ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/22 ojú ìwé 4-7
  • Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ Sí Ohun Àṣenajú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ Sí Ohun Àṣenajú?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ní Láti Ṣọ́ra
  • Tẹlifíṣọ̀n “Olùkọ́ Tó Ń kọ́ Wa Láìmọ̀”
    Jí!—2006
  • Báa Ṣe Lè Ní Èrò Orí Tó Yè Kooro
    Jí!—1999
  • Irú Fíìmù Wo Ni Wàá Máa Wò?
    Jí!—2005
  • Yan Eré Ìnàjú Táá Múnú Jèhófà Dùn
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 5/22 ojú ìwé 4-7

Kí Ló Ti Ṣẹlẹ̀ Sí Ohun Àṣenajú?

BÁWO ni àwọn ará Róòmù ìgbàanì, tí ó jọ pé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn wà ní ipò gíga, ṣe lè wo ìjẹ̀rora àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn bí ohun àṣenajú? Nínú ìwé náà, The Conflict of Christianity With Heathenism, Gerhard Uhlhorn kọ̀wé pé: “Ìyánhànhàn fún àwọn ohun arùmọ̀lára-sókè tuntun, tí wọ́n sì lágbára, nìkan la lè fi ṣàlàyé rẹ̀. Bí gbogbo ìgbádùn tí ó bá lè ṣeé ṣe ti tẹ́ àwọn ènìyàn lọ́rùn, wọ́n ń wá . . . ohun tí yóò ru wọ́n sókè tí wọn kò tún rí níbòmíràn mọ́.”

Ọ̀pọ̀ ènìyàn lónìí ń fi irú “ìyánhànhàn fún àwọn ohun arùmọ̀lára-sókè tuntun, tí ó sì lágbára,” kan náà hàn. Lóòótọ́, wọ́n lè máà kóra jọ láti wòran ìpakúpa tàbí ìwàkiwà tí a kò kó níjàánu ní gidi. Àmọ́, irú ohun àṣenajú tí wọ́n yàn ń fi irú ìsúnniṣe tipátipá kan náà nípa ìwà ipá àti ìbálòpọ̀ hàn. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Sinimá. Michael Medved, tí ó jẹ́ olùṣelámèyítọ́ fíìmù, fi ìtẹnumọ́ kéde pé, ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn tí ń ṣe fíìmù ti fi “ìfẹ́ gíga fún ìwà wíwọ́” hàn. Ó fi kún un pé: “Ó jọ pé kókó ọ̀rọ̀ òwò sinimá ni pé ìgbéjáde ìwà òǹrorò àti ìwà wèrè nílò àgbéyẹ̀wò gidi, àfiyèsí pàtàkì púpọ̀ sí i tí ó yẹ̀ fún ọ̀wọ̀, ju ìgbìdánwò èyíkéyìí láti fi ìwà akin tàbí ìwà rere hàn.”

Ìfigagbága pẹ̀lú tẹlifíṣọ̀n ti fipá mú kí àwọn olùṣefíìmù fẹ́rẹ̀ẹ́ lọ dé ìwọ̀n àyè èyíkéyìí láti tan àwọn ènìyàn sí wíwo sinimá. Alága ilé iṣefíìmù kan sọ pé: “A nílò àwọn àwòrán tí ó lágbára, tí ó sì ń gbàfiyèsí tí ó le jù lọ, tí ó ta yọ láàárín gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí àwọn ènìyàn ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n. Dájúdájú, a kò wà fún fífi àwọn ìran ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ti ọ̀rọ̀ [rírùn] hàn, àmọ́ ohun tí ẹnì kan nílò lóde òní nìyẹn láti gbé fíìmù kan jáde.” Ní tòótọ́, àwòrán sinimá tí ó níwà ipá jù lọ kò tún mú ọ̀pọ̀ ènìyàn wá rìrì mọ́. Olùdarí sinimá náà, Alan J. Pakula, sọ pé: “Àwọn ènìyàn kò fi àìnífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn ìran oníwà ipá tí fíìmù ní mọ́. Iye àwọn tí ń kú ti di ìlọ́po mẹ́rin, iye ìbúgbàù ń yára di rẹpẹtẹ, wọ́n kò sì kọbi ara sí i. Wọ́n ti mú ìfẹ́ ọkàn fún ìmọ̀lára ìwà òǹrorò lọ́nà tí kò ṣeé dá dúró dàgbà.”

