ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 6/22 ojú ìwé 3
  • Oúnjẹ—Ọ̀ràn Tí Ó Gba Ìrònú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oúnjẹ—Ọ̀ràn Tí Ó Gba Ìrònú
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyan Oúnjẹ Tí Ń Ṣara Lóore
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ǹjẹ́ Àǹfààní Kankan Wà Nínú Kéèyàn Dín Bó Ṣe Sanra Jọ̀kọ̀tọ̀ Kù?
    Jí!—2004
  • Ìgbà Tí Kò Dára Láti Sanra
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 6/22 ojú ìwé 3

Oúnjẹ—Ọ̀ràn Tí Ó Gba Ìrònú

BÍBÉLÌ sọ nínú Oníwàásù 9:7 pé: “Máa lọ, máa fi ayọ̀ yíyọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ.” Ní gidi, kì í ṣe pé jíjẹun jẹ́ ohun àìgbọdọ̀máṣe nìkan ni, àmọ́, ó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn fàájì gíga jù lọ nínú ìgbésí ayé.

Gbé ọ̀ràn Thomas, ẹni ọdún 34, yẹ̀ wò. Ó gbádùn jíjẹ ẹran. Ó sì ń jẹ ẹ́ lójoojúmọ́—lọ́pọ̀ ìgbà, ó ń jẹ ẹ́ ní ìgbà bíi mélòó kan lójúmọ́. Ohun tí ó sábà máa ń jẹ́ oúnjẹ àárọ̀ rẹ̀ ní mílíìkì, ẹyin mélòó kan, búrẹ́dì tàbí búrẹ́dì yíyan pẹ̀lú bọ́tà, àti sọ́séèjì tàbí ẹlẹ́dẹ̀ yíyan nínú. Ní àwọn ilé àrójẹ, ó máa ń béèrè fún ẹran lílọ̀ òun wàràkàṣì, ọ̀dùnkún tí wọ́n fi ọ̀rá dín, àti àwọn ohun mímu tí wọ́n fi mílíìkì ṣe. Tí ó bá ń jẹun nílé àrójẹ, lájorí irú oúnjẹ tí ó yàn láàyò ni ègé ẹran. Ilé àrójẹ tí ó yàn láàyò máa ń ta ègé ẹran tí ó jẹ́ gíráàmù 680 àti ọ̀dùnkún yíyan tí wọ́n kó jọ gègèrè pẹ̀lú ọ̀rá wàrà kíkan lórí rẹ̀, bí ó ṣe máa ń fẹ́ ẹ gẹ́lẹ́. Kéèkì oníṣokoléètì tí ó ní ice cream oníṣokoléètì lórí ni ìpanu tí ó yàn láàyò.

Thomas ga ní sẹ̀ǹtímítà 178, ó sì wọn kìlógíráàmù 89; ó fi kìlógíráàmù 9 sanra jù, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà ìjọba United States lórí ìwọ̀n oúnjẹ ní 1995 ti sọ. Thomas sọ pé: “N kò dààmú nípa ìwọ̀n ìtóbi mi. Ara mi yá gágá. N kò tí ì pa iṣẹ́ jẹ lọ́jọ́ kan láàárín ọdún 12 tó kọjá. Lọ́pọ̀ jù lọ ìgbà, mo máa ń gbádùn ara mi, mo sì máa ń lókun—àyàfi, dájúdájú, lẹ́yìn jíjẹ ègé ẹran onígíráàmù 680 kan.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ oúnjẹ tí Thomas ń jẹ lè máa nípa tí kò dára lórí rẹ̀, kí ó máa sọ ọ́ di ẹni tí ó lè ní àrùn ọkàn àyà kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀? Nínú ìwé rẹ̀, How We Die, Dókítà Sherwin Nuland sọ̀rọ̀ nípa ‘àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó jẹ́ ìṣekúpara-ẹni,’ ó sì fi irú oúnjẹ kan kún wọn, tí ó jẹ́ ‘ẹran pupa, ègé ẹlẹ́dẹ̀ yíyan títóbi, àti bọ́tà.’

Báwo ni àwọn oúnjẹ kan ṣe ń yọrí sí àrùn ọkàn àyà fún ọ̀pọ̀ ènìyàn? Kí ló wà nínú wọn tí ń fa ewu? Kí a tó jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a wo àwọn ewu ìlera tí ó wà nínú sísanrajù láwòfín.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Èé ṣe tí irú oúnjẹ bẹ́ẹ̀ fi jẹ́ ọ̀ràn tí ó gba ìrònú?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́