̀ náà. Àwọn ẹyẹ oystercatcher mélòó kan ń fi àgógó wọn nínípọn tí ó pọ́n bí omi ọsàn fa àwọn ekòló lugworm jáde. Ẹyẹ plover aláwọ̀ eérú kan tí ń dá jẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ ọlọ́lá ńlá mélòó kan, ó dúró, ó mi ẹsẹ̀ ọ̀tún, ó wá lọ lé ẹran ìjẹ rẹ̀ mú, ó sì gbé e mì. Àmọ́ ìrugùdù tí ń bọ̀ náà yára fẹ́ ká gbogbo wọn mọ́!

Ìrọ́gììrì Náà Bẹ̀rẹ̀

Lójijì, àwọn ẹyẹ náà gbéra láti kóra jọ lágbolágbo, ní irú ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ wọn. Ìran wíwọnilọ́kàn kan ni, nítorí àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò náà ń fò ní ìrísí tí ó há gádígádí kan. Bí wọ́n ṣe ń yọ láti ẹ̀gbẹ́ kan sí òmíràn, àwọn agbo náà ń pa àwọ̀ dà bí ìtànṣán oòrùn ṣe ń ta sí wọn lára—láti àwọ̀ ilẹ̀ kíki sí àwọ̀ fàdákà funfun tí ń kọ mànà—wọ́n ń hàn kedere ní àkókò kan, tí wọ́n sì ń fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ìrugùdù ẹlẹ́rẹ̀ tí ń bọ̀ náà mu ní àkókò míràn. Láti orí dídúdú mirin sí orí àwọ̀ fàdákà, láti orí àwọ̀ fàdákà sí orí dídúdú mirin, tí ń ṣe déédéé, àti nígbà kan náà, tí wọ́n ń pa ìrísí dà—láti ìrísí bí ẹyin sí ìrísí róbótó, lẹ́yìn náà sí ìrísí lílọ́ kọ́lọkọ̀lọ, àti níkẹyìn, sí ìrísí ìlà gbọn-ọnran lóòró. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń balẹ̀ sórí ìtẹ́jú ẹrẹ̀ pẹrẹsẹ tí ìrugùdù náà kò ì bò.

Láìpẹ́, ìtẹ́jú ẹrẹ̀ àti iyanrìn pẹrẹsẹ tí ó yí wa ká yóò kún ya, nítorí náà, a yára gòkè odò, àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò kan sì tẹ̀ lé wa pẹ̀lú. Àwọn tí ó kọ́kọ́ yà wá sílẹ̀ ni agbo àwọn ẹyẹ dunlin tíntìntín, tí ń yára lu apá, tí wọ́n sì ń súfèé híhantí tí kì í gùn, kí wọ́n má baà fi ara wọn sílẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn ẹyẹ redshank tí ó túbọ̀ tóbi sí i kọjá, tí agbo wọn kò ṣù pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọ́n sì ń fọlá yan. Àwọn ẹyẹ curlew títóbi bí ẹyẹ àkẹ̀ fò kọjá, wọ́n ń dún ìdún onípààrọ̀ ohùn dídùn méjì, tí ń gbádùn mọ́ni, bí wọ́n ṣe ń lọ. Àwọn ẹyẹ avocet tẹ̀ lé wọn nínú agbo ńlá kan, tí wọ́n ń fi ìyàtọ̀ àwọ̀ dúdú òun funfun hàn ní ìfiwéra pẹ̀lú òfuurufú aláwọ̀ búlúù. Wọ́n bà sí òkè ẹnu odò náà, ẹsẹ̀ wọn gígùn, aláwọ̀ búlúù hàn díẹ̀ lórí omi.