Tẹlifíṣọ̀n. Fífi ìbálòpọ̀ hàn láìfibò lórí tẹlifíṣọ̀n ti wọ́pọ̀ nísinsìnyí ní apá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, títí kan Brazil, Europe, àti Japan. Ẹnì kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ní America ń padé ìran ìbálòpọ̀ tí ó tó 14,000 láàárín ọdún kan péré. Àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan sọ pé: “Ìlọsókè nínú àwọn kókó ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ àti àwọn àfihàn tí kò fi ìbálòpọ̀ bò kò fi àmì pé yóò dín kù hàn. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí a ti fìgbà kan kà léèwọ̀, bíi bíbá ẹbí ẹni lò pọ̀, dídunnú nínú ìfìyàjẹni, àti bíbá ẹranko lò pọ̀ ti di ọ̀nà àtipawó gan-an.”

Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Watching America, ti sọ, ìdí kan wà tí ṣíṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n ṣe fàyè gba ohunkóhun. Ó wí pé: “Gbígbé ìbálòpọ̀ jáde ń mérè wá. . . . Bí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àti àwọn ilé iṣẹ́ aṣègbékalẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n ti gbogbogbòò ti ṣàwárí pé àwọn òǹwòran tí àwọn ń ru ìmọ̀lára wọn sókè ju àwọn tí àwọn ń ṣẹ̀ lọ, wọ́n ti mú agbára títa àwọn ìmújáde wọn pọ̀ sí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ nípa fífàyè gba títàpá sí àwọn èèwọ̀ púpọ̀ púpọ̀ sí i lọ́nà ṣíṣe kedere.”

Àwọn Eré Àṣedárayá Orí Fídíò. Sáà tí ó dà bí ìgbà àìmọ̀kan, ní ìfiwéra, tí a gbé àwọn eré àṣedárayá orí fídíò náà, Pac-Man àti Donkey Kong, jáde, ti ṣínà sílẹ̀ fún sànmánì tuntun ti àwọn eré àṣedárayá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀. Ọ̀jọ̀gbọ́n Marsha Kinder ṣàpèjúwe àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí èyí tí “ó burú ju tẹlifíṣọ̀n tàbí sinimá lọ.” Wọ́n ń gbé “ìsọfúnni jáde pé ọ̀nà kan ṣoṣo láti ní agbára jẹ́ nípasẹ̀ ìwà ipá.”

Nítorí àníyàn àwọn aráàlú, ẹnì kan tí ó mú ipò iwájú lára àwọn tí ń ṣe é jáde ní United States nísinsìnyí ń lo ìlànà ìdíwọ̀n kan lórí àwọn eré àṣedárayá orí fídíò rẹ̀. Àkọlé “MA-17” kan—tí ń fi hàn pé, eré tí ó wà fún àwọn “adàgbàdénú” náà kò yẹ fún àwọn tí wọn kò tí ì pé ọmọ ọdún 17—lè ní ìwà ipá líle jù, àwọn kókó ọ̀rọ̀ oníbàálòpọ̀, àti àìmọ́ nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan bẹ̀rù pé, ìdíwọ̀n “adàgbàdénú” yóò kàn dá kún ìfàmọ́ra eré àṣedárayá kan ni. Ọ̀dọ́ kan tí ó jẹ́ olólùfẹ́ eré àṣedárayá sọ pé: “Bí mo bá jẹ́ ọmọ ọdún 15, tí mo sì rí àkọlé MA-17 kan, n óò ra eré àṣedárayá náà lọ́nàkọnà.”

