Matera—Ìlú Ńlá Àwọn Ibùgbé Inú Hòrò Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ
NÍ NǸKAN bí 50 ọdún sẹ́yìn, àwọn kan lérò pé àwọn ibùgbé ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ náà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dà bí “ibi gbígbóná janjan” tí Dante mẹ́nu kàn, èyí tí ó mú kí àwọn aláṣẹ ṣòfin lílé wọn kúrò níbẹ̀. Bí àwọn ènìyàn ti tún bẹ̀rẹ̀ sí í gbé inú àwọn ibùgbé náà lápá kan, a tilẹ̀ tún ti fi wọ́n kún Ohun Àjogúnbá Àṣà Ìbílẹ̀ àti ti Àdánidá Lágbàáyé, tí Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́, Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀, àti Àṣà Ìbílẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (UNESCO) ń dáàbò bò.
Kí ni a ń sọ nípa rẹ̀? Èé ṣe tí a sì ti hùwà lóríṣiríṣi ọ̀nà bẹ́ẹ̀ sí wọn láti ìgbà yí wá? Ìdáhùn sí ìbéèrè àkọ́kọ́ kò le: Sassi (nítumọ̀ olówuuru, “Àwọn Àpáta” lédè Italian) ti Matera, ní ìhà gúúsù Ítálì, tí ó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìsàlẹ̀ àwòrán ilẹ̀ Ítálì, ni a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n láti dáhùn ìbéèrè kejì, a ní láti lóye ohun tí wọ́n jẹ́, kí a sì mọ ohun díẹ̀ nípa ìtàn wọn. O kò ṣe bá wa kálọ bí a ti ń ṣèbẹ̀wò sí Sassi náà, kí o sì kọ́ ohun kan nípa wọn?
Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Guido Piovene ti sọ, “lára àwọn ìrísí ojú ilẹ̀ Ítálì tí ó mú kàyéfì púpọ̀ jù lọ wá,” ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Sassi ló jẹ́ ìlú ńlá kan tí a bù kún pẹ̀lú “òòfà àfiyèsí kíkàmàmà.” Láti lè rí i láìkù-síbì-kan, a lọ síbi gíga àdánidá kan tí a ń ti ibẹ̀ rí ìtújáde omi jíjinlẹ̀ kan. Lódì kejì àfonífojì náà, níwájú wa, ni ìlú ńlá Matera wà. Nínú ìmọ́lẹ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà, a rí àwọn ilé tí wọ́n lẹ̀ mọ́ àpáta; ó jọ pé ńṣe ni a kọ́ wọn sórí ara wọn. Bí àwọn ọ̀nà tóóró tó wà láàárín wọn ti darí sí ìsàlẹ̀ ibi ìtújáde omi, wọ́n di ìtakókó sísokọ́ra kan, tí ó jọ àwọn àkàsọ̀ gbọ̀ngàn àpéjọ ńlá kíkàmàmà kan. Àwọn ihò rẹpẹtẹ tí ó wà lára àpáta tí a rí náà jẹ́ ibùgbé, tàbí kí wọ́n ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ rí. Ní kúkúrú, àwọn ilé Sassi rèé—àwọn ilé inú hòrò tí a yọ nínú àpáta!
Àyíká Ṣíṣàrà-Ọ̀tọ̀
Láti dé Sassi—ìlú ńlá Matera ìgbàanì—a ní láti gba àárín ìlú ńlá òde òní náà, pẹ̀lú ètò ìrìnnà ọkọ̀ àti ariwo rẹ̀. Wíwọ ìlú ńlá àtijọ́ náà dà bíi gbígba àárín ìsokọ́ra àfinúrò tí ń gbéni re ìgbà àtijọ́ àti ọjọ́ iwájú; a yọ sí àyíká ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ kan níbi ti ìdàrúdàpọ̀ òde òní ti ń fàyè sílẹ̀ fún àwọn èrò àtẹ̀mọ́nilọ́kàn ìgbà tó ti kọjá.
