ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/22 ojú ìwé 21-23
  • “Ohun Tí Adìyẹ Ń Lé Kiri Nínú Òjò...”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ohun Tí Adìyẹ Ń Lé Kiri Nínú Òjò...”
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpèníjà Ṣíṣekókó Kan
  • Àwọn Olùgbọ́ Onímọrírì
  • Mo Dúpẹ́ Pé Ìrìn Mi Ò Já Sásán
    Jí!—2005
  • Àwọn Ìnira Ìgbà Ogun Mú Mi Gbára Dì fún Bá A Ṣeé Gbé Ìgbésí Ayé
    Jí!—2004
  • Máa Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Wàásù Ìhìn Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Níní Ìtẹ́lọ́rùn tí Ọlọ́run Ń Fúnni ti Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Jí!—1997
g97 5/22 ojú ìwé 21-23

“Ohun Tí Adìyẹ Ń Lé Kiri Nínú Òjò...”

Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Nàìjíríà

NÍGBÀ tí ìjọ kékeré tí a wà ní ìhà gúúsù Nàìjíríà gba ìpèsè tirẹ̀ nínú ìwé ìléwọ́ Ìròyìn Ìjọba No. 34, tí a pín kárí ayé, a hára gàgà láti mú àwọn ẹ̀dà náà lọ sí gbogbo apá àgbègbè ìpínlẹ̀ wa. Ìyẹn kì í ṣe iṣẹ́ rírọrùn kan. Àwọn ibùdó iṣẹ́ oko, níbi tí a ti ń gbin pákí, iṣu, àti àwọn ohun jíjẹ mìíràn wà nínú àgbègbè ìpínlẹ̀ wa. Wọ́n pa àwọn ibùdó wọ̀nyí síbi jíjìn láàárín igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru náà. Yóò ṣòro láti dé ọ̀dọ̀ wọn, ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun tí kò ṣeé ṣe. Ó ṣe tán, ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni pé kí ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ gbogbo onírúurú ènìyàn, kódà, àwọn àgbẹ̀ inú igbó kìjikìji pàápàá.—Tímótì Kíní 2:3, 4.

Nítorí náà, ní October 16, 1995, àwa 18 kẹ́sẹ̀ sọ́nà láago 7:30 òwúrọ̀, a lọ sí ibùdó kan tí ń jẹ́ Abomgbada, tí ó jìn ní nǹkan bíi kìlómítà 3.5. Ní apá kan ọ̀nà náà, a ní láti wọ́ odò kékeré kan. Omi odò náà mù wá dé ìbàdí.

Kí a lè dé ibùdó mìíràn lọ́jọ́ kan náà, a ní láti wọ́ odò míràn tí ó tóbi ju ìyẹn lọ. Lọ́tẹ̀ yí, àwọn arákùnrin mẹ́rin àti arábìnrin kan péré ló kọjá odò náà. Àwọn tó kù nínú àwùjọ náà dúró lẹ́yìn.

A bá ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń fẹ́ láti gbọ́rọ̀ wa pàdé lọ́jọ́ náà. Ohun tí ó jẹ́ àfikún ayọ̀ wa ni ohun tí a pè ní àjẹmọ́nú àbọ̀ oko wa. Bí a ti ń lọ, a ń ṣa àwọn èso kan tí wọ́n hù fúnra wọn nínú igbó jẹ. A bá àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlejò, tí wọ́n sì mọrírì ìsapá tí a ṣe láti dé ọ̀dọ̀ wọn pàdé; wọ́n fún wa ní ọsàn láti fi pòùngbẹ. A kàn sí nǹkan bí 250 ènìyàn, a sì pín gbogbo ìwé ìléwọ́ tí a ní lọ́wọ́ wa tán.

