ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 22-23
  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Ayẹrafógun Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Ayẹrafógun Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìlòdìsí Ogun Tàbí Ìwà Ipá
  • Wọ́n Ha Lòdì Sí Ogun Pátápátá Bí?
  • Ogun
    Jí!—2017
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • “Ìgbà Àlàáfíà” Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 22-23

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Jẹ́ Ayẹrafógun Bí?

“Ó yẹ kí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì di ayẹrafógun lẹ́ẹ̀kan sí i bí wọ́n ṣe jẹ́ ní àwọn ọ̀rúndún kìíní ìsìn Kristẹni.”—Hubert Butler, òǹkọ̀wé tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ireland.

LẸ́YÌN ìbẹ̀wò kan sí Yugoslavia lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, Hubert Butler fi ìgbójúgbóyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yí nínú àròkọ kan tí ó kọ ní 1947, àmọ́, tí a kò tẹ̀ jáde títí fi di ọdún tó kọjá! Ẹ̀rù bà á nípa bí “Ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ṣe fàyè gba àwọn ìwà ipá bíburú jáì nígbà ogun, tí ó sì yà bàrà kúrò nínú ohun tí Kristi fi kọ́ni.”

Ẹ̀rù kò ba Butler láti sọ̀rọ̀ síta fún àwọn ìlànà tàbí àwùjọ tí kò gbajúmọ̀. Nígbà tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, òun nìkan ni ó dá àlàyé ọ̀rọ̀ náà ṣe. Ó ṣàlàyé ara rẹ̀ láìbẹ̀rù nígbà tí ó fi ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ìhùwà àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wé ìṣesí èrò ìmọ̀lára onígboyà ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí a ṣàpèjúwe wọn nínú ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times gẹ́gẹ́ bí “ẹ̀ya ìsìn aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ jù lọ tí kò lọ́kàn ìfẹ́ nínú ìṣèlú lọ́nà àìlábàwọ́n láàárín gbogbo àwọn yòó kù ní gidi.” Nínú àròkọ rẹ̀, “Ìròyìn Nípa Yugoslavia,” Butler kọ ọ́ pé, àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Yugoslavia gbẹ́jọ́ lẹ́nu Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n “kọ gbogbo èrò ẹ̀tàn tí àwọn aṣáájú nínú ìgbòkègbodò ìṣèlú àti ti ìsìn fi dá ogun láre,” nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti dara pọ̀ nínú ìgbòkègbodò ogun.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó ha tọ̀nà lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, láti ṣàpèjúwe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ayẹrafógun? Láti ṣàlàyé ọ̀ràn náà kí ó yéni, ó lè sinmi lórí ohun tí a ní lọ́kàn nípa ọ̀rọ̀ náà, “ayẹrafógun.” Butler lo ọ̀rọ̀ náà láti gbóríyìn fún Àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí ìgboyà wọn ní kíkọ̀ láti dìhámọ́ra nínú ogun, lójú ìfìyàjẹni lílekoko. Bí ó ti wù kí ó rí, ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ìgbòkègbodò ogun gbà lọ́kàn pátápátá fojú wo ayẹrafógun kan kìkì bí “ojo tàbí ọ̀dàlẹ̀, tí ó dàníyàn láti yẹ ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ sílẹ̀.” Ojú ìwòye yẹn ha tọ̀nà bí?

Ìlòdìsí Ogun Tàbí Ìwà Ipá

Ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary sọ pé, ayẹrafógun ni ẹnì kan tí ó “lòdì sí ìforígbárí, àti ní pàtàkì ogun, lọ́nà lílágbára àti ní ìṣe.” Ó túmọ̀ “ìyẹrafógun” bí “ìlòdìsí ogun tàbí ìwà ipá gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtiyanjú awuyewuye; ní pàtàkì: kíkọ̀ láti dìhámọ́ra ogun lórí ìpìlẹ̀ ìwà títọ́ tàbí ti ìsìn.” Báwo ni àwọn ìtumọ̀ wọ̀nyí ṣe kan àwọn onígbàgbọ́ ní àwọn ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?

Wọ́n ‘kọ̀ láti dìhámọ́ra ogun lórí ìpìlẹ̀ ìwà títọ́ àti ti ìsìn,’ wọ́n sì yẹra fún gbogbo ‘ìforígbárí àti ogun.’ Èé ṣe? Nítorí wọ́n mọ̀ pé Jésù ti sọ pé, àwọn ọmọlẹ́yìn òun “kì í ṣe apá kan ayé” àti pé “gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.” (Jòhánù 15:19; Mátíù 26:52) Nínú ìwé náà, The Early Church and the World, òpìtàn kan wí fún wa pé, “títí di ìgbà ìṣàkóso Marcus Aurelius, ó kéré pin, [láti ọdún 161 sí 180 Sànmánì Tiwa], kò sí Kristẹni kan tí ó di sójà lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀.” Nínú ìwé náà, The New World’s Foundations in the Old, òpìtàn míràn sọ pé: “Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ronú pé kò tọ̀nà láti jà, wọn kò sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun kódà nígbà tí Ilẹ̀ Ọba náà nílò àwọn sójà.”

