Ó Mú Kí Ó Gbégbèésẹ̀!
Ọkùnrin kan láti Caracas, olú ìlú Venezuela, ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀ tó ti darúgbó, Rufino. Bàbá náà ń gbé ní La Loma, abúlé kan ní ìgbèríko náà. Ọmọkùnrin náà fún Rufino ní ìwé náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
Lẹ́yìn ìgbà náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti Los Humocaros lọ wàásù ní La Loma. Ó yà wọ́n lẹ́nu pé àwọn ènìyàn ń sọ pé Ẹlẹ́rìí kan ti ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn. Ó ṣe Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ní kàyéfì nítorí pé wọ́n mọ̀ pé kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tí ń gbé ní àgbègbè náà. Ẹní kan wá tọ́ka sí ilé ẹni tí wọ́n pè ní Ẹlẹ́rìí náà—ilé Rufino ni!
Inú Rufino dùn láti rí àwọn àlejò rẹ̀. Kí ló mú kí àwọn ará abúlé rẹ̀ pè é ní ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tóò, Rufino ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé Walaaye Titilae náà, nígbà tí ó sì dé orí 13, ó rí àwòrán bí Jésù ṣe ń rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde láti wàásù. Rufino dé orí ìpinnu náà pé àwọn Kristẹni òde òní gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ kan náà. Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn aládùúgbò rẹ̀ ṣàjọpín àwọn òtítọ́ tí ó ti ń kọ́ láti inú Bíbélì.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé pẹ̀lú Rufino, wọ́n sì sọ fún un nípa àwọn ìpàdé ìjọ. Ó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Sunday tó tẹ̀ lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni 80 ọdún ni Rufino, ó ti rin ìrìn wákàtí mẹ́ta láti débẹ̀! Láti ọjọ́ yẹn lọ, kò pa ìpàdé kankan jẹ, àyàfi bí ó bá ń ṣàìsàn gidigidi. Ó tilẹ̀ forúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ó sì sọ̀rọ̀ gbígbámúṣé kan. Rufino ṣàìsàn ní èṣín, ó sì kú ní July 1996, ó ní ìrètí fífẹsẹ̀múlẹ̀ nípa àjíǹde sínú párádísè ilẹ̀ ayé kan.
A gbà gbọ́ pé ìwọ náà yóò jàǹfààní nípa kíka ìwé aláwòrán mèremère, olójú ìwé 256 náà, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Bí o bá fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè gba ẹ̀dà rẹ̀ kan, tàbí bí o bá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú ní ojú ìwé 5.