Ìpèníjà Ṣíṣekókó Kan

Ojúlówó ìpèníjà náà dé lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà. Ose Anasi, ibùdó kan tí ó ṣeé ṣe kí a máà tí ì dé rí nínú ìṣètò iṣẹ́ ìwàásù, wà ní kìlómítà 12 sí wa. Àwọn kan lọ́ra láti lọ síbẹ̀. Ó léwu láti kọjá Odò Urasi, púpọ̀ nínú wa kò sì mọ̀wẹ̀. Ó lè léwu láti fẹsẹ̀ wọ́ odò náà nítorí àwọn kùkùté mímú sórósóró. Àwọn ilẹ̀ ẹlẹ́rẹ̀ yóò máa yọ̀, ṣíṣubúlulẹ̀ sì lè fa ìfarapa. Àwọn kan lára àwọn afárá àfọwọ́ṣe náà kò lágbára. Àwọn ejò, ọ̀ni, àti odò tí ọ̀sọ̀sọ̀ kún inú wọn, wà lọ́nà.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwa 16 pinnu láti lọ. A fẹsẹ̀ rin kìlómítà 1.5 kí a tó wọ ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ sọ dá Odò Urasi líléwu, tí ń yára ṣàn lọ náà. Láti dé ibi tí ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ náà wà, a ní láti sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan. Àkókò òjò ni, odò náà sì ti dé ìpele àkúnya. Gbogbo àdúgbò náà jẹ́ ilẹ̀ amọ̀; ó sì máa ń yọ̀ gan-an nígbà òjò. Nígbà tí a sọ̀ nínú ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ náà, a rí i pé ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ náà ti di odò tí ó jìn tó mítà kan ní àwọn ibì kan. Nígbà yẹn ni ojúlówó ìṣòro wa bẹ̀rẹ̀.

A wọ́ ipa odò yí fún bí 30 ìṣẹ́jú. Ilẹ̀ náà ń yọ̀ gan-an débi pé ọ̀pọ̀ lára wa ṣubú sínú omi ẹlẹ́rẹ̀ náà, tí ó sì rin àwọn Bíbélì, ìwé ìròyìn, àti ìwé ìléwọ́ wa. Ara wa yá gágá, nítorí náà, nígbà tí ẹnì kan bá ṣubú, gbogbo wa yóò rẹ́rìn-ín, àti ẹni tí ó ṣubú náà.

Bí a ṣe sọ dá odò kékeré kan, àwọn ọ̀sọ̀sọ̀ so mọ́ wa lẹ́sẹ̀. Ọ̀dọ́ arábìnrin kan tí ọ̀sọ̀sọ̀ so mọ́ lẹ́sẹ̀ kígbe sókè gan-an. Ó ṣì ń kígbe lẹ́yìn tí a ti mú ọ̀sọ̀sọ̀ náà kúrò. A gba ìyẹn náà lọ́nà ìdẹ́rìn-ínpani gẹ́gẹ́ bí apá kan ìrírí eléwu náà, a sì ń tẹ̀ síwájú lọ́nà wa.

Nígbà tí a ń kọjá odò míràn, arákùnrin kan pinnu pé òun kò ní wọ́ odò náà bí àwọn yòó kù ti ṣe, ṣùgbọ́n òun yóò kúkú fò ó dá ni. Ó fo omi náà dá ṣùgbọ́n kò lè yẹra fún ẹrẹ̀. Ó yọ̀, ó nalẹ̀ kòròbàtà sínú ẹrẹ̀ náà. Ó dìde, ó yẹ ara rẹ̀ wò, ó rí i pé òun kò fara pa, ó sì wí pé: “Kò sí ìṣòro kankan; ara ìrírí náà ni.” A rántí pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú pàdé “awọn ewu odò,” bóyá, wọ́n tilẹ̀ pọ̀ ju àwọn tí àwa dojú kọ lọ.—Kọ́ríńtì Kejì 11:26.

A kọjá lórí afárá àfọwọ́ṣe kan, tí ó jọ pé ó léwu, àmọ́ gbogbo wa dọ́gbọ́n kọjá lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àgbègbè náà túbọ̀ wá ń yọ̀ gan-an, tó bẹ́ẹ̀ tí ó wọ́ pọ̀ fún wa láti máa ṣubú.

Arákùnrin aṣáájú ọ̀nà déédéé kan, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni 70 ọdún wà lára wa. Ó wá dágbére fún wa láàárọ̀ yẹn ni. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà, ó béèrè pé: “Báwo ni èmi ṣe lè dúró sílé nígbà tí ẹ̀yin ń lọ wàásù?” Ó rin kinkin mọ́ ọn pé òun yóò bá wa lọ, kò sì sí ohun tí ẹnikẹ́ni lè sọ láti mú kí ó dúró sílé. Ó sọ pé, Jèhófà yóò wà pẹ̀lú òun. Nítorí náà, ó bá wa lọ.