Bíbà Náà

A yára tẹsẹ̀ mọ́rìn kí a lè dé ibi tó ga díẹ̀ níbi tí ẹnu odò náà gbé fún. (Wo àwòrán, ojúkò D.) Ó jọ pé àwọn irú ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan wọ́ pa pọ̀ sójú kan bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Bí ìrugùdù náà ṣe ń ga sí i láìjáfara, àwọn ẹyẹ púpọ̀ sí i ń dara pọ̀ mọ́ agbo náà. Èyí ń fa àtúntò àṣetúnṣe bí ó ṣe túbọ̀ ń ṣòro sí i láti rí àyè ìdúrósí ní etídò náà, tí àwọn apẹ́lẹ́yìn náà sì ń wá àyè tiwọn.

Ìrugùdù gíga náà ti dé báyìí. Àwọn ẹyẹ lapwing àti àwọn ẹyẹ plover aláwọ̀ wúrà ti fò pa dà sí ilẹ̀ dídárafọ́gbìn. A ti fipá mú gbogbo àwọn ẹyẹ tó kù láti kúrò lórí ẹrẹ̀ náà, kí wọ́n sì lọ bà sí eteetí ògbólógbòó odò náà. Ìró onífèrè àwọn ẹyẹ oystercatcher wulẹ̀ ń tú jáde bí iye wọn ṣe pọ̀ tó ni. Àwọn ẹyẹ redshank àti curlew ń dá kún ariwo tí kò dẹwọ́ tí ń wá láti ọwọ́ ẹ̀yìn náà, èyí tí ohùn ẹyẹ skylark kan tí ń kọrin lókè wá bò mọ́lẹ̀ nísinsìnyí—àyíká àgbàyanu kan ní ti gidi.

A gbéra kúrò níbẹ̀ bí àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò náà ṣe ń jẹ̀gbádùn àkókò bíbà wọn ọ̀sán bí ó ṣe yẹ, tí wọ́n fà sẹ́yìn fún ìrugùdù gíga ti ìgbà ìrúwé náà. Láìka ti pé àwọn kan wà lẹ́yìn ògiri ìsékun, tí wọn kò sì lè rí omi náà sí, àwọn ẹyẹ náà yóò mọ ìgbà tí ó yẹ kí wọ́n pa dà sí ibi ìtẹ́jú ẹrẹ̀ tàbí etíkun oníyanrìn wọn. Wọ́n jẹ́ ojúlówó akíyè-sákòókò, ọlọ́gbọ́n àdánidá, wọ́n sì mọ bí àwọn ìrugùdù náà ṣe ń ṣe sí.

Bẹ́ẹ̀ ni, àkókò ìrọ́gììrì níbi ìrugùdù òkun gíga jẹ́ ìran amúniláyọ̀, ní pàtàkì, bí a bá ń wò ó fún ìgbà kíní!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní United States àti Kánádà, a mọ àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò (ti ìdílé Charadriiformes) dunjú bí ẹyẹ etídò.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Gbádùn Àkókò Ìrọ́gììrì Náà

Láti gbádùn àkókò ìrọ́gììrì níbi òkun gíga kan, kọ́kọ́ wá ẹnu odò yíyẹ kan kàn. Lẹ́yìn náà, ìwọ yóò nílò ìsọfúnni díẹ̀ nípa àgbègbè náà, nípa irú ibi tí àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò máa ń lọ àti ibi tí o ti lè máa wòran wọn. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣètò àkọsílẹ̀ oníṣirò nípa ìrugùdù òkun kí o lè mọ ìgbà tí ìrugùdù gíga ìgbà ìrúwé, tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn ìgbà òṣùpá àrànmọ́jú tàbí lẹ́yìn ìgbà oṣù tuntun, yóò wáyé. Ní àfikún sí àkókò tí yóò gbà ọ́ láti rìnrìn àjò débẹ̀, fi wákàtí mẹ́ta sílẹ̀ láti fi wòran àwọn ẹyẹ náà dáradára, kí o sì débẹ̀, ó kéré tán, ní wákàtí méjì ṣáájú ìrugùdù gíga náà.

