Ìrètí Fífẹsẹ̀múlẹ̀ Láàárín Ipò Ìbànújẹ́ ní Chernobyl
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Ukraine
NÍ April 26, 1986, ìjàǹbá bíburú jù lọ ní ilé iṣẹ́ agbára átọ́míìkì nínú ìtàn, ṣẹlẹ̀ ní Chernobyl, Ukraine. Lápá ìparí ọdún yẹn, Mikhail Gorbachev, tí ó jẹ́ ààrẹ ilẹ̀ Soviet nígbà náà, sọ pé, ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà jẹ́ ìránnilétí aṣèpalára pé “aráyé kò lè ṣàkóso àwọn ipá alágbára tí ó ti ṣàwárí.”
Nígbà tí ó ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìjábá tí ó ṣẹlẹ̀ ní Chernobyl náà, ẹ̀dà ìwé ìròyìn Psychology Today ti February 1987, lédè German, sọ pé: “Ìjábá tí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì fà ní Chernobyl . . . jẹ́ àkókò ìyípadà ńlá nínú ìtàn ọ̀làjú òde òní. Ó sì jẹ́ àjálù tí yóò nípa lórí wa fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún dé ìwọ̀n gíga.” Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé, “ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìtànṣán olóró, onígbà pípẹ́ [ti tú jáde] sínú afẹ́fẹ́ àgbáyé, iyanrìn tó wà lókè ilẹ̀ àti omi bíi gbogbo àwọn àyẹ̀wò átọ́míìkì àti àwọn bọ́ǹbù tí ó tí ì bú gbàù rí.”
Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Germany náà, Hannoversche Allgemeine, sọ tẹ́lẹ̀ pé, “ní 50 ọdún tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a fojú díwọ̀n sí 60,000 jákèjádò àgbáyé ni àrùn jẹjẹrẹ yóò pa ní àbájáde ìyòòrò àárín ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára mànàmáná ní Soviet náà . . . Àwọn 5,000 míràn yóò jìyà ìpalára eléwu nínú apilẹ̀ àbùdá wọn, nǹkan bí 1,000 ènìyàn yóò sì jìyà àbùkù ìlera láti ìgbà ìbí wọn.”
Ọ̀ràn ìbànújẹ́ Chernobyl fa ẹ̀rù, àníyàn, àti àìdánilójú lọ́nà tí ń ṣẹ̀rù bani, tí ó ti mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀mí banú jẹ́. Síbẹ̀, àwọn kan ti ń gbádùn ìrètí fífẹsẹ̀múlẹ̀ kan láàárín ìbànújẹ́ rírékọjá ààlà. Ṣàgbéyẹ̀wò ìdílé Rudnik, tí ó ní nínú, Victor àti Anna àti àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì, Elena àti Anja. Ní April 1986, ìdílé Rudnik ń gbé ní Pripet, tí kò tó kìlómítà mẹ́ta sí ibi tí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì ti Chernobyl náà wà.
Ọjọ́ Tí Ìjàǹbá Náà Ṣẹlẹ̀
Ní òwúrọ̀ Saturday tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà ṣẹlẹ̀, ìgbésẹ̀ akin tí àwọn panápaná gbé lórí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì tí ó lábùkù náà ṣèdíwọ́ fún àbáyọrí kan tí ì bá burú jáì. Láàárín wákàtí mélòó kan, àrùn tí ìtànṣán olóró ń fà ti kọ lu àwọn panápaná náà, àwọn mélòó kan lára wọn sì kú nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Grigori Medwedew, igbákejì ọ̀gá onímọ̀ ẹ̀rọ ní Chernobyl ní àwọn ọdún 1970, ṣàpèjúwe nínú ìwé rẹ̀, Burned Souls, pé: “Èéfín olóró náà fẹ́ gba àárín oko igi ahóyaya kékeré tí ó la ibi tí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì náà wà àti ìlú láàárín, ó sì rọ̀jò eérú olóró bo igbó náà.” Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èròjà olóró tí ó ti di ooru ni a gbọ́ròyìn pé ó tú sí afẹ́fẹ́!
Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ó jọ pé ìgbésí ayé ń lọ bí ó ti máa ń rí ní Pripet, ìlú ńlá kan tí àwọn olùgbé ibẹ̀ lé ní 40,000, ní ọjọ́ Saturday yẹn. Àwọn ọmọdé ń ṣeré ní òpópónà, àwọn ènìyàn sì ń múra sílẹ̀ fún ayẹyẹ họlidé tí Soviet máa ń ṣe ní May 1. Kò sí ìkéde kankan nípa ìjàǹbá náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìkìlọ̀ kankan nípa ewu náà. Anna Rudnik wà lóde, ó ń najú pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀ ọlọ́dún mẹ́ta, Elena, nígbà tí wọ́n pàdé ọkọ ìyá Anna. Òun ti gbọ́ nípa ìjàǹbá náà. Bí ó ti ń dààmú nípa ewu ìtànṣán olóró, ó yára wà wọ́n lọ sí ilé rẹ̀ tí ó jìnnà tó kìlómítà 16 síbẹ̀.
Èéfín olóró náà wọnú afẹ́fẹ́, ó sì fẹ́ kọjá ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà lọ dé Ukraine, Belorussia (Belarus nísinsìnyí), Rọ́ṣíà, àti Poland, ó fẹ́ dé Germany, Austria, àti Switzerland pẹ̀lú. Ní ọjọ́ Monday tó tẹ̀ lé e, ìdààmú bá àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Sweden àti Denmark nígbà tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìwọ̀n gíga ìtújáde ìtànṣán olóró.
Àbájáde Rẹ̀
Wọ́n rán àwọn sójà, panápaná, ògbógi nínú iṣẹ́ ìkọ́lé, àti àwọn mìíràn ní Soviet lọ sí Chernobyl. Àwùjọ ènìyàn yìí—tí wọ́n tó 600,000—di èyí tí a wá mọ̀ sí “àwọn olùṣàtúnṣe.” Wọ́n ṣèdíwọ́ fún ìjábá tí ì bá burú jáì fún Europe nípa fífi pósí olókùúta tí wọ́n fi irin lílẹ̀ àti kọnkéré ṣe, tí ó ga tó ilé alájà mẹ́wàá, tí ó sì ki ní mítà méjì dí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì tí ó bà jẹ́ náà.
Wọ́n bẹ́rẹ̀ sí í kó àwọn ènìyàn kúrò ní àwọn àgbègbè tí ó sún mọ́ ọn láàárín ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn náà. Victor ṣàlàyé pé: “A ní láti pa ilé wa tì, kí a fi ohun gbogbo sílẹ̀—aṣọ, owó, ìwé àkọsílẹ̀, oúnjẹ—gbogbo ohun tí a ní. A ń ṣàníyàn jinlẹ̀jinlẹ̀, níwọ̀n bí Anna ti wà nínú oyún ọmọ wa kejì.”
Nǹkan bí 135,000 ènìyàn ní láti kó kúrò níbẹ̀—gbogbo ibùdó tí ó wà ní 30 kìlómítà sí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì náà ni àwọn ènìyàn ti kó kúrò. Ìdílé Rudnik kó lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹbí wọn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí í fòyà pé ìdílé Rudnik yóò kó ìtànṣán olóró náà ràn wọ́n. Anna sọ pé: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dààmú, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n ní kí a máa lọ.” Àwọn ènìyàn míràn tí wọ́n kó kúrò níbẹ̀ ní irú ìrírí aronilára tí ó jọra. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ní September 1986, ìdílé Rudnik tún fi Kaluga ṣe ibùjókòó, nǹkan bí 170 kìlómítà sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn Moscow, Rọ́ṣíà.