Má retí àtirí olùgbé inú hòrò kankan. Lónìí, agbára káká ni o fi lè rí àwọn hòrò gidi tí a ṣe nígbàanì mọ́, nítorí pé bí a kò bá tí ì kọ́ odindi ilé síwájú wọn, a ti fi àwọn òkúta ẹfun ṣe ọnà síwájú wọn lóríṣiríṣi ọ̀nà ní ìbámu pẹ̀lú onírúurú sáà: sànmánì agbedeméjì, ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, àti ti ìgbàlódé. Bí a ti ń lọ, ìran náà jọ bí èyí tí ń yí pa dà láìdúró lójú wa.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn awalẹ̀pìtàn ti sọ, ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àwùjọ àwọn alákòókiri kan, bóyá tí wọ́n jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, tẹ̀ dó sí àgbègbè yí. Àwọn hòrò àdánidá rẹpẹtẹ tó wà káàkiri àgbègbè náà pèsè ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ipò ojú ọjọ́ àti àwọn adọdẹwájẹ. Láìpẹ́, àwọn ènìyàn ti fi púpọ̀ lára àwọn hòrò náà ṣelé. Ó jọ pé àwọn ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí fi hàn pé àwọn ènìyàn ti ń gbé àgbègbè náà láti ìgbà náà wá.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í wá fi àwọn ilé Sassi náà fúnra wọn ṣe ibùgbé. Ní ìgbà àwọn Gíríìkì òun Róòmù, ibùdó kékeré kan wà ní òkè pátápátá àpáta yíyọgọnbu kan, tí ó wá di àárín gbùngbùn ìlú ńlá àtijọ́ náà lóde òní. Raffaele Giura Longo kọ̀wé pé, ní àwọn àkókò ìgbàanì wọ̀nyẹn, àgbègbè Sassi náà jẹ́ “àfonífojì ẹgàn méjì, àwọn ilẹ̀ abẹ́ òkun méjì tí ó tẹ́ rẹrẹ sí ẹ̀gbẹ́ ibi gíga tí wọ́n kọ́ ìlú ńlá àtijọ́ náà lé lórí, tí ó sì ń wo omi tí ń tú síbi ìtújáde omi náà láti òkè; kò sí ẹni tí ń gbé ibẹ̀, àmọ́ . . . igbó ti kún bò ó.” Láti ìbẹ̀rẹ̀ Sànmánì Agbedeméjì, pẹ̀lú bí a ti ń gbẹ́ àwọn òkúta ẹfun tí kò le ní wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tí a sì ń la àwọn ọ̀nà, tí a ń kọ́ àwọn gbàgede, àti àwọn ilé tí a fi àpáta tí a wà nínú ilẹ̀ kọ́, Sassi bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìrísí àfiṣàpẹẹrẹ wọn.
A nílò àwọn ilé àti àwọn ibi tí a óò máa tọ́jú àwọn ẹranko sí, tí a óò sì ti máa ṣe àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú sísin àwọn ẹran ọ̀sìn, bíi ṣíṣe wàràkàṣì. Bí ó ti wù kí ó rí, lájorí ìgbòkègbodò ibẹ̀ ni iṣẹ́ àgbẹ̀. A ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn ewébẹ̀ sí ilẹ̀ ńlá títẹ́jú tí a yọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ àfonífojì tóóró gíga tí Sassi ga jù lọ. A ṣì lè rí àwọn àmì ilẹ̀ títẹ́jú náà. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìgbésí ayé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà jẹ́ láàárín agboolé, ní àgbàlá àwọn ilé tí ọ̀pọ̀ ibùgbé yí ká.
Ètò Fífa Omi Lọ́nà Tí Ó Wúni Lórí
A tún lè sọ pé, ìtàn Sassi jẹ́ ti ìjàkadì tí ènìyàn ń bá àpáta àti omi jà, tí wọ́n sì ń bá gbé pọ̀, nígbà kan náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé omi kò pọ̀ yamùrá, nígbà òjò, omi òjò ń ba ilẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣọ̀gbìn lórí ilẹ̀ títẹ́jú—tí wọ́n ṣe iṣẹ́ takuntakun láti ṣẹ̀dá—náà jẹ́ bí ó ti ń ṣàn gba ẹ̀gbẹ́ àfonífojì tóóró gíga náà. Nítorí náà, àwọn olùgbé Sassi rí i pé ó yẹ kí wọ́n darí omi òjò, kí wọ́n sì máa fà á.
Ṣùgbọ́n báwo àti ibo ni wọ́n ti lè máa fà á? Wọ́n gbẹ́ àwọn kànga ìdamisí sórí ilẹ̀ títẹ́jú náà, wọ́n sì ṣe é lọ́nà tí omi inú rẹ̀ kò ní máa ṣàn jáde. Ètò dídarí omi àti ti gọ́tà ń gbé omi èyíkéyìí tí ó bá wà lọ sínú àwọn kànga ìdamisí wọ̀nyí, tí a kọ́kọ́ ń lò fún ohun tí ó bá jẹ mọ́ iṣẹ́ àgbẹ̀ dípò fún àwọn ohun mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí ayàwòrán ilé náà, Pietro Laureano, ti sọ, iye wọn, “tí ó pọ̀ ju iye àwọn hòrò tí ènìyàn ń gbé tàbí ju iye tí a nílò fún omi mímú lọ gan-an,” jẹ́rìí sí i pé, “àwọn kànga ìdamisí àgbègbè Sassi jẹ́ ètò fífa omi fún ìbomirinlẹ̀ lọ́nà tí ó wúni lórí ní ìbẹ̀rẹ̀.”