Àwọn ohun èèlò wo ni ìwọ yóò nílò? Bí kò bá jẹ́ pé o ti mọ̀ nípa àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò dáradára, yẹ ìwé kan wò láti dá wọn mọ̀. Awò kan lè wúlò gidigidi pẹ̀lú. Ìwọ yóò mọ̀ láìpẹ́ pé irú ọ̀wọ́ ẹyẹ tí ń wọ́dò kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ànímọ́ ìdánimọ̀ tirẹ̀, ó sì ń ṣa oúnjẹ lọ́nà tí ó bá bí a ṣe ṣẹ̀dá àgógó rẹ̀ mu. Awò awọ̀nàjíjìn kò pọn dandan—ṣùgbọ́n aṣọ amóoru, tí omi kò lè rin pọn dandan! Wà lójúfò sí àwọn ewu. Má ṣe rìn lórí àwọn ìtẹ́jú ẹrẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé o ti mọ̀ wọ́n dunjú. Ó rọrùn láti di ẹni tí ìrugùdù tí ń yára ga sókè ká mọ́. Láfikún sí i, bí kùrukùru ìsẹ̀ ìrì òkun bá dé lójijì, o lè tètè sọ nù. Tún ṣàgbéyẹ̀wò ẹ̀fúùfù pẹ̀lú. Àwọn ìjì líle lè fa ìrugùdù ìgbì tí ń yára ga sókè tí ó sì lè ṣèjàǹbá gidigidi ní ẹnu odò èyíkéyìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn Ẹnu Odò Pàtàkì Lágbàáyé

Àgbègbè onírugùdù gíga gan-an, tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ní Europe ni a ń pè ní Wadden Zee, ní Netherlands, ó sì ṣeé ṣe kí ó máa gbàlejò àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò tí ó lé ní igba ọ̀kẹ́. Ó nà lọ ní ìhà àríwá sí ìhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jutland. Ibi mẹ́ta tí ó dára láti ṣèbẹ̀wò sí ní àgbègbè gbígbòòrò yí ni ọ̀nà omi tí ó lọ sí Rømø, ní Denmark; ẹnu Odò Weser, lájorí ibi tí àwọn ẹyẹ ń bà sí nígbà ìrugùdù gíga, ní Germany; àti Lauwers Zee nítòsí Groningen, ní Netherlands. Níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Iberian, ẹnu odò tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni ti Odò Tagus ní Portugal.

Àwọn ẹnu odò tí ó wà ní etíkun Pacific ti àpapọ̀ Àríwá àti Gúúsù America ń pèsè oúnjẹ fún nǹkan bí irínwó ọ̀kẹ́ àwọn aṣíkiri ẹyẹ tí ń wọ́dò. Lára àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì tí wọ́n wà ni ibi ìyawọlẹ̀ omi òkun ti San Francisco àti ti Humboldt, ní California; 200 kìlómítà níbùú lóròó ní Kánádà láti ibi Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Ẹnubodè Vancouver yí po lọ sí Erékùṣù Iọ́nà, British Columbia; àti ẹnu odò Stikine òun ẹ̀ya ẹnu Odò Copper ti Alaska.

A tún lè rí àwọn ibi títayọlọ́lá fún àwọn ẹyẹ tí ń wọ́dò ní ibi Ìyawọlẹ̀ Omi Bolivar àti Galveston, ní Texas, U.S.A.; ní Tai-Po, ní Hong Kong; ní Cairns, ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Australia; àti nítòsí Mombasa, Kenya.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Àwọn ẹyẹ “oystercatcher” márùn-ún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Àwọn ẹyẹ “knot” tí ń rọ́ gììrì láti ibùwọ̀ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

ẸNU ODÒ ALDE, SUFFOLK

Ojúkò ìwòran B

Ojúkò ìwòran D

Ibi ìwòran àkọ́kọ́ A

Gbọ̀ngàn Ìṣiré Snape Maltings

[Credit Line]

Snape Maltings Riverside Centre

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹyẹ “knot”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ẹyẹ “redshank”

Ẹyẹ “curlew”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Lókè: Àwọn ẹyẹ “curlew”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́