ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/8 ojú ìwé 15-25
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
Jí!—1997
g97 6/8 ojú ìwé 15-25

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

(A lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí, a sì kọ àwọn ìdáhùn náà ní kíkún sí ojú ìwé 25. Fún àfikún ìsọfúnni, wo ìtẹ̀jáde náà, “Insight on the Scriptures,” tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.)

1. Pèpéle ilẹ̀ wo, tí ó wọnú òkun ní etíkun ìlà oòrùn Kírétè, ni Pọ́ọ̀lù wọkọ̀ òkun kọjá lára rẹ̀ nígbà tí ó ń lọ fún ìjẹ́jọ́ ní Róòmù? (Ìṣe 27:7)

2. Kí ni Mósè ń ṣe nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò rí i, tí ó mú kí obìnrin náà yọ́nú sí i? (Ẹ́kísódù 2:6, NW)

3. Àwọn ẹni mélòó ni Jésù sọ pé yóò rí ọ̀nà tí ó lọ sí ìyè? (Mátíù 7:14)

4. Kí ni ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ń ṣe lẹ́yìn tí a ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé? (Jẹ́nẹ́sísì 1:2, NW)

5. Lẹ́yìn tí ó fi òróró onílọ́fínńdà, olówó iyebíye, pa ẹsẹ̀ Jésù, kí ni Màríà fi irun rẹ̀ ṣe? (Jòhánù 12:3)

6. Kí ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti pe àwọn ọkọ ní ìbátan pẹ̀lú àwọn aya wọn? (Ẹ́sítérì 1:20, NW)

7. Kí ni òṣùwọ̀n títóbi jù lọ tí àwọn Hébérù ń lò fún ìwọ̀n ìwúwo àti iye owó? (Àwọn Ọba Kejì 23:33, NW)

8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kí àwọn ènìyàn má baà kú mọ́ ni Mósè ṣe ṣe é, kí ni Ọba Hesekáyà pa run nítorí tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn rẹ̀ ní àkókò ọba náà? (Àwọn Ọba Kejì 18:4, NW)

9. Kí ni orúkọ obìnrin tí ó wà ní ìlú Fílípì, tí ó ṣòro fún láti yanjú ọ̀ràn kan pẹ̀lú Kristẹni arábìnrin rẹ̀, Síńtíkè? (Fílípì 4:2, 3)

10. Kí ni Mósè ṣe, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un, láti fi kó wàláà òkúta tí a kọ Òfin sí lára sí? (Diutarónómì 10:1-5, NW)

11. Àwọn ọlọ́run àjọ́sìnfún wo ni àwọn ará Áfà, tí ọba ilẹ̀ Ásíríà tẹ̀ dó sí Samáríà lẹ́yìn tí ó ti kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbèkùn, ń jọ́sìn? (Àwọn Ọba Kejì 17:31, NW)

12. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe wí, ẹni tí ó bá “kí” apẹ̀yìndà kan di kí ni? (Jòhánù Kejì 11)

13. Bí Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ sọ pé àwọn olùṣòtítọ́ ará Kọ́ríńtì jẹ́ “lẹ́tà Kristi” tí a kọ sórí àwọn ọkàn àyà, kí ni ó sọ pé a kò lò? (Kọ́ríńtì Kejì 3:3)

14. Ní sàkáání ìlú wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ti kọ́kọ́ sún Sámúsìnì ṣiṣẹ́, tí a sì wá sin ín síbẹ̀ lẹ́yìn náà? (Àwọn Onídàájọ́ 13:25; 16:31, NW)

15. Kí ni Jésù fi ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wé nítorí tí ó ń ní ìyọrísí iṣẹ́ ìsọdìbàjẹ́? (Mátíù 16:11, 12)

16. Èé ṣe tí Jòhánù fi sunkún nígbà tí ó rí àkájọ ìwé tí a fi èdìdì méje dì náà? (Ìṣípayá 5:1-4)

17. Kí ni orúkọ kejì tí a fi mọ Ísọ̀, èkejì Jákọ́bù? (Jẹ́nẹ́sísì 36:1, NW)

18. Èé ṣe tí Dáfídì fi ń ṣe àwọn àmì bíi ti ọmọdé nígbà tí ó wà níwájú Ọba Ákíṣì ti Gátì, tí ó sì jẹ́ kí itọ́ rẹ̀ ṣàn sára irùngbọ̀n rẹ̀? (Sámúẹ́lì Kíní 21:13, NW)

19. Báwo ni a ṣe ń pe ọmọ ìbílẹ̀ Gátì? (Sámúẹ́lì Kejì 15:22, NW)

20. Èé ṣe tí Dáfídì fi gbé Jèhófà lárugẹ ní Orin Dáfídì 139:14 (NW)?

21. Kí ni a ti ń pe ìkángun ẹ̀yìn ọkọ̀ ojú omi? (Máàkù 4:38)

22. Oṣù mélòó ni àwọn òbí Mósè fi lè fi í pa mọ́ lẹ́yìn ìbí rẹ̀? (Hébérù 11:23)

23. Bàbá kí ni Jésù pe Sátánì? (Jòhánù 8:44)

24. Kí ni Hámánì ṣe láti pinnu ọjọ́ tó fọre láti pa àwọn Júù tí ń gbé Ilẹ̀ Ọba Páṣíà run? (Ẹ́sítérì 3:7, NW)

25. Pa pọ̀ mọ́ igi ólífì àti àjàrà, irúgbìn wo ló tún yọrí ọlá jù lọ nínú Bíbélì? (Jòhánù 1:48)

26. Ọ̀gangan ibo ni Jónátánì, ọmọkùnrin Sọ́ọ̀lù, ti sọ pé Dáfídì ni ọba tí ó kàn, tí yóò jẹ ní Ísírẹ́lì? (Sámúẹ́lì Kíní 23:16-18, NW)

27. Ta ni olùṣàkóso ará Páṣíà tí ó ṣàwárí àkọsílẹ̀ tí Kírúsì ṣe, tí ó sì yọ̀ǹda pé kí á ṣe àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì? (Ẹ́sírà 6:1-12, NW)

28. Ẹranko wo ló sún mọ́ òkété, ṣùgbọ́n tí ó tóbi jù ú lọ? (Léfítíkù 11:6, NW)

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè

1. Sálímónè

2. Ó ń sunkún

3. Ìwọ̀nba díẹ̀

4. Ó “ń lọ síwá-sẹ́yìn lójú omi”

5. Ó fi nu ẹsẹ̀ rẹ̀ gbẹ

6. Olúwa

7. Tálẹ́ńtì

8. Ejò bàbà

9. Yúódíà

10. Àpótí májẹ̀mú

11. Níbúhásì àti Tátákì

12. “Alájọpín nínú àwọn iṣẹ́ burúkú rẹ̀”

13. Yíǹkì

14. Éṣítáólì

15. Ìwúkàrà

16. “Nítorí pé a kò rí ẹnì kan tí ó yẹ láti ṣí àkájọ ìwé náà tàbí láti wo inú rẹ̀”

17. Édómù

18. Kí ó lè mú un dá ọba lójú pé orí òun kò pé, kí ó sì sá là

19. Ará Gátì

20. Nítorí pé ‘lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá rẹ̀ tìyanu-tìyanu’

21. Ìdí ọkọ̀

22. Mẹ́ta

23. Irọ́

24. Ó ṣẹ́ púrì (kèké)

25. Igi ọ̀pọ̀tọ́

26. Hóréṣì

27. Dáríúsì

28. Ehoro

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́