Orin. Ìwé ìròyìn kan tí ń ṣàyẹ̀wò kínníkínní lórí ohun tí ó wà nínú àwọn orín wíwọ́pọ̀ sọ pé, lópin ọdún 1995, lára àwọn 40 àwo orin tí ó mú ipò iwájú, 10 péré ni kò ní ọ̀rọ̀ àìmọ́ tàbí ìtọ́kasí oògùn líle, ìwà ipá, tàbí ìbálòpọ̀ nínú. Ìwé agbéròyìnjáde St. Louis Post-Dispatch sọ pé: “Orin tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn tí wọn kò tí ì bàlágà ń yani lẹ́nu gidigidi, ọ̀pọ̀ lára rẹ̀ jẹ́ aláìnígbàgbọ́ nínú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ gbáà. [Orin] tí ń fa àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà kan mọ́ra kún fún ìbínú àti àìnírètí, ó sì ń fún àwọn ìmọ̀lára pé ayé àti ẹni tí ń tẹ́tí sí i fúnra rẹ̀ ń retí ìparun níṣìírí.”

Ó jọ pé àwọn orin rọ́ọ̀kì ikú “onígìtá àtapajúdé,” àti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò “elédè àwọn ìpàǹpá asùnta” ń fi ìwà ipá ṣayọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan tí ìwé agbéròyìnjáde San Francisco Chronicle gbé jáde sì ti sọ, “ọ̀pọ̀ àwọn tí a tẹ́wọ́ gbà bíi mẹ́ńbà ilé iṣẹ́ olówò ohun àṣenajú ń wí àwítẹ́lẹ̀ pé, àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n ń ṣẹ̀rù bani jù lọ kò ní pẹ́ yọrí.” Àwọn orin tí ń fògo fún ìbínú àti ikú ti lókìkí nísinsìnyí ní Australia, Europe, àti Japan. Lótìítọ́, àwọn ẹgbẹ́ akọrin kan ti gbìyànjú láti ṣàmúlò àwọn ìsọfúnni kan tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ le jù. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé agbéròyìnjáde Chronicle sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ènìyàn púpọ̀ kò ra orin tí kò ní àríwísí.”

Àwọn Kọ̀ǹpútà. Ìwọ̀nyí jẹ́ ohun èlò níníyelórí tí a ń lò fún ọ̀pọ̀ ohun dáradára. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn kan tún ti lò wọ́n láti gbé àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ àlùfààṣá jáde. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Maclean’s ròyìn pé, èyí ní “àwọn àwòrán àti ìwé nípa gbogbo nǹkan láti orí ìgbanilọ́kàn aláìjẹ́lásán dé orí iṣẹ́ aṣẹ́wó títí dé yíyan ọmọdé láàyò fún ìbálòpọ̀ nínú—àwọn ohun tí yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà wá rìrì, kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọmọdé.”

Àwọn Ohun Kíkà. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé lílókìkí kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá. Àṣà ìgbàlódé kan láìpẹ́ ní United States àti Kánádà ni a ti pè ní “ìtàn àròsọ amúniwárìrì”—àwọn ìtàn ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ń dẹ́rù bani, tí wọ́n fojú sun àwọn èwe tí ọjọ́ orí wọn kéré tó ọmọ ọdún mẹ́jọ. Nígbà tí Diana West ń kọ̀wé nínú ìwé ìròyìn náà, New York Teacher, ó sọ pé, àwọn ìwé wọ̀nyí “ń sọ àwọn ọ̀dọ́ di aláìbìkítà nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ẹlòmíràn, ó sì ń ṣèdíwọ́ fún ìdàgbàsókè èrò orí, kí ó tilẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ pàápàá.”

Ẹgbẹ́ Tí Ń Rí Sí Ìwà Ipá Orí Tẹlifíṣọ̀n ti Àpapọ̀ (NCTV) ròyìn ìwádìí kan tí ó ṣe pé, ọ̀pọ̀ àwọn ìwé àkàrẹ́rìn-ín tí a tẹ̀ jáde ní Hong Kong, Japan, àti ní United States ń gbé “àwọn kókó ọ̀rọ̀ ogun oníwà ẹhànnà, tí ó sì le koko, jíjẹ ènìyàn, ìbẹ́nilórí, bíbá ẹ̀mí èṣù lò, ìfipábáni-lòpọ̀, àti ìsọ̀rọ̀ àìmọ́” jáde. Dókítà Thomas Radecki, olùdarí iṣẹ́ ìwádìí fún ẹgbẹ́ NCTV, sọ pé: “Bí ìwà ipá àti àwọn ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ atẹ́nilógo tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ti le tó ń múni wá rìrì. Ó ń fi bí a ti sọ ara wa di aláìbìkítà nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn tó hàn.”