Nígbà tó ṣubú, tó fẹ̀yìn lélẹ̀ lórí ilẹ̀ yíyọ̀ náà, kò sẹ́ni tó rẹ́rìn-ín. A fi ìdàníyàn béèrè bóyá ó fara pa. Ó dáhùn pé: “Rárá. Mo fara balẹ̀ ṣubú ni, kí n má baà pa ilẹ̀ lára.” A rẹ́rìn-ín tìturatìtura, a sì rántí ìwé Aísáyà 40:31, tí ó sọ pé, “àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára pa dà.”

Àwọn Olùgbọ́ Onímọrírì

Níkẹyìn, a dé ibi tí a ń lọ. Àwọn ènìyàn náà dáhùn pa dà lọ́nà tí n ṣíni lórí. Ẹ̀rù ba ọkùnrin kan nígbà tí ó rí wa, tí a ń bọ̀ wá sí ahéré rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó mọ ẹni tí a jẹ́, ó wí pé: “Ó ṣòro fún mi láti gbà gbọ́ pé ẹ rin ìrìn àjò tí kò rọrùn bẹ́ẹ̀, kìkì láti wá wàásù fún wa. A mọrírì rẹ̀.” A fi òwe àdúgbò kan fèsì pé: “Ohun tí adìyẹ ń lé kiri nínú òjò, ó ṣe pàtàkì sí i ni.” Ó yé ọkùnrin náà.

Àgbẹ̀ míràn wí pé: “Bí ìwàásù bá ti dé ibí yìí, ó túmọ̀ sí pé ìgbàlà ti dé ọ̀dọ̀ wa nìyẹn.” Ọ̀pọ̀ lára wọn ní ìbéèrè, a sì dáhùn wọn. Wọ́n rọ̀ wá pé kí a tún pa dà wá, a sì ṣèlérí pé a óò ṣe bẹ́ẹ̀.

Ní Ose Anasi, a fi ìwé ìléwọ́ bíi 112 sóde—gbogbo èyí tí a ní lọ́wọ́. Lápapọ̀, a wàásù fún nǹkan bí 220 ènìyàn.

Nígbà tí a ń pa dà bọ̀, a ṣìnà. Ì bá gbà wá ní wákàtí kan ààbọ̀ láti pa dà sí ibùdó náà, ilẹ̀ sì ti ń ṣú lọ. A gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà, a sì pinnu láti máa rìn lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìyẹn túmọ̀ sí pé a ní láti wọ́ odò tí ń wuni léwu kan, tí ó mù wá dé itan.

Lẹ́yìn tí a sọ dá odò náà, a já ọ̀nà, a sì rí i lọ́nà tí ó yà wá lẹ́nu pé, a ti rin ìdá mẹ́rin nínú márùn-ún ọ̀nà tí a ní láti rìn dé ilé. Ṣíṣì tí a ṣìnà ti wá já sí àbùjá tí ó dín ìrìn wa kù fún nǹkan bíi wákàtí kan, ó kéré tán! Kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́ mọ́, inú gbogbo wa dùn, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Bí oòrùn ṣe ń wọ̀, a délé—ó rẹ̀ wá, ebi sì ń pa wá, ṣùgbọ́n a láyọ̀ púpọ̀.

Lẹ́yìn náà, nígbà tí a ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí ọjọ́ náà, arábìnrin kan sọ pé: “Mo ti gbọ́ nípa bí àgbègbè yẹn ṣe rí tẹ́lẹ̀, nítorí náà, mo mọ̀ pé n óò ṣubú. Bí kò bá jẹ́ nítorí ti ìhìn rere ni, n kì bá tí lọ síbẹ̀, kódà bí wọ́n bá kó gbogbo owó ayé yìí fún mi!” Arákùnrin kan ké gbàjarè pé: “Ìhìn rere náà ti dé Ose Anasi nígbẹ̀yìngbẹ́yín!”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Sísọdá afárá àdúgbò kan

A sọ dá ọ̀pọ̀ odò tí ọ̀sọ̀sọ̀ kún inú wọn

Ní ìsàlẹ̀ ọ̀nà eléwu yìí, a wọ ọkọ̀ ọ̀pẹẹrẹ tí a fi sọ dá Odò Urasi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́