Anna sọ pé: “Lẹ́yìn náà, a wá mọ̀ níkẹyìn pé kò sí ìrètí pípadàsílé. A ti pàdánù ilé ìdílé wa ọ̀wọ́n, níbi tí wọ́n bí wa sí, tí wọ́n sì ti tọ́ wa dàgbà. Ó jẹ́ àgbègbè tí ó lẹ́wà, tí òdòdó àti ewéko tútù bo ilẹ̀ rẹ̀, tí àwọn òṣíbàtà wà nínú itọ́ odò. Igbó rẹ̀ kún fún èso oníwóóníṣu àti olú.”
Kì í ṣe pé ẹwà Ukraine bà jẹ́ nìkan ni, àmọ́, ipa iṣẹ́ rẹ̀ bí èyí tí ń ṣèmújáde ọkà fún Soviet Union bà jẹ́ pẹ̀lú. Ọ̀pọ̀ lára ìkórè orílẹ̀-èdè náà nígbà ìwọ́wé yẹn ni ó ti ní májèlé nínú. Bákan náà, ní Scandinavia, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún ẹran ìgalà ni a polongo bí èyí tí kò dára láti jẹ nítorí pé àwọn ẹranko náà ti jẹ àwọn ewéko tí ó ní ìtànṣán olóró. Àti pé ní àwọn apá kan ní Germany, wọ́n ń fi àwọn ewébẹ̀ sílẹ̀ láti jẹrà nínú oko nítorí ìbẹ̀rù níní májèlé.
Ìbàjẹ́ Tí Ìtànṣán Olóró Ṣe fún Ìlera
Iye tí àwọn aláṣẹ gbé jáde lọ́dún márùn-ún lẹ́yìn ìjàǹbá náà sọ pé, 576,000 ènìyàn ni wọ́n fara gba ìtànṣán olóró. Ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn àrùn tí ó ní àrùn jẹjẹrẹ àti èyí tí kò ní àrùn jẹjẹrẹ nínú ni a ròyìn pé ó pọ̀ jù láàárín irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Ní pàtàkì, ó ti ṣèbàjẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́. Ìwé ìròyìn New Scientist ti December 2, 1995, sọ pé, ọ̀kan lára àwọn ògbógi tí ó mú ipò iwájú nípa èkùrọ́ ọrùn ní ilẹ̀ Europe gbà gbọ́ pé, “ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé tí wọ́n fara gba àwọn ìwọ̀n gíga jù lọ èròjà olóró tí ó fọ́nká láti Chernobyl nígbà tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún kan lè wá ní àrùn jẹjẹrẹ inú èkùrọ́ ọrùn bí wọ́n bá dàgbà.”
Nítorí pé Anna ti fara gba ìtànṣán olóró náà nígbà tó wà nínú oyún, àwọn dókítà rin kinkin mọ́ pé kí ó ṣẹ́yún. Nígbà tí Victor àti Anna kọ̀ jálẹ̀, wọ́n ní láti fọwọ́ sí àkọsílẹ̀ kan ní ṣíṣèlérí pé wọn óò bójú tó ọmọ náà, kódà bí wọ́n bá bí i ní abirùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Anja kì í ṣe abirùn, ó ní àrùn àìríranjìnnà, ìṣòro èémí, àti àwọn àrùn tí ó kan ọkàn àyà àti ìṣàn ẹ̀jẹ̀. Ní àfikún sí i, ìlera àwọn mẹ́ńbà ìdílé Rudnik míràn ti bà jẹ́ láti ìgbà ìjábá náà. Victor àti Elena ti ní àwọn ìṣòro ọkàn àyà, Anna sì jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn tí a kọ orúkọ wọn sílẹ̀ bí aláàbọ̀-ara ní Chernobyl.
Lára àwọn tí wọ́n fara gba ìtànṣán olóró jù lọ ni àwọn olùṣàtúnṣe tí wọ́n dí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí wọ́n ṣèrànwọ́ níbi ìpalẹ̀mọ́ náà ni a sọ pé wọ́n ti kú láìtọ́jọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ṣì wà ni wọ́n ní ìṣòro ìgbékalẹ̀ ìṣètò ọpọlọ àti ti èrò orí. Ìsoríkọ́ wà káàkiri, ìṣekúpara-ẹni kò sì ṣọ̀wọ́n.