A Ní Láti Ṣọ́ra

Ní kedere, òòfà ọkàn wà fún ìbálòpọ̀ àti ìwà ipá nínú ayé òde òní, àwọn ilé iṣẹ́ tí ń ṣe àwọn ohun àṣenajú sì ń gbé e jáde. Ipò náà dọ́gba pẹ̀lú èyí tí Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.” (Éfésù 4:19) Nítorí ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń wá ohun tí ó sàn jù lónìí. Ìwọ ńkọ́? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, inú rẹ yóò dùn láti mọ̀ pé o lè rí ohun àṣenajú gbígbámúṣé, bí àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé èyí yóò ṣe fi hàn.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Tẹlifíṣọ̀n Lè Jẹ́ Orísun Ewu

NÍ United States, 1939 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí tẹlifíṣọ̀n jáde, níbi àfihàn àgbáyé ní New York. Oníròyìn kan tí ó wà níbẹ̀ sọ ìbẹ̀rù tí ó ní nípa ọjọ́ iwájú ìhùmọ̀ tuntun yìí. Ó kọ̀wé pé: “Ìṣòro tí ó wà pẹ̀lú tẹlifíṣọ̀n ni pé, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ jókòó, kí wọ́n sì tẹjú mọ́ ọn; ìdílé kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ní America kò ní àkókò fún un.”

Ẹ wo bí ó ti kùnà tó! Ní gidi, a ti sọ pé, nígbà tí ẹnì kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ní America bá fi máa jáde ilé ẹ̀kọ́, yóò ti lo àkókò tí ó fi ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ ju èyí tí ó lò níwájú olùkọ́ lọ níwájú tẹlifíṣọ̀n. Ọ̀mọ̀wé Madeline Levine sọ nínú ìwé rẹ̀, Viewing Violence, pé: “Àwọn ọmọ tí wọ́n ń lo àkókò púpọ̀ gan-an nídìí tẹlifíṣọ̀n túbọ̀ máa ń jẹ́ oníjàgídíjàgan, elérò òdì, ẹni tí ó sanra jù, tí kì í lè finú wòye nǹkan tó bẹ́ẹ̀, tí kì í fi bẹ́ẹ̀ lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, wọ́n sì máa ń jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí kò kúnjú ìwọ̀n tó àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń wo tẹlifíṣọ̀n níwọ̀nba.”

Àmọ̀ràn wo ló fúnni? “A ní láti kọ́ àwọn ọmọ pé, bíi gbogbo ìhùmọ̀ míràn tí ó wà nínú ilé, tẹlifíṣọ̀n ní ète pàtó kan. A kì í fi ẹ̀rọ ìgbẹrun sílẹ̀ ní títàn lẹ́yìn tí irun wá bá ti gbẹ, tàbí kí a fi ààrò oníná tí a fi ń yan búrẹ́dì sílẹ̀ ní títàn lẹ́yìn tí búrẹ́dì náà bá ti yan tán. A mọ àwọn ìlò pàtó tí àwọn ìhùmọ̀ wọ̀nyí wà fún, a sì mọ ìgbà tí ó yẹ kí a pa wọ́n. A ní láti kọ́ àwọn ọmọ wa ní irú ẹ̀kọ́ kan náà nípa tẹlifíṣọ̀n.”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ohun Àṣenajú Káàkiri Ayé

Jí! ní kí àwọn aṣojúkọ̀ròyìn rẹ̀ ní ibi gbogbo lágbàáyé ṣàpèjúwe ohun tí ń ṣẹlẹ̀ ní ti ohun àṣenajú láyìíká wọn. Díẹ̀ lára ohun tí wọ́n wí nìwọ̀nyí.