Ìṣètò náà tún pèsè omi mímu tí ó pọ̀ tó, pẹ̀lú bí iye àwọn olùgbé ibẹ̀ sì tún ṣe ń pọ̀ sí i, kókó yìí wá di èyí tí ó ṣe pàtàkì lọ́nà púpọ̀ sí i. Fún ìdí yìí, wọ́n ṣàmúlò ìṣètò ọlọ́gbọ́nlóye kan. Wọ́n fa àwọn kànga ìdamisí wọnú ara wọn, ní ìpele kan náà àti lórí àwọn ilẹ̀ títẹ́jú ní ìpele ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. “Bíi ti ìṣètò àwọn ibi ìpọntí títóbi, wọ́n fàyè gba fífa èérí kúrò nínú omi láìdáwọ́dúró bí ó ti ń lọ láti inú kànga ìdamisí kan sí òmíràn.” Wọ́n wá fa omi náà láti inú ọ̀kan lára àwọn kànga púpọ̀ tí ó wà káàkiri Sassi. A ṣì lè rí ojú àwọn kan lára àwọn kànga wọ̀nyí lónìí. Ó ṣọ̀wọ́n kí omi pọ̀ gan-an tó bẹ́ẹ̀ ní àgbègbè gbígbẹ koránkorán kan.
Ilé Tí Ó Wà Láàárín Àpáta
Bí a ti ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àkàsọ̀ náà, tí a sì gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ àwọn ojú pópó tóóró kọjá, a wá mọ̀ pé ńṣe ni a ṣètò àwọn àdúgbò ìgbàanì wọ̀nyí sí àwọn ìpele dídagun wálẹ̀, tí a fi sábà máa ń rí i tí a ń rìn lórí àwọn ilé lọ sórí ilẹ̀ títẹ́jú nísàlẹ̀. Ní àwọn ibì kan, ìpele ibùgbé mẹ́wàá ló wà lórí ara wọn. Níhìn-ín, ènìyàn ń gbé ní ìfarakanra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú àpáta. Ní ìgbà náà lọ́hùn-ún, ní ọ̀rúndún kẹtàlá, àwọn ìwé àfàṣẹsí pe àwọn àdúgbò wọ̀nyí ní “Sassi.”
A dúró ní ìta ibùgbé kan. Ti pé iwájú ilé fẹ̀, ó sì jọ ti ìgbàlódé dé ìwọ̀n àyè kan kò gbọ́dọ̀ tàn wá jẹ, nítorí pé níhìn-ín, a ti fi ọ̀nà àbáwọlé kan tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi òkúta ẹfun ṣe kún ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ibùgbé àfiṣàpẹẹrẹ Sassi kan nìyí. Lẹ́yìn tí a kọjá ní ọ̀nà àbáwọlé náà, a tọ ọ̀wọ́ àwọn àkàsọ̀ kan lọ sísàlẹ̀ dé inú iyàrá ńlá kan níbi tí ìdílé náà ti máa ń ṣe ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìgbòkègbodò abẹ́lé nígbà kan rí. A lọ sísàlẹ̀ sí i dé inú iyàrá kejì, tí òmíràn wà nísàlẹ̀ rẹ̀. Àwọn iyàrá kan jẹ́ ògbólógbòó kànga ìdamisí tí wọ́n ti sọ di èyí tí inú rẹ̀ ṣeé gbé—wọ́n fi nǹkan dí ojú rẹ̀ lókè, níbi tí omi máa ń gbà wọlé, wọ́n sì kọ́ ọ̀nà abáwọlé náà nípa gbígbẹ́ ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ títẹ́jú náà. Wọ́n ti máa ń lo iyàrá tí ó wà ní inú pátápátá fún kìkì kíkó àwọn ẹranko akẹ́rù sí nígbà kan, nígbà tí ìdílé náà ń gbé àwọn iyàrá tí ó sún mọ́ ọ̀nà àbáwọlé jù lọ. Ibì kan tí ó ṣí sílẹ̀ gbayawu lókè ilẹ̀kùn náà ni ìmọ́lẹ̀ àti afẹ́fẹ́ ń gbà wọlé. A kò tún ní láti máa sọ ọ́, àwọn olùgbé Sassi kì í kó àwọn ẹranko akẹ́rù sínú ilé mọ́ lónìí!