Angela jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùlàájá, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà àwọn ìṣòro ìlera líle koko. Nígbà ìjábá náà, ó ń gbé Kiev, olú ìlú Ukraine, tí ó jìnnà ju 80 kìlómítà lọ sí Chernobyl. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, ó máa ń lọ gbé ohun tí àwọn olùṣàtúnṣe náà nílò fún wọn ní ibi tí ìhùmọ̀ aṣàkóso ìgbéjáde agbára átọ́míìkì náà wà. Svetlana, olùlàájá mìíràn, tí ń gbé Irpin’, nítòsí Kiev, ní àrùn jẹjẹrẹ, wọ́n sì ṣiṣẹ́ abẹ fún un.
Ríronú Lórí Ohun Tó Ti Kọjá
Ní April 1996, ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí àjálù ibi ńláǹlà náà ṣẹlẹ̀, Mikhail Gorbachev sọ pé: “A kò múra sílẹ̀ fún irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn rárá.” Lákòókò kan náà, Ààrẹ Yeltsin ti Rọ́ṣíà sọ pé: “Aráyé kò tí ì nírìírí irú ìṣẹ̀lẹ̀ ibi tí ìbàjẹ́ rẹ̀ pọ̀ tó báyìí rí, tí ó ní àbájáde líle koko gan-an tó bẹ́ẹ̀, tí ó sì ṣòro láti yanjú.”
Lọ́nà tí ó gbàfiyèsí, ẹ̀dà ìwé ìròyìn Scientific American lédè German fi àbájáde ìjábá Chernobyl náà wé ohun tí ì bá ti jẹ́ ìyọrísí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé alábọ́ọ́dé kan. Àwọn kan fojú díwọ̀n iye àwọn tó kú nítorí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ náà sí nǹkan bí 30,000.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan ti sọ lọ́dún tó kọjá, nígbà àyájọ́ ọdún kẹwàá ìjàǹbá náà, àgbègbè oníkìlómítà 29 kan ṣì wà nítòsí ilé iṣẹ́ náà, tí ẹ̀dá ènìyàn kò gbọ́dọ̀ gbé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìròyìn náà sọ pé, “647 lára àwọn olùgbé ibẹ̀ tí wọ́n ta kú ti yọ́ wọ ibẹ̀, nípa fífún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lábẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí wíwọ àgbègbè náà lọ láìfibò.” Ó ṣàlàyé pé: “Láìsí-tàbítàbí, kò sí ẹni tí ń gbé máìlì 6 [kìlómítà 10] sí àgbègbè ilé iṣẹ́ náà. Àgbègbè míràn tí ó fẹ̀ ní máìlì 12 [20 kìlómítà] tí ó yí ìyẹn ká ni àwọn ènìyàn ọgọ́rùn-ún bíi mélòó kan pa dà sí.”
Ìgbọ́kànlé Láàárín Ìbẹ̀rù Tí Ó Wà Káàkiri
Fún ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n ti gbé nítòsí Chernobyl rí, ìgbésí ayé ti ṣòro gan-an, ó sì ṣòro síbẹ̀. Ìwádìí kan tí a gbé jáde nípa àwọn tí wọ́n kúrò níbẹ̀ fi hàn pé, ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ni kò láyọ̀ ní àwọn ibùgbé wọn tuntun. Inú wọ́n ń bà jẹ́, ó ń rẹ̀ wọ́n, ara ń ni wọ́n, ara ń kan wọ́n, wọ́n sì nímọ̀lára ìdánìkanwà. Chernobyl kì í ṣe ìjàǹbá agbára átọ́míìkì kan lásán—ó jẹ́ rògbòdìyàn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ìrònú òun ìhùwà tí ó pọ̀ lọ́nà kíkọyọyọ. Kò yani lẹ́nu pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ gbígbàfiyèsí bí èyí tí ó ṣáájú ti Chernobyl tàbí bí èyí tí ó tẹ̀ lé ti Chernobyl.