Iṣẹ́ tí a yàn fún àwọn Kristẹni jẹ́ láti wàásù ìhìn rere náà. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ó yé wọn pé Ọlọ́run kò yan iṣẹ́ fún àwọn láti gbógun dìde sí àwọn ọ̀tá rẹ̀, láti ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí wọ́n jẹ́ aṣekúpani fún Ọlọ́run. (Mátíù 5:9; Róòmù 12:17-21) Gẹ́gẹ́ bí Butler ti sọ, kìkì nígbà tí àwọn tí a pè ní Kristẹni bá ‘yà kúrò nínú ẹ̀kọ́ tí Kristi kọ́ wọn’ ni wọ́n ń kira bọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè. Nígbà náà ni àwùjọ àwọn àlùfáà ń súre fún àwọn ọmọ ogun, tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún ìṣẹ́gun, tí ó sábà máa ń jẹ́ ní ìhà méjèèjì ìforígbárí náà. (Fi wé Jòhánù 17:16; 18:36.) Fún àpẹẹrẹ, ní Sànmánì Agbedeméjì, àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn Kátólíìkì ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun tí ó mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́wọ́, tí ó yọrí sí ohun tí Kenneth Clark kọ nínú ìwé rẹ̀, Civilisation, pé, “àwọn ohun ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó [já lu] Ìhà Ìwọ̀ Oòrùn Europe, àwọn ìhà méjèèjì polongo ara wọn bí ohun èlò ìrunú Ọlọ́run.” Àwọn ẹ̀rí tí a fi hàn láti fi dá irú ogun báyìí láre ni ìwé gbédègbẹ́yọ̀ McClintock àti Strong náà, Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, sọ pé, “ó hàn gbangba pé wọ́n wá láti inú ìfẹ́ ọkàn láti tu àwọn aláṣẹ ìjọba lójú, ó sì hàn gbangba pé irú àwọn ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ta ko ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni ìgbàanì àti gbogbo ète Ìhìn Rere náà lápapọ̀.”—Jákọ́bù 4:4.

Wọ́n Ha Lòdì Sí Ogun Pátápátá Bí?

Bí ó ti wù kí ó rí, ‘ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kristẹni ìgbàanì àti gbogbo ète Ìhìn Rere náà lápapọ̀’ ha jẹ́ ti ìyẹrafógun bí? A ha lè fi tòótọ́tòótọ́ ṣàpèjúwe àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ayẹrafógun, bí a ṣe túmọ̀ rẹ̀ níṣàájú, bí? Rárá! Èé ṣe tí a kò lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí kan ni pé, wọ́n mọ ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti gbógun. (Ẹ́kísódù 14:13, 14; 15:1-4; Jóṣúà 10:14; Aísáyà 30:30-32) Láfikún sí ìyẹn, wọn kò fìgbà kan rí ta ko ẹ̀tọ́ Ọlọ́run láti fún Ísírẹ́lì ìgbàanì láṣẹ láti jà fún òun nígbà tí orílẹ̀-èdè yẹn ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun èlò rẹ̀ kan ṣoṣo lórí ilẹ̀ ayé.—Orin Dáfídì 144:1; Ìṣe 7:45; Hébérù 11:32-34.

Kì í ṣe ẹ̀tọ́ nìkan ni Ọlọ́run ní, ó tún ní iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe kan lórí ìpìlẹ̀ ìdájọ́ òdodo láti mú àwọn ẹni ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣebi kò ní ṣègbọràn sí ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ onísùúrù tí Ọlọ́run ń ṣe sí wọn láti ṣàtúnṣe àwọn ọ̀nà wọn láé. (Aísáyà 45:22; Mátíù 7:13, 14) Àyè tí Ọlọ́run fi gba ìwà ibi ní ààlà. (Aísáyà 61:2; Ìṣe 17:30) Nítorí náà, àwọn Kristẹni mọ̀ pé nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Ọlọ́run yóò fi tipátipá mú àwọn olubi kúrò lórí ilẹ̀ ayé. (Pétérù Kejì 3:9, 10) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, èyí yóò jẹ́ nígbà “ìṣípayá Jésù Olúwa láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára nínú iná tí ń jó fòfò, bí ó tí ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn wọnnì tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn wọnnì tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.”—Tẹsalóníkà Kejì 1:6-9.

Ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bíbélì ṣàpèjúwe ìforígbárí yìí bí “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tàbí Amágẹ́dónì. (Ìṣípayá 16:14, 16) Ó wí pé Jésù Kristi yóò mú ipò iwájú nínú èyí, pé ó “ń bá ogun lọ nìṣó nínú òdodo.” (Ìṣípayá 19:11, 14, 15) A fi ẹ̀tọ́ pe Jésù Kristi ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6) Àmọ́, òun kì í ṣe ayẹrafógun. Ó ti ja ogun kan tẹ́lẹ̀, ní ọ̀run, láti mú gbogbo àwọn ọlọ̀tẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run kúrò. (Ìṣípayá 12:7-9) Láìpẹ́, òun yóò ja ogun mìíràn “láti mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bàjẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé kò ní kópa nínú ìdájọ́ àtọ̀runwá yẹn.—Ìṣípayá 11:17, 18.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. Wọ́n wà láìdásí tọ̀tún tòsì pátápátá nínú ìforígbárí ogun, ìṣèlú, àti ti ẹ̀yà ìran lágbàáyé. Àmọ́, kí a sọ ọ́ lọ́nà pípé pérépéré, wọn kì í ṣe ayẹrafógun. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n tẹ́wọ́ gba ogun Ọlọ́run tí yóò sọ ìfẹ́ rẹ̀ di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé nígbẹ̀yìngbẹ́yín—ogun kan tí yóò yanjú ọ̀ràn ńlá ti ipò ọba aláṣẹ àgbáyé, tí yóò sì mú gbogbo àwọn ọ̀tá àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé títí láéláé.—Jeremáyà 25:31-33; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 22]

Christ Mocked/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́