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ibùgbé náà ni kò yọ síta. Èé ṣe? Nítorí pé ọ̀nà àbáwọlé náà àti àwọn kan lára àwọn ilé tí a fi hòrò ṣe náà fúnra wọn ni a gbẹ́ sórí ibi dídà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kan kí wọ́n lè ṣàmúlò ìtànṣán oòrùn. Nígbà òtútù, tí oòrùn máa ń wà ní ibi rírẹlẹ̀ jù lọ lórí ibi tí ilẹ̀ pin sí, ìtànṣán rẹ̀ lè wọlé, kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sínú ilé, kí ó sì mú un móoru; nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ìtànṣán oòrùn kì í kọjá ọ̀nà àbáwọlé, inú ilé yóò tutù, yóò sì lọ́rinrin. Lára ògiri ẹ̀yìn hòrò tí a ń bẹ̀ wò, a rí àlàfo kan tí wọ́n gbẹ́ tí ó ní onírúurú “àpáta pẹlẹbẹ ìgbéǹkanlé.” Òun ni wọ́n fi ń wo agogo ní lílo òjìji, tí a ṣe láti fi bí oòrùn ṣe ń lọ hàn jálẹ̀ ọdún. Nígbà tí a jáde síta, a ní ìmọ̀lára àrà ọ̀tọ̀. Bí inú hòrò náà ṣe tutù ti mú wa gbàgbé ooru ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ó wà níta!
Ìbàjẹ́ àti Ìmúbọ̀sípò
Kí a yọ ti ipò àyíká ṣíṣàrà-ọ̀tọ̀ sọ́tọ̀, Sassi náà ti fojú winá oríṣiríṣi ìyípadà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jẹ́ àárín gbùngbùn ìgbòkègbodò ìlú ńlá tí ó ṣọ̀kan, tí ó sì gbé kánkán dé ìwọ̀n àyè kan fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ohun kan yí pa dà ní ọ̀rúndún kejìdínlógún. Àwọn ilé tuntun àti òpópónà fara gbún ètò àbójútó omi tí a ṣe lọ́nà jíjáfáfá, tí èyí sì mú ìṣòro bá ọ̀nà ìkódọ̀tídànù déédéé. Bí àbáyọrí rẹ̀, àrùn ń pọ̀ sí i. Síwájú sí i, ìyípadà nínú ètò ọrọ̀ ajé àgbègbè náà yọrí sí ipò òṣì tí ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ìdílé tí ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ ní Sassi, ìlú tí ń kún síwájú àti síwájú sí i.
Ó jọ pé a kò lè yẹ bíbàjẹ́ tí àgbègbè tí ó ti lẹ́wà nígbà kan rí yìí ń bà jẹ́ síwájú sí i sílẹ̀. Nítorí náà, pẹ̀lú èrò yíyanjú ìṣòro náà pátápátá, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950, ìjọba pinnu láti lé àwọn tí ń gbé Sassi kúrò níbẹ̀. Fún àwọn tí ń gbé Matera níhìn-ín, tí iye wọn lé ní 15,000, ìyẹn túmọ̀ sí hílàhílo gidi kan ní pàtàkì láti ojú ìwòye ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, bí a ti já àwọn ìdè ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ tí wọ́n ti mú dàgbà ní àwọn àdúgbò náà.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn púpọ̀ gbà gbọ́ pé kò yẹ kí a pàdánù ibi ìṣàpẹẹrẹ ìran ìlú ńlá kíkàmàmà yí. Nípa bẹ́ẹ̀, ọpẹ́lọpẹ́ iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò jíjáfáfá kan, àwọn ilé Sassi ti ń kọ́fẹ pa dà, àwọn ènìyàn sì ti ń gbé inú rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ fẹ́ràn láti nírìírí ipò tí ó gba àyíká àwọn gbàgede ìgbàanì náà kan àti àwọn òpópónà sísokọ́ra ní Sassi. Bí o bá wá sí àgbègbè yí, o kò ṣe yà láti bẹ ìlú ńlá yìí, tí ó ti wà fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, tí ó yọ jáde láti inú àpáta, wò?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
1. Ìrísí Sassi ti Matera láìkù síbì kan; 2. “àwọn àdúgbò,” pẹ̀lú kànga lápá òsì lọ́wọ́ iwájú; 3. inú ibùgbé àfiṣàpẹẹrẹ kan; 4. àlàfo gbígbẹ́ tí wọ́n fi ń wo agogo ní lílo òjìji; 5. ọ̀nà gbígbẹ́ kan tí wọ́n ń lò nígbà kan rí láti gbé omi lọ sínú àwọn kànga ìdamisí