Ní ìyàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹpẹtẹ mìíràn, ìdílé Rudnik kojú ipò náà dáradára lọ́nà tí ó gbàfiyèsí. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti pé, ní àbájáde rẹ̀, wọ́n mú ìgbàgbọ́ tí ó lágbára dàgbà nínú ìlérí tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ayé tuntun òdodo kan. (Aísáyà 65:17-25; Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Lẹ́yìn náà, ní 1995, Victor àti Anna fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ọmọbìnrin wọn, Elena, pẹ̀lú ṣèrìbọmi.
Victor ṣàlàyé pé: “Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ kí a lè mọ Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, àti àwọn ète rẹ̀ fún aráyé lórí ilẹ̀ ayé. A kò tún sorí kọ́ mọ́, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, irú àwọn ìjàǹbá líle koko bẹ́ẹ̀ kò ní wáyé mọ́. A ń fojú sọ́nà fún àkókò náà nígbà tí agbègbè àrọko tí ó yí ibùgbé wa ọ̀wọ́n lẹ́bàá Chernobyl ká yóò kọ́fẹ pa dà kúrò ní ipò bíbàjẹ́ tí ó wà, tí yóò sì di apá kan párádísè àgbàyanu.”
Angela àti Svetlana, tí àwọn pẹ̀lú gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run, ní ìfojúsọ́nà fún ọjọ́ ọ̀la amọ́kànyọ̀ kan náà láìka àwọn àrùn tí ìtànṣán olóró ń fà tí ń ṣe wọ́n sí. Angela sọ pé: “Láìsí ìmọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá àti àwọn ète rẹ̀, ìgbésí ayé yóò ṣòro. Ṣùgbọ́n, níní ipò ìbátan pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú Jèhófà ń ràn mí lọ́wọ́ láti máa ní ojú ìwòye títọ̀nà. Ìfẹ́ ọkàn mi jẹ́ láti máa bá ṣíṣiṣẹ́sìn ín lọ gẹ́gẹ́ bí oníwàásù alákòókò-kíkún nípa Bíbélì.” Svetlana fi kún un pé: “Àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà fún mi.”
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti fi hàn fún irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ pé, ìjàǹbá tí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” fà ń fìyà jẹ àwọn ènìyàn níbi yòó wù kí wọ́n wà àti ẹni yòó wù kí wọ́n jẹ́. (Oníwàásù 9:11, NW) Ṣùgbọ́n àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, láìka bí àwọn ìṣòro wọn ṣe lè máa múni banú jẹ́ tó sí, kò sí ohun tí ó bà jẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run kò lè tún ṣe, kò sí ìpalára tí kò lè wò sàn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àdánù tí kò lè san pa dà.
Báwo ni ìwọ pẹ̀lú ṣe lè ní ìgbọ́kànlé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ gbádùn ìrètí amọ́kànyọ̀? Ẹni tí ó kọ ìwé Òwe inú Bíbélì dáhùn pé: “Kí ìgbọ́kànlé rẹ lè wá wà nínú Jèhófà ni mo ṣe fún ọ ní ìmọ̀ lónìí.” (Òwe 22:19, NW) Bẹ́ẹ̀ ni, o ní láti gba ìmọ̀ nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àgbègbè rẹ yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí. Wọ́n ń nawọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí a óò pèsè ní àkókò àti ibi yíyẹ fún ọ, lọ́fẹ̀ẹ́.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
“Aráyé kò tí ì nírìírí irú ìṣẹ̀lẹ̀ ibi tí ìbàjẹ́ rẹ̀ pọ̀ tó báyìí rí, tí ó ní àbájáde líle koko gan-an tó bẹ́ẹ̀, tí ó sì ṣòro láti yanjú.” Ààrẹ Yeltsin ti Rọ́ṣíà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Chernobyl kì í ṣe ìjàǹbá agbára átọ́míìkì kan lásán—ó jẹ́ rògbòdìyàn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ti ìrònú òun ìhùwà tí ó pọ̀ lọ́nà kíkọyọyọ
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Tass/Sipa Press