ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 16
  • Àwòkọ́ṣe Kan Láti Fara Wé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwòkọ́ṣe Kan Láti Fara Wé
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹwà Àwọn Ọgbà Ohun Alààyè Orílẹ̀-Èdè Níbi Òkè
    Jí!—1997
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 16

Àwòkọ́ṣe Kan Láti Fara Wé

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ CHILE

Giacomo Castelli ní ilé gbéetán kan ní Antofagasta, ìlú ńlá kan ní ìhà àríwá Chile, tí àwọn olùgbé ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 170,000. Ní June tó kọjá, láti ibi àkọ́yọ ilé rẹ̀, ó ṣàkíyèsí àwùjọ àwọn ènìyàn kan ní ọgbà ìtura àdúgbò kan. Ó kọ sínú lẹ́tà kan sí ìwé agbéròyìnjáde El Mercurio pé: “Ohun kíkàmàmà níbẹ̀ ni rírí àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n ń rẹ́rìn-ín, tí wọ́n sì ń gbádùn ara wọn pẹ̀lú àwọn òbí wọn.” Láti rí àrídájú ohun tí ó ń wò náà, ó lọ sínú ọgbà ìtura náà.

Òǹkọ̀wé ọlọ́fìn-íntótó náà sọ pé: “Mo tún rí ìyàlẹ́nu mìíràn. Nígbà tí díẹ̀ lára àwọn ìdílé náà parí oúnjẹ ọ̀sán wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa ohun tí ó ṣèèṣì bọ́ sórí koríko láti ọwọ́ wọn, wọ́n sì ń jù ú sínú àpò pàǹtírí olúkúlùkù wọn. . . .”

Òǹkọ̀wé náà ń bá a lọ pé: “Mo fẹ́ láti mọ ẹni tí àwọn ènìyàn ṣíṣàjèjì yí jẹ́. Mo tọ ọmọdébìnrin rírẹwà kan, tí ó jojú ní gbèsè tó láti gbẹ̀yẹ ìdíje ẹwà, lọ, ó sì wí fún mi lọ́nà pẹ̀lẹ́ gan-an pé: ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a sì ń pàdé ní Pápá Ìṣeré Regional fún àpéjọ kan.’” Nígbà ìsinmi ọ̀sán, àwọn àwùjọ láti àpéjọ àyíká náà tí 3,000 ènìyàn pésẹ̀ sí, lọ sí ọgbà ìtura náà láti jẹun ọ̀sán.

Òǹkọ̀wé náà sọ pé: “Mo jẹ́ Roman Kátólíìkì ti ìjọ Àpọ́sítélì. Mo máa ń fi tọkàntọkàn lọ síbi ìsìn Máàsì mímọ́, mo tilẹ̀ rìnrìn àjò lọ síbi ìjọsìn ní Lourdes, ní ilẹ̀ Faransé, lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn.

“Bí ó ti wù kí ó rí, ní bíbọ̀wọ̀ fún títọ́ tí wọ́n tọ́ mi dàgbà bíi Kristẹni lọ́nà jíjinlẹ̀, mo gbọ́dọ̀ bi ara mi léèrè láìsí àbòsí pé: Kí ni wọ́n ní tí àwa Kátólíìkì, ìsìn àwọn púpọ̀ jù lọ ní Chile, kò ní? Èé ṣe tó fi jọ pé ara tu àwọn ọ̀dọ́langba wọ̀nyí láti wà pẹ̀lú àwọn òbí wọn, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọmọbìnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kì í fara mọ́ mi bí mo bá tilẹ̀ dámọ̀ràn èrò jíjùmọ̀ròde?

“Èé ṣe tí àwọn ọmọ wa tí wọ́n jẹ́ Kátólíìkì fi jẹ́ oníjàgídí-jàgan; èé ṣe tí wọ́n fi máa ń pariwo, tí wọ́n sì máa ń ṣe eré ẹ̀dá ìtàn ‘Power Rangers,’ tí wọ́n máa ń lu àwọn ọmọdé mìíràn, . . . àmọ́ tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ní ẹ̀mí àlàáfíà, tí wọ́n ń dunnú lọ́nà gbígbámúṣé, tí ẹ̀kọ́ nípa ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn sì jẹ wọ́n lọ́kàn? Èé ṣe tí àwa Kátólíìkì kò lè pé jọ pọ̀ ní àwọn àpéjọ láìsí kíkówọnú ìpolówó-ọjà akóni-nírìíra, tí ó yí àwọn ibi ìjọsìn wa mímọ́ jù lọ ká, bí àwọn ojúbọ La Tirana, Andacollo, àti àwọn mìíràn?”

Ẹni tí ó kọ ìwé náà, Ọ̀gbẹ́ni Castelli, parí lẹ́tà rẹ̀ sí ìwé agbéròyìnjáde náà pẹ̀lú ìbéèrè pé: “Ǹjẹ́ àwa tí a ka ara wa sí Kátólíìkì àti Kristẹni yóò ha dà bíi wọn láé bí? Kí Ọlọ́run àti Wúndíá náà ràn wá lọ́wọ́ láti lè ṣe bẹ́ẹ̀.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́