Brazil: “Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i. Síbẹ̀, nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn òbí ń ṣiṣẹ́ lóde ilé, wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọmọ sílẹ̀ láti máa fi tẹlifíṣọ̀n najú láwọn nìkan. Àwọn ike ikósọfúnnisí tí wọ́n ní kókó ọ̀rọ̀ ẹlẹ́mìí òkùnkùn àti àwọn eré àṣedárayá lórí fídíò tí ń gbé ògidì ìwà ipá jáde wọ́pọ̀.”

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Czech: “Láti ìgbà tí ètò ìjọba Kọ́múníìsì ti ṣubú, ohun àṣenajú ti bo orílẹ̀-èdè yí pátápátá lọ́nà tí a kò rí irú rẹ̀ rí níhìn-ín, títí kan àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n láti Ìwọ̀ Oòrùn, àti àwọn ilé ìtajà ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń lọ sí ilé ìgbafàájì fún ijó dísíkò, àwọn ilé ìgbafàájì eré àṣedárayá fífi igi gbá bọ́ọ̀lù lórí tábìlì, àti ilé ọtí. Ìpolówó-ọjà aláṣerégèé àti agbára ìdarí àwọn ojúgbà sábà máa ń ní ipa alágbára lórí wọn.”

Germany: “Ó dunni pé, ó máa ń rẹ ọ̀pọ̀ àwọn òbí jù láti ṣètò ohun àṣenajú fún àwọn ọmọ wọn, nítorí èyí, àwọn èwe sábà máa ń gbára lé ẹnìkíní kejì wọn láti jayé orí wọn. Àwọn kan máa ń ya ara wọn láṣo sídìí àwọn eré àṣedárayá orí kọ̀ǹpútà. Àwọn mìíràn máa ń lọ sóde ijó àjómọ́jú tí a ń pè ní rave, níbi tí oògùn olóró ti wà lọ́fẹ̀ẹ́lófò.”

Japan: “Àwọn ìwé àkàrẹ́rìn-ín ni ohun àfipawọ́ tí tọmọdétàgbà fẹ́ràn jù lọ, àmọ́ àwọn ìwé wọ̀nyí sábà máa ń kún fún ìwà ipá, ìwà pálapàla, àti èdè èébú. Tẹ́tẹ́ títa tún wọ́pọ̀. Àṣà míràn tí ó tún ń dani lọ́kàn rú ni pé àwọn ọ̀dọ́mọdébìnrin kan máa ń tẹlifóònù àwọn ẹgbẹ́ onítẹlifóònù kan tí a ń polówó káàkiri, tí a pète fún àwọn ọkùnrin eléte ìṣekúṣe. Àwọn kan ń tẹlifóònù kìkì fún ìmóríyá, nígbà tí àwọn mìíràn lọ dé orí dídájọ́ àjọròde tí wọn yóò gbowó lé lórí, tí ó sì máa ń ṣàmọ̀nà sí iṣẹ́ aṣẹ́wó nínú àwọn ọ̀ràn kan.”

Nàìjíríà: “Àwọn ilé ìwòran fídíò tí a kò ṣàkóso ń tàn kálẹ̀ jákèjádò Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Àwọn iyàrá àdàkàdekè yí ṣí sílẹ̀ fún tọmọdétàgbà. Wọ́n ń fi àwọn fídíò aláwòrán arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè àti ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ hàn déédéé. Ní àfikún, àwọn fíìmù tí a ń ṣe ládùúgbò, tí wọ́n ń gbé sáfẹ́fẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, ń fi ìbẹ́mìílò hàn.”

Gúúsù Áfíríkà: “Àwọn ijó àjómọ́jú ń pọ̀ sí i níhìn-ín, àwọn oògùn olóró sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó níbẹ̀.”

Sweden: “Àwọn ilé ọtí àti ilé ìgbafàájì alaalẹ́ ń rí ṣe ní Sweden, àwọn ọ̀daràn sì sábà máa ń rọ́ lọ sí irú àwọn ibi báwọ̀nyẹn. Fífi tẹlifíṣọ̀n àti fídíò najú ti kún fún ìwà ipá, ìbẹ́mìílò, àti ìwà pálapàla.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́